Bolaji Abdullahi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Bolaji Abdullahi
Bolaji Abdullahi.jpg
Mallam Bolaji Abdullahi, Former Minister of Youth Development, Federal Republic of Nigeria
Ọjọ́ìbíBolaji Abdullahi
Ẹ̀kọ́University of Lagos
University of Sussex
Iṣẹ́Politician
Writer

Bolaji Abdullahi (A bi ni ọdún 1969) jẹ́ olóṣèlú àti oǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà láti Ìpínlẹ̀ Kwara. Ó wà nínú Ìgbìnmọ̀ ti Alakoso orílẹ̀-èdè Naijiria tẹlẹ, lábẹ́ àkóso Goodluck Jonathan gẹ́gẹ́ bi Minisita fún Ìdàgbàsókè Ọ̀dọ́ ní oṣù Keje ọdún 2011 ati lehinna bi Minisita Idaraya.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Abdullahi kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè lórí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì èkó. Ní ọdún 2001, pẹ̀lú sikolashipu Chevening, Abdullahi fi orúkọ sílẹ̀ fún ikẹkọ ní ilé ẹ̀kọ́ fún iwadi ìdàgbàsókè (Institute of Development Studies) ní Yunifásítì ti Sussex níbití O ti kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè gíga tí ó peregedé lori Ìṣèjọ́ba ati Ìdàgbàsókè (Governance and Development)

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1997, Abdullahi darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ ìwé ìròhìn tí This Day gẹ́gẹ́ bí oníròhìn sùgbọ́n lẹ́hìn ọdún kan, Ó kúrò láti lọ darapọ̀ mọ́ Àpèjọ Alákòso Áfríkà (African Leadership Forum). Ó padà ní ọdún 2002 tí ó sì ní ìgbega sí ipò igbákejì olóòtú ti ìwé ìròhìn ní ọdún 2003. Lehinna, wọ́n kọ́kọ́ yan Abdullahi gẹ́gẹ́ bí olùránlọ́wọ́ pàtàkì fún Ìbáraenisọ̀rọ̀ àti Ìpín ýiká(Special Assistant Communication and Strategy) sí gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara tẹ́lẹ̀, Bukola Saraki ní ọdún 2003 lehinna ni O wa di olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí Ìmúlò àti ìpín yíká (Special Adviser on Policy and Strategy) ní ọdún 2005. Wọ́n yan Bolaji Abdullahi gẹ́gẹ́ bi koomisoanna fún ètò ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ́ ti Ìpínlẹ̀ Kwara láti ọdún 2007 sí ọdún 2011. Ó tẹ̀ síwájú láti lọ sìn nínú ìgbìmọ̀ Minisita ti aàrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Goodluck jonathan nígbàtí wọ́n yàán gẹ́gẹ́ bi Minisita fún ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní oṣù keje ọdún 2011. Lehinna ni wọ́n yàán gẹ́gẹ́ bi Minisita fún eré ìdárayá.

Ní oṣù kejìlá ọdún 2016, wọ́n kéde Abdullahi gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé gbogboogbo ti orílẹ̀ (National Poblicity Secretary) fún ẹgbẹ́ onigbale (All Progressive Congress). Ní ọjọ́ kini oṣù kẹjo ọdún 2018, Abdullahi finú fẹ́dọ̀ fí ìwé sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé gbogboogbo tí ẹgbẹ́ onigbale (All Progressive Congress) tí Ó sì kúrò nínú ẹgbẹ́ na.

Àwọn Ìtọ́kasí

1. https://www.thisdaylive.com/index.php/2018/10/02/bolaji-abdullahi-seven-others-withdraw-from-kwara-pdp-guber-race/

2. https://punchng.com/ex-minister-laments-hardship/

3.https://www.thisdaylive.com/index.php/2018/03/02/bolaji-abdullahi-newly-inaugurated-boards-will-help-mdgs-navigate-political-difficulties/

4.https://punchng.com/i-like-doing-house-chores-to-encourage-my-sons-bolaji-abdullahi/

5,https://www.vanguardngr.com/2017/11/bolaji-abdullahi-a-liar-exposed-his-book-as-tissue-of-lies-jonathan/

6. http://saharareporters.com/2018/08/01/breaking-its-official-bolaji-abdullahi-resigns-apc

7.https://www.tammysenglishblog.com/2019/02/jambs-201920-english-novel-bolaji.html

8.https://www.basedonnews.com/download-pdf-bolaji-abdullahi-sweet-sixteen-16-jamb-novel-summary-likely-exam-questions-150-plus-answers-jamb-examination/

9.https://dailypost.ng/2018/08/01/breaking-apc-spokesman-bolaji-abdullahi-confirms-exit-party/

10.https://www.thecable.ng/payback-time-bolaji-abdullahi

11. https://dailypost.ng/2018/08/24/apc-ex-spokesman-bolaji-abdullahi-run-kwara-governor/

12.https://www.dailytrust.com.ng/why-i-wrote-a-book-on-former-president-jonathan-bolaji-abdullahi.html