Bọ́sẹ̀ Ọ̀kẹ́owó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Bọ́sẹ̀ Ọ̀kẹ́owó tí wọ́n bí lọ́dún 1994 [1] jẹ́ gbajúmọ̀ àkàndá abarapá ọmọbìnrin ayàwòrán tí kò lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó ń ṣiṣẹ́ ọ̀nà lárà ọ̀tọ̀.[2] Ó jẹ́ abarapá ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Èkìtì tí ó máa ń rìn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìjókòó-ìrìnnà(wheelchair). [3]

Ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé Bọ́sẹ̀ ló ti ní ìṣòro, ṣùgbọ́n kò gbà kí èyí mú un já kulẹ̀. Àwọn òbí Bọ́sẹ̀ bí i ni abarapá tí kò lẹ́sẹ̀ àti ìkà-ọwọ́. Bàbá rẹ̀ jẹ́ olùkọ́ tí ìyá rẹ̀ sìn jẹ́ oǹṣòwò láti Ìpínlẹ̀ Èkìtì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bọ́sẹ̀ kò kà ju ipele kejì lọ ní ilé-ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ nítorí ipò abarapá tí ó wà. Ṣùgbọ́n lónìí, ó lè sọ èdè òyìnbó dáradára. Láti kékeré ní ó ti ṣe àwárí ẹ̀bùn afọwọ́yàwòrán, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ìka owó. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sìn ní àwòrán àwọn ènìyàn ńláńlá tí ó ti yà. [4]


Àṣàyàn àwọn iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Davido and Chioma; CEO, Oracle Experience Agency, Dr. Felix Eiremiokhae; Mr. Adepeju Olukokun (Kokun Foundation ); Wife of Nigeria Vice President, Dolapo Osinbajo; Dj Cuppy; Taraji P Henson

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Meet Bose Okeowo, The Unorthodox Female Artist". BrandCrunch Nigeria. 2019-11-27. Retrieved 2020-11-08. 
  2. "Bose Okeowo: Àárẹ̀ kékeré ló sọ mi dí aláàbọ̀ ara yìí ṣùgbọ́n... - BBC News Yorùbá". BBC News Yorùbá (in Èdè Jetinamu). 2020-11-07. Retrieved 2020-11-08. 
  3. Anwankwo, Akan (2020-07-20). "Meet Bose Okeowo who drew Joshua and other top Nigerian celebs with a pencil". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2020-11-08. 
  4. "Meet Bose Okeowo, a wheelchair-bound artist who sketched Anthony Joshua, Davido and Bisi Fayemi". LiveTimes9ja. 2019-09-04. Retrieved 2020-11-08.