Bolaji Ogunmola
Bolaji Ogunmola | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Bolaji Ogunmola |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ilorin National Open University of Nigeria Royal Arts Academy |
Iṣẹ́ | Oṣere |
Ìgbà iṣẹ́ | [ 2013] |
Bọ́lájí Ògúnmọ́lá jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ògúnmọ́lá ní ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Philomena Nursery and Primary School, Èbúté Métta, ṣááju kí ó tó lọ sí ìlú Ìbàdàn fún ètò ẹ̀kọ́ mẹ́wàá rẹ̀. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ Ìṣàkóso Ìṣòwò ní National Open University of Nigeria.[1] Ògúnmọ́lá tún jẹ́ àkẹ́ẹ̀kọ́-gboyè ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì ti Ìlorin. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ eré ìtàgé ṣíṣe gẹ́gẹ́ bi akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní Royal Arts Academy.[2] Nígbà kan tí ó n sọ̀rọ̀ fún ilé-iṣẹ́ oníròyìn Vanguard lóri níní ẹni tí òun pẹ̀lu rẹ̀ dì jọ n ṣe wọléwọ̀de, Ògúnmọ́lá ṣàlàyé wípé, òun kò ní bẹ́ẹ̀ òun kò wá. Ó wípé ọ̀nà àti ṣiṣẹ́ owó ni òun gbájúmọ́. Ó tún ṣàlàyé pé owó jẹ́ èròjà pàtàkì nínu èyíkèyí wọléwọ̀de tó yanrí.[3] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ti ọdún 2016, ó sọ di mímọ̀ wípé bótilẹ̀jẹ́pé òún ní ìfẹ́ sí àwọn ọkùnrin tí ó bá mọ́ láwọ̀, òun kò fọwọ́sí bíbóra.[4]
Iṣẹ́ ìṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ògúnmọ́lá jẹ́ olùkópa níbi ètò ìfihàn Next Movie Star ti ọdún 2013.[5] Ipa rẹ̀ nínu eré Okon goes to School jẹ́ ìtọ́kasí gẹ́gẹ́ bi fíìmù àkọ́kọ́ tí ó ti hàn.
Fún ipa rẹ̀ nínu Sobi's Mystic, ó wọ àtòkọ Newsguru.com bi ọ̀kan nínu àwọn máàrún òṣèré Nollywood tí yóó gòkè àgbà lọ́jọwájú.[6] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú The Punch, ó ṣe àpèjúwe ipa méjì rẹ̀ tí ó kó nínu fíìmù náà gẹ́gẹ́ bi Aida/Mystic bi ìpèníjà tí ó ga jùlọ nínu iṣẹ́ rẹ̀. Ó tún ṣe ìkéde Bíọ́dún Stephen, Mo Ábúdù àti Oprah Winfrey gẹ́gẹ́bi àwọn àwòkọ́ṣe rẹ̀ nídi ṣíṣe fíìmù.[7]
Ó ní àwọn yíyàn méjì níbi ayẹyẹ City People Movie Awards ti ọdún 2018.[8]
Àṣàyàn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Tough Love
- Sobi's Mystic
- All Shades of Wrong[9]
- Okon Goes to School
- Tempted[10]
- Outcast[10]
- Out of Luck[10]
- On Bended Knees[11]
- Squatters (season 1)[11]
- Lekki Wives (season 1)[11]
- Jenifa's Diary (season 1)[11]
- Living Next to You[11]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "People think I’m not talented because I’m curvy– Bolaji Ogunmola". The Punch. August 12, 2018.
- ↑ "Bolaji Ogunmola: I Am Blessed With Big Bosoms, I Can’t Date A Poor Man". Information Nigeria. September 4, 2016.
- ↑ Onikoyi, Ayo (February 18, 2017). "A poor man should seek money instead of wife – Bolaji Ogunmola". Vanguard.
- ↑ "I don’t have sex and I will remain so for a while — Bolaji Ogunmola". Vanguard. September 24, 2016.
- ↑ Onikoyi, Ayo (February 18, 2017). "A poor man should seek money instead of wife – Bolaji Ogunmola". Vanguard.
- ↑ "Five Nollywood actresses you should be paying attention to". Newsguru.com.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "People think I’m not talented because I’m curvy– Bolaji Ogunmola". The Punch. August 12, 2018.
- ↑ "Nominees For 2018 City People Movie Awards". City People.
- ↑ "7 things you should know about Nollywood actress, Bolaji Ogunmola". newsguru.com.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ 10.0 10.1 10.2 "People think I’m not talented because I’m curvy– Bolaji Ogunmola". The Punch. August 12, 2018.
- ↑ 11.0 11.1 11.2 11.3 11.4 "Bolaji Ogunmola: I’ll Love to Date D’banj; He’s Stylish, Hot". ThisDay. October 29, 2016.