Jump to content

Shina Peters

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Shina Peters: Àgbà Olorin Shina Peters ń kí Amóhùnmúàwòrán Orisun kú àyeye Ọdún Kẹ̀wá

Sir Ṣínà Peters tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kẹ́ta, ọdún 1958 (30 May 1958) ní ó jẹ́ olórin Jùjú ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà.

Ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Olúwásínà Àkànbí PetersÌpínlẹ̀ Ògùn. Peters bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ láti ìgbà èwe rẹ̀, nígbà tí ó ma ń ṣeré pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lábé orúkọ " Olúṣínà àti àwọn Ọmọ ìyá-Méjìlá gidi  (Olushina and His Twelve Fantastic Brothers).[1] Lásìkò náà, ni ó ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ta dùrù (piano) tí ó sì padà di ọmọ lẹ́yìn Ebenezer Obey. Lẹ́yìn èyí, ó kúrò lẹ́yìn Obey láti dara pọ̀ mọ́ ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀gbẹ́ni General Prince Adékúnlé gẹ́gẹ́ bí oní jìtá. Ẹgbẹ́ Adékúnlé ló ma ń ṣeré ní àwọn ilé ìtura ìlú-Èkó bíi:  ' Western Hotel, Palm Beach Hotel àti Executive Hotel. Nígbà míràn tí ó àárẹ̀ bá kọlu ọ̀gbẹ́ni Adékúnlé, Peters ló ma ń sábà ṣíwájú orin fún ẹgbẹ́ náà. Láìpẹ́ ni ó kúrò lẹ́yìn Adékúnlé láti dá ẹgbẹ́ Ṣínà Adéwálé sílẹ̀ pẹ̀lú ìlú-mọ̀ọ́ka olórin jùjú Ṣẹ́gun Adéwálé.[2] Àmọ́ ṣá, kò pẹ́ tí wọ́n tún fi pínyà lẹ́yìn tí ó ti śe àwọn àwo orin ọlọ́kan-ò-jọ̀kan jáde pẹ̀lú Ṣẹ́gun Adéwálé láàrín ọdún 1980, ní ó pinu láti dá ẹgbẹ́ òṣèré tirẹ̀ kalẹ̀ tí ó pè ní  "Sir Shina Peters & His International Stars".

Sina Peters ló tún jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé nínú eré 'Agbára Owó (Money Power). Inú eré yìí tí Ọlá Balógun jẹ́ olùkọ̀tàn rẹ̀ ni ó ti yófẹ̀ẹ́ pẹ̀lú arábìnrin  Clarion Chukwura tí òun náà jẹ́ òṣèré tí wọ́n sì jọ di tọkọ-taye tí wọ́n sì bí ọmọ ọkùnrin kan fúnra wọn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́  Clarence Peters.

Iṣ́e orin rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹgbẹ́ Sir Shina Peters & His International Stars gbé àwo orin 'Ace (Afro-Juju Series 1) jáde ní ọdún 1989. Àwo orin tí ó jáde lábẹ́ CBS Records of Nigeria ni ó sọ Peters di gbajú-gbajà olórin.  "Ace" tí Láolú Akins bá gbé jáde ni ó jẹ́ àkójọpọ̀ Jùjú àti Afró (Afrobeat). Àwo orin tí ó so ẹ̀yà, èdè, àti àṣà ilẹ̀ Nàij̀íríà papò. Orin Afró jùjú ni ó jẹ́ orin tí ọwọ́ ìlù àti ijó rẹ̀ le látàrí àkójọpọ̀ èrọ (electronic Keyboards, Saxophone àti Guitar). Ọ̀pọ̀ orin inú àwo náà pàá pàá jùlọ 'Ijó Shina' ni àwọn ènìyàn fẹ́ràn jù lo. Wọ́n fún àwo orin náà ní àmì-ẹ̀yẹ 'garner awards' tí ó fi Sina Peters sí inú àwọn òṣèré ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó gba àmì-ẹ̀yẹ .  Lẹ́yìn àwo orin 'Ace' , ó tún gbé àwo orin 'Shinamania' jáde, tí ó sì kọ àwọn àkòrí orin bíi: 'Olúwa Yóò Pèsè', 'Ọmọ Ń Bọ̀' àti 'Give our women Chance'. Àwo orin 'Shinamania (Afro-Juju Series 2)'  ni ó fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ wípé ẹgbẹ́ 'Sir Shina Peters & His International Stars' ti ṣe tán láti sọ eré Jùjú di ọtún ní àwùjọ orin ilẹ̀ Adúláwọ̀. Pẹ̀lú àṣeyọrí [citation needed] Sir Shina Peters yí ní ó fi hàn wípé òun ni olùdásílẹ̀ ẹ̀yà orin eré  (Afró Jùjú) tí ọ́ dá dúró títí di òní.  Àwo orin mẹ́rìndín-lógún  (16 album) ní ó ti gbé jáde.

Sir Shina Peters, tí wọ́n tún ń dàpè ní "SSP",  ni ó ti gba oríṣiríṣi àmì-ẹ̀yẹ ìdánimọ̀ fún ìgbìyànjú rẹ̀ lórí iṣẹ́ ọnà àtinúdá rẹ̀.[citation needed] Shina Peters & His International Stars ti di igi àlọ́yè láàrín àwùjọ orin àgbáyé. Peters ti ta àwo orin tí ó tó Mílíọ́nù mẹ́fà (6 millions) jákè-jádò àgbáyé, tí ó sì ti kọrin káàkiri ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti fúnfún bíi: South Africa, Europe, Germany, United Kingdom, Italy àti United States. Wọ́n gba Sir Shina Peters láyè sí US tour to Orbit Entertainment in 2012, láti ma kó àwọn ènìyàn rìn ìrìn-àjo káà kiri ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ilé iṣẹ́ rẹ̀ wà ní New York. SSP ní ó fi ìlú Èkó ṣe ibùgbé, tí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̣̀ sì lágbára síbẹ̀ láwùjọ orin ilẹ̀ Nàìjíríà.


Àwọn Àwo orin rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. Way to Freedom (1980)
 2. Freedom (1981)
 3. Money Power (1982)
 4. Kọ́ Tèmi fún mi (1984)
 5. Ṣẹ́wẹ́lẹ́ (1986)
 6. Ace "Afro Juju Series 1 (1989)
 7. Shinamania (1990)
 8. Dancing Time (1991)
 9. Experience (1992)
 10. Mr. President (1993)
 11. My Child (1994)
 12. Kilode (1995)
 13. Love (1996)
 14. Reunion (1997)
 15. Playmate (1999)
 16. Happy Hour (2001)
 17. Pay Back Time (2005)
 18. Splendour (2006)
 19. D one 4 me (2012)

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. Oguntayo, Ademola (March 19, 1990). "An Ace of Gold". African Concord (Lagos). 
 2. Empty citation (help)