Kofoworola Bucknor

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kofoworola Bucknor-Akerele
11th Deputy Governor of Lagos State
In office
29 May 1999 – 29 May 2003
Arọ́pòFemi Pedro
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí30 April 1939
Lagos State, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress
Alma materUniversity of Surrey

Kofoworola Bucknor-Akerele (tí a bí ní ọjọ́ ọgbọ̀n, osù kẹrin, ọdún 1939) jẹ́ olósèlú àti igbákejì gómìnà Ipinle Eko nígbà kan rí.[1] Òun ni igbákejì gómìnà nígbà ìjọba gómìnà Bola Tinubu láàrin ọdún 1999 wọ ọdún 2003.[2]

Ìbèrẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọjọ́ ọgbọ̀n, osù kẹrin, ọdún 1939 ni wọ́n bi. Ilé-ìwé CMS Girls School ni ó ti bẹ̀rẹ̀ ètò èkọ́ rẹ̀ kí ó tó lọ sí ilé-ìwé gíga ti ìlú Surrey, ní England lọ kàwé.[3]

Isẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó gboyè nínú ẹ̀kọ́ Journalism ní ọdún 1962. Ó sì ń ṣiṣẹ́ gégẹ́ bí akọròyìn fún BBC àti VON magazine.[4] Ní ọdún 1999, ó wọlé gẹ́gẹh bíi amúgbálẹ́gbèẹ́ gómínà Bola Tinubu, óun sí ni igbákejì gómìnà ẹlékọkànlá. Lọ́dún náà lọ́hùn-ún, òun nìkan ni obìnrin láàrin àwọn olóṣèlú tó wà nínú ìṣèjọba.[5]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]