Lota Chukwu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lota Chukwu
Ọjọ́ìbíUgwu Lotachukwu Jacinta Obianuju Amelia
Oṣù Kọkànlá 29, 1989 (1989-11-29) (ọmọ ọdún 34)
Nsukka, Ipinle Enugu, Naijiria
Iléẹ̀kọ́ gíga
Iṣẹ́Osere, Akowe
Ìgbà iṣẹ́2014–iwoyi

Ugwu Lotachukwu Jacinta Obianuju Amelia jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Lota Chukwu . Ó di gbajúmọ̀ òṣèré lẹ́hìn kíkópa rẹ̀ nínu eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dègbà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Jenifa's Diary ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Fúnké Akíndélé, Juliana Olayode àti Falz, níbi tí ó ti kó ipa gẹ́gẹ́ bi "Kiki",[1] ọ̀rẹ akópa aṣíwájú, Jenifa . Ó jẹ́ enìkan tó nìfẹ́ sí eré ìdárayá yoga.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lota ni a bí ní Nsukka, Ìpínlẹ̀ Enugu, Nàìjíríà[3] ṣùgbọ́n ó ṣe ìgbà èwe rẹ̀ ní Ìlu Benin. Lota ni ọmọ ìkẹhìn nínu àwọn ọmọ mẹ́rin ti àwọn òbi rẹ̀. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìtẹ̀sìwàjù iṣẹ́ ọ̀gbìn ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Benin. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó parí ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Benin náà ló tún lọ kẹ́ẹ̀kọ́ eré ìtàgé ṣíṣe ní Royal Arts Academy tó wà ní ìlú Èkó, Nàìjíríà.[4]

Iṣẹ́ ìṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣááju kí ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré, Lota jẹ́ afẹwàṣiṣẹ́, ó sì ti kópa nínu ìdíje ẹwà ti Nàìjíríà ní ọdún 2011 lẹ́ni tó n ṣojú Ìpínlẹ Yobe.[5] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe rẹ̀ ní ọdún 2011 ṣùgbọ́n ó di gbajúmọ̀ lẹ́hìn tí ó hàn nínu Jenifa's Diary níbití ó ti kó ipa "Kiki". Ó tún ti kópa nínu àwọn eré àgbéléwò bíi Royal Hibiscuss Hotel, Falling, Fine Girl,[6] The Arbitration,[7] Dognapped[8] àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Lota kó ipa asíwájú nínu fídíò Reminisce kan, Pónmilé[9] àti nínu fídíò Aramide, Why So Serious.[10]

Ní ọdún 2017 ó kéde ṣíṣe ìfihàn tẹlifíṣọ̀nù kan tí ó pè ní "Lota Takes". Ìfihaǹ náà dá lóri bí a ṣé n dánọ́ óúnjẹ àti bí a ṣé n gbé ìgbésí ayé, èyítí n júwe Lota gẹ́gẹ́ bi olólùfẹ́ óúnje àti ìṣẹ̀dá.[11] Ìfihàn náà ti rí yíyẹ́sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ ìlu Nàìjíríà tó fi mọ́ Adékúnlé Gold,[12] Tósìn Ajíbádé,[13] Aramide,[14] àti MC Galaxy.[15]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]