Folorunsho Alakija
Folorunsho Alakija | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 15 Oṣù Keje 1951 Ikorodu, Southern Region, British Nigeria (now in Lagos State, Nigeria) |
Iṣẹ́ | Oníṣòwò obìnrin |
Title | Managing director, Rose of Sharon Group Vice chairman, Famfa Oil |
Olólùfẹ́ | Modupe Alakija (m. 1976) |
Àwọn ọmọ | 4 |
Àwọn olùbátan | DJ Xclusive (nephew) |
Website | www.folorunsoalakija.com |
Folorunsho Alakija(tí a bí ní ọjọ́ Kàrúndínlógún oṣù keje ọdun 1951) jẹ́ onísòwò àti olùfifúni ní Nàìjíríà.[1] Ó ń ṣe òwò àwọn ìkan ọ̀sọ́(fashion), epo rọ̀bì, àti ilẹ̀ títa. Òun ni olùdarí Rose of Sharon Group àti ígbákejì alága Famfa oil limited[2] Gégé bí ọ̀kan lára àwọn àtẹ̀jáde Ilé ìròyìn Forbes nípẹ́ òun ni obìnrin tó lówó jùlọ ní Nàìjíríà, owó rẹ̀ tó bíllíọ́nù kan dollar ní ọdun 2020.[3]
Àárò ayé àti Èkó rè
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bi Alakija ni 15 July 1951 si idile Oloye L. A. Ogbara ti Ikorodu, ìpínlè Eko. Alakija lo ilé-ìwé akobere ti Our Ladies Of Apostles, ipinle Eko laarin odun 1955 si odun 1958. Nigba to jé omo odun meje, o lo orílè-èdè United Kingdom lati tesiwaju iwe primari rè ní Dinorbem School for Girls laarin odun 1959 sí 1963. Nigba to pari eko primari rè, o lo Muslim High School ni Sagamu, ìpínlè Ogun, koto tun pada sí Pitman's Central College ni London[4]
Ise re
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Alajika bere Ise ni odun 1974 gege bi akowe ilé-isé Sijuade Enterprises ni ìpínlè Eko. O pada lo sise ni ilé ifowopamosi First National Bank ti Chicago gegebi akowe fun adari ile ifowopamosi naa. osise fun odun mejila ni awon ile ifowopamosi. Nitori ife re si oge ati oso, o lo ilé-ìwé kan ni London lati ko nipa aso riran, Nigba ti o pada si Naijiria, o bere ilé-isé oso re ti o pè ni supreme stitches, o pada yi oruko re pada si Rose of Sharon house of Fashion ni odun 1996.
Ififuni
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Alakija da Rose of Sharon Foundation kale lati ran awon opo ati omo alaini baba ati Iya lowo nipa sisan owo ilé-ìwé won ati fifun won lowo fun oko owo.[5]
Idile re
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Alakija fé agbejoro, Modupe Alakija láti idile Adeyemo Alakija ni osu kokanla, odun 1976.[6] Awon mejeji ún gbé ni ipinle Eko pelu omo won mererin ati omo-omo won.
Àwon Ìtókasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Iyengar, Rishi (2014-12-30). "Folorunsho Alakija Unseats Oprah As the World's Richest Black Woman". Time. Archived from the original on 2018-05-03. Retrieved 2022-05-30. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "About Me". Alakija. 2017-01-12. Archived from the original on 2021-04-27. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ "Folorunsho Alakija". Forbes. 2019-08-14. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ "Folorunso Alakija". Harvard University Center for African Studies. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ Ellis, From Jessica (2012-02-16). "Nigerian billionaire takes on cause of 'mistreated widows'". CNN. Retrieved 2022-05-30.<nowiki>
- ↑ "Meet Folorunso Alakija: The Richest Woman in Africa". Money Inc. 2019-10-09. Retrieved 2022-05-30.