Jump to content

Ìlèdí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sanitary napkins
Different sized maxipads
Different brands on a shelf

Ìlèdí fún ọmọdé, ìlèdí tàbí ìlàpọ̀n fún àgbà tàbí páàdì fún àwọn obìnrin jẹ́ ohun èlò kan tí ó ma ń gba omi bíi ìtọ̀ àti Ìgbẹ́ Ènìyàn dúró lára ọmọ ìkókó tàbí ọmọdé. Ó tún jẹ́ ohun èlò tí àwọn obìnrin ma ń lò láti fi gba ẹ̀jẹ̀ dúró lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nkan oṣù, tàbí tí wọ́n bá bímọ, bẹ́ẹ̀ wọ́n ma ń lòó láti fi fí ojú ara àwọn obìnrin tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ abẹ fún. Ó ṣe pàtàkì kí wọ́n ma pàrọ̀ ìlèdí ní àìmọye ìgbà nínú ọjọ́ kan, ìyẹn bí nkan oṣù náà bá ṣe pọ̀ sí. Wọ́n ma ń ṣe ìlèdí látara àwọn ohun èlò oríṣiríṣi, ìyẹ̀n bí wọ́n bá ṣe fẹ́ kó rí.

Ṣíṣe rẹ̀ dá lórí orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ti ń pèsè rẹ̀,tabí ilé-iṣẹ́ tí wọ́n bá ti ń ṣeé jáde. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà a ń lo ohun-èlò Kotex láti pèsè ìlédí tí wọ́n ń pè ní Always, Equate, àti Stayfree. Ìlédí Lil-lets náà wà káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Irúfẹ́.àwọn ìlédí tí.a ti mẹ́nu bà yí kò sí fún àwọn aláàrẹ̀ tí agbẹ̀du ìtọ̀ wọn ti daṣẹ́ sílẹ̀, àmọ́ àwọn mìíràn ma ń lò wọ́n fún irúfẹ́ àwọn aláàrẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Ìpínsísọ̀rí rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Fáìlì:Always Platinum ìgbẹ́ ènìyàn
Platinum maxipad

Ìlédí tí ó ṣeé sọnù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn olùpèsè àwọn ohun-èlò yí kíì sọ gbogbo ohun tí wọ́n fi pèlò ọjà wọn jáde, àmọ́ àwọn ohun tí ó gbajúmọ̀ nínú ni bleached rayon, (cellulose made from wood pulp), òwú àti ike wà. Láfikún , wọ́n ma ń fi tùràré aládìídùn àti oògù apakòkòrò àìfojúrí si. Wọ́n ma ń fi àwọn èròjà ẹbu láílọ̀nù si kí ó le ní agbára láti gba omi dúró, èyí ni ó ma ń wú púkẹ́ nínú ìlèdí nígbà tí omi wọ́n bá wọ̀ọ́.

Lápapọ̀, bí wọ́n ṣe to àwọn èròjà tí a ti kà sẹ́yìn yí lẹ́sẹẹ́sẹ ni: "èròja Kotex tí wọ́n lọ̀ pọ̀ mọ́ ẹbu láílọ̀nù ni wọ́n fi sí àárín òwú tí wọ́n fi òórùn adídùn pò, òwú yí ni wọ́n rán mọ́ aṣọ fúlọ́fúlọ́ tí wọ́n fi ike gbámú ní eteetí kí ó lè ṣeé wọ̀ sí abẹ́ aṣọ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ lòó.[1] Láti sọ ìlèdí tí wọn ti lò nu, a lè sọọ́ sí inú apò tabí atàn tí abò, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọ́n lè gbe lọ sí ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe àtúnrọ àwọn ohun-èlò kí wọ́n fi ṣe nkan mìíràn jáde fún lílò. Oríṣiríṣi ìlédí ni ó wà tí a lè sọnù.

Reusable cloth menstrual pad with Kokopelli motif.

Àwọn Ìtọ̀kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]