Jump to content

Ayo Omidiran

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ayo Hulayat Omidiran
Member of the House of Representatives
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
May 2011
AsíwájúPatricia Etteh
ConstituencyAyedaade/Irewole/Isokan
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí10 Oṣù Kọkànlá 1963 (1963-11-10) (ọmọ ọdún 61)
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAPC
Alma materAhmadu Bello University, Zaria
ProfessionPolitician

Ayo Hulayat Omidiran, tí a bí ní ọjọ́ kẹwàá, oṣú kọkànlá, ọdún 1965, jé olóṣèlú ti orílè-èdè Naijiria àti aṣòfin ti ìjọba ìbílẹ̀ Ayedaade/Irewole/Isokan ní Ipinle Osun. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ egbé All Progressive Congress. Ọmọ ìlú IkireIpinle Osun ni ó ti wá.[1]

Ètó-ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-ìwé Ayedaade Grammar School Ikire, ní Ipinle Osun, tí ó sì gba ìwé-ẹ̀rí ti WAEC ní ọdún 1980. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá lọ Ahmadu Bello University láti gboyè nínú Biochemistry ní ọdún 1985.

Ní ọdún 2011, ó díje fún ipò asojú ilé ìgbìmọ̀ asòfin ti ìjọba àpapọ̀, ó sì wọlé. Lẹ́yìn sáà kìíní rè, ó tún díje ní ẹlẹ́ẹ̀kejì, ósì wọlé lábẹ́ egbẹ́ APC. Ó ti fìgbà kan wà nípò orísiríṣi bíi amúgbálégbèẹ́ alága, egbé ilé ìgbìmọ̀ asòfin fún eré-ìdárayá, àti bẹ́ẹ̀ béẹ̀ lọ.[2]

Adarí ètò fún eré-ìdárayá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2002, ó darapọ̀ mọ́ egbẹ́ Nigerian Football Association Board títí wọ ọdún 2005. Láti ọdún 2006, ní ó ti darapọ̀ mọ́ egbé FIFA ti àwọn obìnrin. Wọ́n sì fi joyè olórí ẹgbẹ́ Omidiran babe tí ń ṣe ẹgbé àwọn obìnrin tó ń gbá bọ́ọ̀lụ̀ aláfẹsẹ̀gbá ti ìlú Osogbo ní ọdún 1997.[1] Ní ọdún 2017, wọ́n fi joyè olóri ẹgbé Nigeria Football Federation, ti ẹgbẹ́ àwọn obìnrin tó ń gbá bọ́ọ̀lụ̀ aláfẹsẹ̀gbá.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "Hon (Mrs) Ayo Omidiran - The Official Website Of The State Of Osun". Archived from the original on 2018-07-09. Retrieved 2018-07-03.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "National Assembly | Federal Republic of Nigeria". Nass.gov.ng. Archived from the original on 2018-07-03. Retrieved 2018-07-03.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Akpodonor, Gowon (7 November 2017). "Omidiran’s return will stabilize Nigerian women football, says Mabo". Archived from the original on 3 July 2018. https://web.archive.org/web/20180703220207/https://guardian.ng/sport/omidirans-return-will-stabilize-nigerian-women-football-says-mabo/. Retrieved 3 July 2018.