Délé Òjó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Dele Ojo jẹ́ olórin Jùjú ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà wípé òun ni ó tan ẹ̀yà orin náà kálẹ̀.[1]

Iṣẹ́ orin rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

[2]

Délé Òjó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin rẹ̀ ní pẹrẹu nígbà tí ó ṣalábàá-pàdé olórin kan tí ó ń jẹ́ Victor Ọláìyá ẹni tí ó gba Délé sí inú ọmọ ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀. Ní ọdún 1961, Òjó dá ẹgbẹ́ òṣèré akọrin tírẹ̀ náà kalẹ̀ tí ó pè ní  "Délé Òjó & His Star Brothers" lẹ́yìn tí Ọláìyá tú ẹgbẹ́ akọrin tirẹ̀ ká . Òjó àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àwọn àwo orin ọlọ́kan- ò- jọ̀kan jáde tí wọ́n sì ń pèé ní elére káà kiri ìlú àti ìpínlẹ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bí:  Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ìpínlẹ̀ Èkó àti Ìpínlẹ̀ Òṣun. Bákan náà ni ó tún gbé orin rẹ̀ dé ọ̀pọ̀ Ìpínlẹ̀  orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.[2]

Àwo orin rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Alafia
  • Juju Music at Its Best

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]