Lánre Towry-Coker

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Dr. Lanre Towry-Coker FRIBA ni wọ́n bí ní ọdún (1944) , tí ó sì jẹ oníṣẹ́ ayàwòrán ilé, olóṣèlú ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà,[1] . Ó ti ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba àti aládàáni rí, tí ó sì jẹ́ Kọmíṣánà àkọ́kọ́ fún iṣẹ́ àti ilégbèé ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[2][3][4] nígbà kan rí.

Ìgbésí ayé àti isẹ́ rẹ̀ti[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bàbá Láre jẹ́ onímọ̀[5][6] (civil engineer) ọmọ oríẹ̀ èdè Nàìjíríà, ẹni tí ó jẹ́ olùbádámọ̀ràn ètò aṣojú orílẹ̀ èdè Nàìjìríà sí orílẹ̀ èdè Malaysia,ìyẹn Tunku Abdul Rahman, ní àsìkò ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1960s, Lánre Towry-Coker lọ sílé-ẹ̀kọ́ St. Matthias ní ìpínlẹ̀ Èkó àti Kingston College, Surrey, ní orílẹ̀-èdè England, ṣáájú kí ó tó lọ sí ilé èkọ́ ayàwòrán ilé òun ìlú ní Architectural Association School of Architecture àti ilé-ẹ̀kọ́ Fáfitì North-East ní ìlú London. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ìdókòwò lẹ́yìn èyí nílé-ẹ̀kọ́ Harvard University Graduate School of Business Administration (OPM).[7][4]

Ó dá ilé iṣé ayàwòrán rẹ̀ kalẹ̀ tí ó pé ní (Towry-Coker Associates), ní ọdún 1975.[8] Ní ọdún 1976, wọ́n fi orúkọ àdúgbò kan sọrí rẹ̀ nílùú Èkó, kátàrí iṣẹ́ àti ipa ribiribi tí ó kó lórí ìdàgbàsókè agbègbè náà nílú Ekó, ìyẹn ní Lagos Island tí wọ́n ń pè ní (Towty Street) láti fi bu ọlà fún àwọn ẹbí rẹ̀. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n fètò sí orílẹ̀ olú ìlú [4]Àbújá, tí ó sì ti gba àmì ẹ̀yẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ fún àwọn iṣẹ́ mánigbàgbé pàá pàá jùlọ, àwọn ilé àrà-m-barà tí ó ti pètò rẹ nílẹ̀ Nàìjíríà.[4]

NÍ ọdún1999, Towry-Coker di ẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ jẹ́ Kọmíṣánà fún iṣe àti ilégbèé ní ìpínlẹ̀ Èkó. Òun ni ònkọ̀wé [2] [3] [4] Housing Policy àti The Dynamics Of Housing Delivery ní Nàìjíríà: tí ó sì lo ìpínlẹ̀ Èkó gẹ́gẹ́ bí ìwòye nínú ìwé rẹ̀ , tí ilé iṣẹ́ MakeWay tẹ̀ jáde ní ọdún 2012. [9]

Towry-Coker jẹ́ Olùkọ́ni ti Institute of Architects (NFIA) àti alábàáṣepọ̀ ti Institute Institute of Arbitrators (ACI. Arb.) ní ìlú UK. [4] Ní ọdún 2017, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí olùdásílẹ̀ Royal Institute of British Architects , ní ilẹ̀ Nàìjíríà àti ọkan nínú àwọn ayàwòrán ọgbọ̀n ní gbogbo àgbáyé ni Naijiria ati ọkan ninu awọn olùyàwòrán ọgbọn ní gbogbo àgbáyé. [10]

Ó fẹ́ ìyàwó rẹ̀ Bísífẹ Towry-Coker ṣùgbọ́n wọ́n ti pín yà báyìí. [2] [11] Ó bí àwọn ọmọ obìnrin mẹ́ta pẹ̀lú ọkùn rin kan Ọláòtán. [3]

Ẹ tún lé wo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • HAkojọ awọn oniseworan ile Naijiria
  1. "‘Nigeria Needs New Housing Policy’". Leadership News. 3 May 2014. http://leadership.ng/business/369315/nigeria-needs-new-housing-policy. Retrieved 18 March 2015. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Lagos socialite, Lanre Towry-Coker's lonely world". 15 January 2015. Archived from the original on 18 March 2015. https://archive.is/20150318205609/http://www.thecapital.ng/index.php/home/1538-lagos-socialite-lanre-towry-coker-s-lonely-world. Retrieved 18 March 2015. 
  3. 3.0 3.1 3.2 Empty citation (help) 
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 4.4 4.5 Kemi Akinyemi, "Celebrating Society Patriarch, Lanre Towry-Coker at 70", The Elites Nigeria, 15 November 2014.
  5. "Towry Coker hits 70". 23 November 2014. http://thenationonlineng.net/new/lanre-towry-coker-hits-70/. Retrieved 18 March 2015. 
  6. Empty citation (help) 
  7. "Dr. Lanre Towry-Coker" at Towry-Coker Associates.
  8. Yinka Kolawole (11 July 2011). "FMBN has failed to deliver on housing finance – Towry-Coker". The Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2011/07/fmbn-has-failed-to-deliver-on-housing-finance-towry-coker/. Retrieved 18 March 2015. 
  9. Housing Policy and the Dynamics of Housing Delivery in Nigeria: Lagos State as Case Study, MakeWay Publications, 2012, ISBN 978-1907925177.
  10. "For the Towry-Cokers, it’s a cold war". New Telegraph. 19 April 2014. Archived from the original on 25 May 2015. https://web.archive.org/web/20150525040352/http://newtelegraphonline.com/towry-cokers-cold-war/. Retrieved 18 March 2015.