Jump to content

Chaste Christopher Inegbedion

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Chaste Christopher Inegbedion tí wọ́n bí ní agbègbè ìlú MuṣinÌpínlẹ̀ Èkó jẹ́ gbajú-gbajà olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ara ẹni ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe ti Creative5. [1]

Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Christopher lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì Ọlábísí Ọnàbánjọ (OOU) tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn lẹ́yìn tí parí ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Nígbà tí ó wà ní ile-ẹ̀kọ́ Fáfitì, ó dara pọ̀ọ́ ẹgbẹ́ "Rotary" àti " Lions and Junior Chamber International families".


Christopher jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ International Youth Council, àjọ tí ó jẹ́ ti gbogbo gbò ènìyàn láwùjọ. Wọ́n dá ajọ yí sílẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Youth Assembly at the United Nations ní ọdún 2007. Pátákì iṣẹ́ tí àjọ náà gbé dání ni kí àwọn ọ̀dọ́ lè fohùn ṣọ̀kan lágbàáyé gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan agbáyé ṣe gbe kalẹ̀.

Chaste ni ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n gbé iṣẹ́ àkànṣe Giving Garage kalẹ̀[2] . Iṣẹ́ àkànṣe tí ó níṣe pẹ̀lú ìṣedéédé pẹ̀lú àwọn obìnrin láwùjọ. Orúkọ tí wọ́n ńnpe Christopher ni Bàbá onílèdí ( "Pad Man”) látàrí bí ó ṣe ma ń pín Ìlèdí fún àwọn obìnrin pàá pàá jùlọ àwọn ọmọ obìnrin aláìlẹ́nìkan kí wọ́n lè róun lò lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nkan oṣù, kí wọ́n sì lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa pàtàkì lílo ìlèdí fún ìdábòbò ẹ̀ṣọ́ obìnrin .[3] [4] Chaste tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ United Nations Inter-Agency Network on Youth Development's Working Group on Youth and Gender Equality member.

Chaste tún jẹ́ ọ̀kan lára awọn ìgbìmọ̀ tí ó rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdébìnrin lágbàáyé ti United Nations Major Group for Children & Youth. Ó tún kópa nínú iṣẹ́ àkànṣe ti South Africa for the Global Child Forum ní ọdún 2015.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]