Efinrin
Jump to navigation
Jump to search
Efinrin (Látìnì: Ocimum gratissimum) ni wọ́n tún ń pè ní "clove basil", tàbí "African basil",[1] tí àwọn Hawaii mọ̀ sí "wild basil",[2] jẹ́ ẹ̀yà ewé kan tí ó wá tí ó sì wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, Madagascar, apá Gúsù ilẹ̀ Asia, ilẹ̀ Bismarck Archipelago, wọ́n ń gbìín ní Polynesia, Hawaii, Mexico, Panama, West Indies, Brazil, àti orílẹ̀-èdè Bolivia.[3]
Orúkọ rẹ̀ ní àwọn èdè mìíràn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Efinrin ni wọ́n ewébẹ̀ tàbí egbògi tí ó wọ́pọ̀ jùlọ ní ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀, tí wọ́n sì ń pèé ní àwọn orúkọ wọ̀nyí nínú èdè wọn.
- Èdè Ẹdó Ebe-amwonkho
- Èdè Fon Tchayo
- Èdè Yorùbá Efirin
- Èdè Igala Añyeba
- Èdè Hausa Daidoya
- Èdè Igbo Nchuanwu tàbí Arimu
- Èdè Ibibio,
- Èdè Efik Ntong
- Èdè Okrika Kunudiri
- Èdè Akan Nunum
- Yerba di holé in Papiamento
- Èdè Haiti Fobazen
- Èdè Uganda Mujaaja
- Èdè Sri Lanka Maduruthala
- Èdè Kerala Kattutulasi
- Èdè Thai Bai yeera
- Èdè Georgia Rehani