"Kukere" (nínú èdè Efik: "má ronú") jẹ́ orin láti ọwọ́ olórin ilẹ̀ Nàìjíríà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iyanya.[2] Orin náà jáde gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn orin nínú àwo-orin Desire (2013). Lẹ́yìn tí wọ́n gbé orin náà jáde, orin náà wọ ipò kìíní nínú àtẹ Top FM ti oṣù Karùn-ún, Soundcity Viewers Choice, Rhythm FM, àtiThe Beat 99.9 FM Blackberry. Àmọ́ ipò kejì lo wà lórí àtẹ Radio Port Harcourt.[3] "Kukuere" gba àmì-ẹ̀yẹ Hottest Single of the Year ní Nigeria Entertainment Awards ti ọdún 2013, àti Best Pop Single ní The Headies ti ọdún 2012.
Àwọn oníjó CEO farahàn níbi ìṣeré orin náà ní Britain's Got Talent.[4] Cokobar àti Iyanya ṣètò ìdíje Kukere Queen láti lè ṣe ìgbélárugẹ orin náà ní ìlú London. Ìdíje náà gba àwọn olùdíje láàyè láti fi fídíò ijó wọn ránṣẹ́, àti ìdí mẹ́ta tí ó yẹ fún olùdíje náà láti gbégbá orókè.[5]
Àtúnkọ orin "Kukere" jáde ní ọjọ́ ogun oṣù Kẹjọ ọdún 2012; ohun D'banj sì ni ó hàn jù nínú orin náà.[11] Àtúnkọ yìí ní àkóónú bí i ti àkọ́kọ́ tó jáde, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ohun èlò orin tó wà nínú orin àkọ́kọ́ farahàn nínú àtúnkọ yìí.[12]