Jump to content

Fúnmi Martins

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Olúwafúnmi Martins
Ọjọ́ìbíOlúwafúnmi
1963
Iléṣà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun,
AláìsíÌpínlẹ̀ Èkó
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Òṣèré orí-ìtàgé
Àwọn ọmọMidé Fúnmi Martins, Ayọ̀ Martins. Àkanbí Ayọ̀mípọ̀

Fúnmi Martins tí wọ́n bí ní ìlú IléṣàÌpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní inú oṣù Kẹsàn án ọdún 1963 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé àti sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Fúnmi ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní inú oṣù Kẹsàn án ọdún 1963, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Òkè-Ọnà àti ilé-ẹ̀kọ́ girama ní Ìlú Abẹ́òkútaÌpínlẹ̀ Ògùn. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ girama, ó tẹ̀ siwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Beepo Secretarial Institute ní ìlú Ìbàdàn níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gba ìwé-ẹ̀rí dípúlọ́mà nínú ìmọ̀ Secretariate.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fúnmi kọ́kọ́ se modeling fúngbà díẹ̀ ṣáájú kí ó tó bẹrẹ ẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré orí-ìtàgé. Ó di ìlú-mòọ́ká látara eré kan tí ọ̀gbẹ́ni Fidelis Duker gbé jáde ní ọdún 1993. Ó kópa nínú àwọn eré ọlọ́kan-ò-jọkan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àsìkò ọdún 1990s. Lásìkò yí, àwọn òṣèré orí-ìtàgé bí Fúnmi Martins, Adébáyọ̀ Sàlámì àti àwọn díẹ̀ kan ni wọ́n lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti fi kópa nínú eré tí a fi èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì gbé jáde.[2][3]

Àwọn àsàyàn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ti kópa lààmì-laaka nínú àwọn onírúurú eré bíi:

  • Ìjà ọmọdé
  • Ẹrù ẹlẹ́rù
  • Ẹ̀tọ́ mi
  • Pẹ̀lú mi ati bẹ̀ẹ́ bẹ̀ẹ́ lọ.

Fúnmi bí ọmọ méjì fún ọkọ àárọ̀ ọjọ́ rẹ̀, ìyẹn Mide Martins àti Ayọ̀ Martins. Lẹ́yìn tí ìgbéyàwó òun ati ọkọ rẹ̀ akọ́kọ́ forí ṣọ́pọ́n ni ó tún fẹ́ gbajú-gbajà olórin Afro jùjú tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sir Shina Peters tí ó sì bímọ ọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àkànbí Ayọ̀mípọ̀ Peters ní ọdún 2002.

Fúnmi papò dà ní ọmọ ọdún méjìdínlógójì nkan bí oṣù méjì lẹ́yìn tí ó bímọ rẹ̀ tán látàrí àìsàn ọkan. Ó kú sí ilé ìwòsàn kan ní agbègbè Agége ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Karùn-ún ọdún 2002. [4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Orodare, Michael (2020-03-11). "Remembering Funmi Martins: Nollywood actor who left early but left an heir". Nigerian Entertainment Today. Retrieved 2020-10-23. 
  2. "Sam Loco, Funmi Martins, other Nollywood stars we miss". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics. 2020-02-11. Retrieved 2020-10-23. 
  3. "The Story Of The Life And Death Of Legendary Yoruba Actress, Funmi Martins". GQBuzz.com. 2018-01-04. Archived from the original on 2020-10-27. Retrieved 2020-10-23. 
  4. Falae, Vivian (2018-01-04). "The truth about Funmi Martins death revealed". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2020-10-23. 

Ẹ̀ka:Àwọn òṣèré ilẹ̀ Nàìjíríà