Bùkólá Adéẹyọ̀
Bùkọ́lá Adéẹ̀yọ̀ jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, olùgbéré jáde, adarí eré àti àsojú fún ilé iṣẹ́ kan ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Bùkọ́lá ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kejìlá ọdún 1989 ní ìlú Ìbàdàn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ati girama ní ní Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe ti Moshood Abíọ́lá ( MAPOLY) ní ìlú Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bùkólá bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe eré ìtàgé ní ọdún 2008, lẹ́yìn tí ó dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ ìgbéré jáde Ọdúnladé Adékọ́lá. Ó di ìlú-mòọ́ká látàrí ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré Ilẹ̀ Ọ̀wọ̀. Ó sì ti kòpa nín7 eré ọlọ́kan-ò-jọkan eré bí:
- Àbíkẹ́ Standing
- Ọmọ Àdúgbò,
- Sunday Dagború
- Fèrè síṣẹ́ mi. Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìgbé ayé ré
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bùkọ́lá Adéẹ̀yọ̀ jẹ́ aya ọ̀gbẹ́ni Bello Ọládipọ̀ Ibraheem tí ó jẹ́ adarí ati òṣèré orí-ìtàgé. Wọ́n bí ọmọ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jannell. Ó tún bímọ mìíràn fún ẹnìkan tí wọ́n pè ní Lasben.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Africa, Information Guide (2020-09-11). "Bukola Adeeyo Biography, Early Life, Age, Family, Education, Career And Net Worth ~ Information Guide Africa". Information Guide Africa. Retrieved 2020-10-25.
- ↑ Owolawi, Taiwo (2019-02-13). "Nollywood actress Bukola Adeeyo welcomes 2nd child, a baby boy". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2020-10-25.