Festus okotie eboh
Festus Okotie Eboh | |
---|---|
Okotie-Eboh in 1963 | |
Minister of Finance | |
In office 1957 – 15 January 1966 | |
Alákóso Àgbà | Abubakar Tafawa Balewa |
Asíwájú | Position established |
Arọ́pò | Obafemi Awolowo |
Minister of Labour and Social Welfare | |
In office 1955–1957 | |
Alákóso Àgbà | Abubakar Tafawa Balewa |
Asíwájú | Position established |
Arọ́pò | Position abolished |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Warri, Southern Nigeria Protectorate | 18 Oṣù Keje 1912
Aláìsí | 15 January 1966 | (ọmọ ọdún 53)
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | National Council of Nigeria and the Cameroons |
Àwọn ọmọ | Ajoritsedere Awosika (daughter) (Son) |
Relatives |
|
Occupation | Politician |
Olóyè Festus Okotie-Eboh (18 July 1912- 15 January 1966) jẹ́ olóṣèlú Nàìjíríà kan ó sì jẹ́ mínísítà ètò ìṣúnà tí Nàìjíríà láti ọdún 1957 sí 1966 lásìkò ìjọba ti Ògbẹ́ní Abubakar Tafawa Balewa.[1]
Okotie-Eboh ni a bí sí ìdílé olóyè Itsekiri kan, ọmọ ọba Okotie Eboh ni ìpín Warri, ìlú kan ni ẹ̀bá ọ̀nà odò Benin ni Niger Delta. Kí ó tó ṣe ìyípadà orúkọ, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olóyè Festus Samuel Edah. Ó jé akápò àpapọ̀ tí ẹgbẹ́ Nigerian First Republic (NCNC), ó tún jẹ́ adárí tí ẹgbẹ́ Federal Parliamentary tí NCNC tí a fi rọ́pò K.O Mbadiwe.[2][3].[4]
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àti iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Okotie Eboh gẹ́gẹ́bí Festus Samuel Edah ni Benin River, ìpín àtijọ́ Warri. Láti ọdún 1932 sí 1936, ó lọ sí ilé ìwé Sapele Baptist. Lẹ́yìn ìjáde rẹ̀, ó ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ní ilé iṣẹ́ àgbègbè ìbílẹ̀ kí ó tó wá sí ilé ìwé tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́bí olùkọ́. Ní ọdún 1937, a gbà á síṣẹ́ ní ilééṣẹ́ aṣe bàtà gẹ́gẹ́bí akọ̀wé ìṣirò owó. Nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́bí akọ̀wé, ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bookkeeping àti Accounting (ìṣirò). Ní 1944, ilééṣẹ́ Bàtà ṣí nípò lọ sí Ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́bí akọ̀wé àgbà àti àṣirò ti West Coast. Ẹ̀kọ́ ni ó wà fún ọdún kan kí ó tó padà sí Sapele láti lọ di ìgbà kejì alámojútó ni ẹ̀ka Sapele. In 1947, a ran lọ sí Prague, Czechoslovakia fún ìgbáradì nibi ti o ti gba Diploma ní Business Administration àti chiropody. O fi Bata Shoe sílẹ̀ láti lọ dá ilééṣé tíḿbà àti rọ́bà sílẹ̀. O dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ajé fífi rọ́bà ìránṣẹ́ jáde lábẹ́ orúkọ ti Afro-Nigerian Export and Import Company. Ilééṣé yìí fi ribbed smoked rubber ìránṣẹ́ jáde si Europe àti North America. Ní ọdún 1958, ó ṣí ilééṣé rubber - creeping, nígbà tó yá ní ọdún 1963, ó bẹ̀rẹ̀ ilééṣé Omimi Rubber àti Canvas Shoe. Ó tún bẹ̀rẹ̀ ilééṣé kankan pẹ̀lú àwọn alábàṣiṣọ́pọ̀ aláwọ̀ funfun: Dizengoffand Coutinho Caro, àwọn alábàṣiṣọ́pọ̀ yìí gbé Mid-West Cement Co lárugẹ, ọgbà sìmẹ́ntì kan ní Koko àti Unameji Cabinet Works.
Okotie Eboh ṣe ìgbéyàwó ni ọdún 1942, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì jọ bẹ̀rẹ̀ sí ní dá ilé ìwé púpọ̀ sílẹ̀. Ilé ìwé àkọ́kọ́ jẹ́ Sapele Boys Academy, èyí tí Zik's College of Commerce sí tẹ́lẹ̀. Ní ọdún 1953, ó bẹ̀rẹ̀ Sapele Academy Secondary School. Ní àwọn ọdún 1940s àti 1950s, Okotie Eboh wá lára ìgbìmọ̀ ti Warri Ports Advisory Committee, Sapele Township Advisory Board àti Sapele Town Planning Authority.
Ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Okotie Eboh fẹ́ arábìnrin Itsekiri kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́, ní ọdún 1942. Ọmọbìnrin wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alero, fẹ́ Oladipo Jadesimi.[5] Ọmọbìnrin àbígbẹ̀yìn wọn ni Ajoritsedere Awosika.
Ikú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n pa Okotie-Eboh pẹ̀lú Prime Minister Tafawa Balewa nínú ìdẹ̀tẹ̀ ìjọba ní 15 January 1966, tó sì fòpin sí Nigerian First Republic, èyí tó bí ìjọba olómìnira.[6]
Tún kà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Rosalynde Ainslie, Catherine Hoskyns, Ronald Segal; Frederick A. Praeger, Political Africa: A Who's Who of Personalities and Parties. Frederick A. Praeger, 1961
- Ryszard Kapuściński, Anatomy of a Coup d'Etat chapter in The Shadow of the Sun (1998)
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Chief Festus Sam Okotie-Eboh, the colossus lives on". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-01-13. Retrieved 2022-03-03.
- ↑ Larson, Sylvia B. (February 2000). Evans, George (1797-1867), lawyer, politician, and businessman. American National Biography Online. Oxford University Press. doi:10.1093/anb/9780198606697.article.0400350.
- ↑ "Okotie- Eboh: In time and history". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-04-10. Archived from the original on 2022-07-01. Retrieved 2020-05-26.
- ↑ Sklar, Richard (2004). Nigerian Political Parties: Power in an Emergent African Nation. Africa World Press Press. p. 227. ISBN 9781592212095. https://books.google.com/books?id=Oi0aVR4YkmUC&q=okotie+eboh+treasurer&pg=PA227.
- ↑ "Oil tycoon Oladipo Jadesimi's daughter, Emma, takes to dancing in London". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-09-21. Retrieved 2020-06-04.
- ↑ "Nigeria - the 1966 Coups, Civil War, and Gowon's Government".