Jump to content

Freedom Park

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán freedom park

Freedom Park jẹ́ oun ìrántí àti àyè fàájì láàárín èkó, ní Lagos Island, Nàìjíríà tó jé Her Majesty's Broad Street Prison nígbà kan rí. Olùyàwòrán Theo Lawson ni ó ya àwòrán náà.

Wọ́n kọ́ ilé-fàájì náà láti fi dáàbò bo ìtàn àti àwọn ohun ìní tó jemáṣà ti àwọn ará Nàìjíríà. Àwọn ohun àràbarà tí ó wà níbẹ̀ ń ṣàfihàn ohun ìní àwọn amúnisìn ìpínlẹ̀ Èkó, àti ìtàn ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Wọ́n kọ́ ọ láti fi ṣèrántí ayẹyẹ àádọ́ta ìgbòmìnira ní oṣù kẹwàá, ọdún 2010. Ọgbà náà dúró gẹ́gé bíi ohun ìrántí fún orílẹ̀-èdè, ìtàn, àyè ìpolongo àṣà, isẹ́-ọnà àti àyè fún eré-ìdárayá.

Nígbà tí ọgbà náà jẹ́ ọgbà ẹ̀wọn, ó jẹ́ ilé-ìgbé fún àwọn òlùgbejà fún ètò ìṣèlú tó jà fún òmìnira Nàìjíríà.[1]

Ọgbà náà ti wá di ilé-ìgbé fún àwọn ènìyàn lóríṣiríṣi, àti àyè fún àwọn àlejò. Lónìí, ọgbà náà ti wa di ibi-ìṣeré fún ayẹyẹ lóríṣiríṣi àti ilé fàájì àti afẹ́.[2][3]

Ní ọdún 1861, lẹ́yìn tí àwọn ará Britain sọ ìlú Èkó di ìletò ni wọ́n dá ọgbà ẹ̀wọ̀n Broad Street sílẹ̀.[4] Wọ́n kọ́ ìgbékalẹ̀ àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe fún ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ní ọdún 1882, pẹ̀lú ògiri alámọ̀ àti ewé koríko. Àmọ́ kò pẹ̀ rárá nítorí ìdàrúdàpọ̀ láti ọwọ́ àwọn alátakò ìjọba amúnisìn. Gẹ́gẹ́ bi Theo Lawson tó jẹ́ olùyàwòrán Freedom Park ṣe sọ pé àwọn alátakò amúnisìn ti ilẹ̀ Britain ń sọná si, wọ́n sì ń sun ún níná. Nítorí náà, àwọn ìjọba amúnisìn náà gbé bíríìkì wá láti England láti fi kó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.[4] Ìjábọ̀ fún ọdún 1898 fi lélè pé ọkùnrin 676, obìnrin 26, àti ọ̀dọ́ mọ́kànlá ni wọ́n wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà lọ́dún náà lọ́hùn-ún.

ògiri àkọ́kọ́ ṣe náà ṣíì wà níbẹ̀

Àwọn èèyàn jànnkan-jànnkàn ní ọgbà èwọ̀n náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]


Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "20 years journey to making of Freedom Park". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-08. Archived from the original on 2022-02-10. Retrieved 2022-02-10. 
  2. "Basic facts about the Freedom Park". The Pulse. Archived from the original on 18 May 2015. Retrieved 6 May 2015. 
  3. "Freedom Park". Tripadvisor. 
  4. 4.0 4.1 "How Nigeria turned Her Majesty's prison into a place of pleasure". BBC. Retrieved 17 December 2016.