Orin fújì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Fuji music)

Fújì jẹ́ orin tó gbajúgbajà láàárín àwọn Yorùbá. Ó jáde látara orin Wéré, tí wọ́n tún ń pè ní ajísàrí tó máa ń jí àwọn Musulumi nígbà àwẹ̀. Sikiru Ayinde Barrister ló sọ orin yìí di gbajúmọ̀ ní 1950 sí 1960, ó sì yí orúkọ rẹ padà sí Fuji.[1] Barrister sọ ọ́ di mímọ̀ pé ìwé alẹ̀móde kan ni òun rí ní pápá ọkọ̀ òfurufú, tí wọ́n kọ "Mount Fuji sí, tí oh jẹ́ òkè tó ga jùlọ ni Japan. Wọ́n sì máa ń sọ pé kí a má ṣi Fuji gbé fún "fuja" tàbí "faaji".

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orin wéré jẹ́ orin tó gbajumọ̀ láàárín àwọn Musulumi, òun sì ni wọ́n máa ń lò láti fi jí àwọn Musulumi lásìkò àwẹ̀. Ní bíi ọdún 1950, Dáúdà Àkànmú Epo Àkàrà àti Ganiyu Kuti[2] ló dá orin yìí sílẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn. Wọ́n máa ń lo sakara àti goje láti fi gbéorin yìí jáde. Díẹ̀ lára àwọn olórin wéré ni; Sikiru Omo Abiba, Ajadi Ganiyu, Ayinde Muniru Mayegun, Ajadi BAshiru, Sikiru Onishemo, Kawu Aminu, Jibowu Barrister, Ayinde Fatayi, Kasali Alani, Saka Olayigbade, Ayinla Yekini àti Bashiru Abinuwaye.

Ní ọdún 1960, Sikiru Ayinde àti àwọn akọrin wéré yòókù di gbajúmọ̀ ní gbogbom Èkó.[3]

Orin yìí wọ́pọ̀ láàrin àwọn ọkùnrin, àmọ́ èyí tí àwọn obìnrin máa ń kọ ni orin wákà. Àwọn obìnrin ló sìm máa ń gbe orin fún àwọn oní fuji.[4]

Ìdàgbàsókè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn gbajúgbajà olórin fuji ní orílè-èdè Naijiria ni; Rasheed Ayinde Adekunle Merenge, Abass Akande obesere (PK 1), Sir Shina Akanni, Alhaji Isiaka Iyanda Sawaba, Adewale Ayuba, Wasiu Alabi, (Oganla 1) King Dr.Saheed Osupa (His Majesty), Late Sunny T Adesokan (Omo Ina ton ko fújì), Alayeluwa Sulaimon Alao Adekunle Malaika (KS1, Original ), Shefiu Adekunle Alao (Omo Oko), Sule Adio (Atawéwé), Tajudeen Alabi Istijabah (Oju Kwara), Wasiu Ajani (Mr. Pure Water), Taiye Currency, Alhaji Komi Jackson, Remi Aluko(Igwe fújì), Muri Alabi Thunder, Karube Aloma, Oyama Azeez (Arabesa, Alapatinrin, The Modern Real Fuji Creator), Murphy Adisa Sabaika (Madiba 2), Abiodun Ike Minister (Aremo Alayeluwa), Tunde Ileiru, Karubey Shimiu, Adeolu Akanni (Paso Egba), Shamu Nokia, (Quintessential) Sunny Melody, Olusegun Ologo, Segun Michael, Bola Abimbola,[5] àti Sulaimon Alao Adekunle (KS1 Malaika).

Orin fuji ṣì ń tà láyé òde-òní. Àwọn eléré tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wọ orin fuji ni; Shanko Rasheed, Wasiu Container, Cripsymixtee, Konkolo Wally G, Global T, àti Muri Ikoko. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Wasiu Ayinde, tí a tún mọ̀ si K1 De Ultimate ni ó jẹ́ gbajúgbajà jù lọ ńnú gbogbom àwọn olórin fuji. Láti ọdún 1990, àwọn òsèré bíi Abass Akande Obesere, Wasiu Alabi Pasuma (Oganla Fuji), àti King Saheed Osupa ṣì wà lójú ọpọ́n olórin fuji.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Klein, Debra (2019). "Fuji" in Continuum encyclopedia of popular music of the world. Shepherd, John, 1947-. London: Bloomsbury Academic. pp. 145-151. ISBN 0-8264-6321-5. OCLC 50235133. https://www.worldcat.org/oclc/50235133. 
  2. W. Akpan, "And the beat goes on?", in M. Drewett and M. Cloonan, eds, Popular Music Censorship in Africa (Aldershot: Ashgate Publishing, Ltd., 2006), ISBN 0-7546-5291-2, p. 101.
  3. Unknown facts about Sikiru Ayinde Barrister https://www.premiumtimesng.com/arts-entertainment/117934-unknown-facts-about-sikiru-ayinde-barrister-by-olayinka-olaribigbe.html#sthash.sZUtB1FO.dpbs Archived 2014-09-03 at the Wayback Machine.
  4. Klein, Debra L. (2020). "Allow Peace to Reign: Musical Genres of Fújì and Islamic Allegorise Nigerian Unity in the Era of Boko Haram" (in en). Yearbook for Traditional Music 52: 1–22. doi:10.1017/ytm.2020.5. ISSN 0740-1558. https://www.cambridge.org/core/product/identifier/S0740155820000053/type/journal_article. 
  5. World Music Central Bola Abimbola Archived 2016-03-04 at the Wayback Machine. Retrieved 25 December 2020