Jump to content

Èdè Swàhílì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Kiswahili)
Èdè Swàhílì
Swahili Language
Kiswahili
Sísọ ní Burundi
 Congo DR


 Kenya
 Mozambique
 Rwanda
 Somalia
 Tanzania
 Uganda


 Oman[1]
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀
Èdè ìbátan
Lílò bíi oníbiṣẹ́
Èdè oníbiṣẹ́ ní African Union
 Kenya
 Tanzania
 Uganda
Àkóso lọ́wọ́Baraza la Kiswahili la Taifa (Tanzania)
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-1sw
ISO 639-2swa
ISO 639-3variously:
swa – Swahili (generic)
swc – Congo Swahili
swh – Coastal Swahili
  Eti okun, n'ibi ti Ede Swahili ti je Ede abinibi,
  gege bi Ede Ijobi,Oselu ,tabi Ede orile-ede,
  gege bi Ede owo, ati ibalopo eyameya.

Ede Swahili tabi Kiswahili(ni ede Kiswahili) je ede ni Afrika.Ede naa je ede Bantu ti o gbooro ju lo fun iwulo ni iha Ìlaòrùn Áfríkà.Pupo ninu awon eya ti o wa ni Ila Oorun Afrika, ni o n lo ede naa, gege bi ede Ibara soro.Lilo ede naa wopo julo lati Ariwa orile ede Kenya titi de Ariwa orile Ede Mozambique, ati awon Erekusu ti o wa ninu okun India,fun apere Zanzibar ati Pemba, tabi Kòmórò ati Mayotte.b'o tile je pe iye eniyan egbegberun marun{5 million} nikan ni o n lo ede naa gege bi ede abinibi,Iye apapo eniyan to gbo, ati ti o le lo ede naa fun ibanisoro laarin ara, to egbegberun Ogota[60Million} eniyan[2], ni Ila Oorun ati Aarin Orile Erekusu Afrika.

b'o tile je pe itona kiko Larubawa ni a koko lo ni kiko Ede Swahili,itona kiko Latini ni ede naa n lo fun ikosile nisisiyii, eleyyi ti o di iwulo, nitori awon olupolongo fun Esin Kristi ati ijoba amunisin. kiko ti o jeyo ninu aworan yii je Adura oluwa ni itona ti esin katoliki.[3]

Swahili je ede Bantu. pupo ninu awon Eya ti wa ni Eba odo Okun India, ni Ila Oorun Afrika ni o si n lo Ede naa. Pupo ninu awon oro ti o jeyo ninu Ede Swahili,lo ní orisun ninu Ede Larubawa, nitori Ibalopo ti o waye laarin awon Eya Bantu, ati awon Onisowo Larubawa, ti o wa ni eti bebe Sánji (Zanj) ati pásíà (Iran) ni Ila orun Afrika, ni bi odun Ogorun mejila sehin. Awon ede miran ti jeyo ninu awon oro Swahili ni Ede Jamani(German), Ede Potoki(Portuguese),Èdè Gẹ̀ẹ́sì(English), ati Ede Faranse{French}, lati awon Ibalopo ti o waye larin awon onilo ede wonyii, ni nkan bi odun Ogorun marun (500) sehin.Ede Swahili ni oni ,ti di ede Keji, ni Ilo fun Egbegberun eniyan ni orile-ede meta ni Iha Ila Orun Afrika, Tànsáníà, Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tòṣèlúaráìlú ilẹ̀ Kóngò ati Kenya, ni ibi ti ede naa ti je ede Ijoba.Ijoba Orile ede Uganda so ede naa di kiko ni gbogbo Ile Iwe alakobere, ni odun 1992. Bi o tile je pe igbese naa o sele bi won ti se ro, Ijoba orile ede naa so ede naa da Ede Ijoba no odun 1995, fun Imura s'ile ti Ìsọkan ti agbègbè Ilà Orùn Áfríkà. Gbogbo eniyan orile-ede Komoros ninu okun India ni o le so Ede Swahili, tabi ede ti o fara pẹ Swahili, fun apẹẹrẹ Èdè Shíkọmọ(Comorian).Iye eniyan die si n lo ede na ni awon Orile Ede Bùrúndì, Rùwándà, ati Ariwa orile ede Sámbíà


  1. Ethnologue list of countries where Swahili is spoken
    Thomas J. Honneybusch, 2010, "Swahili", International Encyclopedia of Linguistics, Oxford, pp. 99-106
    David Dalby, 1999/2000, The Linguasphere Register of the World's Languages and Speech Communities, Linguasphere Press, Volume Two, pg. 733-735
    Benji Wald, 1994, "Sub-Saharan Africa", Atlas of the World's Languages, Routledge, pp. 289-346, maps 80, 81, 85
  2. Irele 2010
  3. http://wikisource.org/wiki/Baba_yetu