Jump to content

Lisa Omorodion

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lisa Omorodion
Ọjọ́ìbíLondon, England
Iṣẹ́Actor, movie producer, entrepreneur

Ọmọọba Lisa Omorodion tí a mọ̀ nídi iṣẹ́ rẹ̀ bi Lisa Omorodion jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, agbéréjáde àti olùṣòwò. Ó gbajúmọ̀ fún ipa iwájú rẹ̀ nínu fíìmù ti ọdún 2013 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ First Cut, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Joseph Benjamin àti Monalisa Chinda.[1][2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Omorodion ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù.[3] Bàbá rẹ̀ lẹnìkan tó wá láti Ìlú Ẹdó tó sì jẹ́ olùdásílẹ̀ Hensmor Oil and Gas,[4] bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ̀ náà sì jẹ́ agbẹjọ́rò. Omorodion jẹ́ ìkaàrún nínu àwọn ọmọ mẹ́fà tí òbí rẹ̀.

Omorodion lọ sí ilé-ìwé alàkọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Corona Primary School ní ìlú Èkó.[5] Ní àkókò tí ó wà ní ilé-ìwé náà, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eré ìtàgé, níbẹ̀ sì ni ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún eré ṣíṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní lékún. Lẹ́hìn náà ó lọ sí Ilé-ìwé Command Secondary School fún ọdún mẹ́ta péré ṣááju kí ó tó lọ sí ilé-ìwé kan ní Ìlú Ẹ̀pẹ́ fún ètò ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ níbi tí ó tún ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eré ìtàgé ti ilé-ìwé ọ̀ún náà. Lẹ́hìn náà, ó lọ sí Yunifásitì Ìlú Èkó, níbi tí ó tí gba oyè nínu ìmọ́ Economics.[6]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Omorodion ṣe àgbéjáde eré First Cut ti ọdún 2013 tó sí tún kópa nínu rẹ̀.[7] Eré náà jẹ́ eré kan tó la àwọn ènìyàn lóye lóri ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpò àti ìwá ìpáǹle. Ní ọdún kan náà, ó dá ilé-iṣẹ́ kan tó n rí sí gbígbé fíìmù jáde sílẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Platinum Studios.[8] Omorodion ti ṣe àgbéjáde bẹ́ẹ̀ ló sì ti ní ìfihàn nínu àwọn fíìmù míràn bi Schemers (2015), Inn (2016) Karma ni Bae (2017) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ọdún 2015, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ipa Folakemi nínu eré tẹlifíṣọ̀nù ti Ndani TV kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Skinny Girl in Transit.

Àṣàyàn àwọn eré tí ó ti kópa

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Àkọ́lé Olùdarí Àwọn àkọsílẹ̀
2013 First Cut Lisa Omorodion Theatrical released full feature film, produced by Platinum Studios
2014 Calabash Obi Emelonye Premiered on Africa Magic
2014 Ikogosi Toka Mcberor Premiered on Africa Magic and irokotv
2014 The Other Side of The Coin Lancelot Oduwa Imasuen Premiered on ibakatv
2014 Therapist Lancelot Imasuen Premiered on Ibaka TV
2014 Open Marriage Chico Ejiro Premiered on Africa Magic and irokotv
2014 On a Trip Grace Edwin Okon
2014 Peppersoup Grace Edwin Okon
2015 Schemers Lisa Omorodion Premiered on Africa Magic and Iroko TV
2016 WoEman Damijo Efe Young Premiered on Ibaka TV
2016 Moth to a Flame One Soul Premiered on irokotv
2016 What a Day Emmanuel Eme
2016 This Very Weekend Emmanuel Eme Premiered on Ibaka TV
2016 The Inn Lisa Omorodion Premiered on ibakatv
2016 Karma is Bae Lisa Omorodion Premiered on Ibaka TV
2016 The Relationship Rukky Sanda Premiered on Ibaka TV
2016 Whose Meal Ticket Grace Edwin Okon Theatrical Release and Premiered on Ibaka TV
2016 Excess Luggage Damijo Efe Young Theatrical Release
2016 Jofran Okechukwu Oku Premiered on Africa Magic
2016 The Personal Assistant Rukky Sanda Premiered on Iroko TV
2017 Little Drops of Happy Grace Edwin Okon Theatrical Release
2017 Your Fada Simon Peacemaker Theatrical Release and Premiered on Ibaka TV
2017 Date Night Mercy Aigbe Premiered on Iroko TV
2017 Dark Past Chika Ike Premiered on Ibaka TV
2017 Waiting to Exhale Sobe Charles Umeh and Simon Peacemaker Premiered on Conga TV
2017 Levi Okechukwu Oku
2018 Ghetto Bred Eniola Badmus
2018 The Spell Grace Edwin Okon
2018 Night Bus to Lagos Chico Ejiro

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]