Jump to content

Majid Michel

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́


Majid Michel
Ọjọ́ìbíMajid Michel
22 Oṣù Kẹ̀sán 1980 (1980-09-22) (ọmọ ọdún 44)
Cantonments, Accra, Ghana
Ọmọ orílẹ̀-èdèGhana
Iṣẹ́Actor and pastor
Ìgbà iṣẹ́2000–present
Notable workThings We Do For Love
Olólùfẹ́Virna Michel
Àwọn ọmọ3[1]
Websitemajidmichel.com[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]


Majid Michel tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógójì, oṣù kẹsàn-án, ọdún 1980 jẹ́ òṣèré ti orílẹ̀-èdè Ghana, olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ̀ amóhùn-máwòrán, ajíhìnrere àti oníwà-ìranmọlàkejì-lọ́wọ́. Wọ́n yàn án fún ìdíje gbígba àmì-ẹ̀yẹ fún òṣèré-kùnrin tó dára jù lọ ní ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards ní ọdún 2009, 2010, 2011, 2012, 2014 àti 2017.[2][3] Ó pàpà gba àmì-ẹ̀yẹ ọ̀hún ní ọdún 2012 lẹ́yìn tí wọ́n ti yàn án ní ọdún mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.[4][5]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀.

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Accra ní orílẹ̀-èdè Ghana ni wọ́n bí Michel sí. Lebanese ni bàbá rẹ̀ tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ìlú Ghana,[2] ìlú Accra sì ni ó gbé dàgbà pẹ̀lú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ mẹ́sẹ̀sán. Ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ St. Theresa ni ó lọ, lẹ́yìn tí ó wá lọ ilé-ìwé Mfantsipim, tí Van Vicker àti akọ̀wé àgbà ti United Nations (Kofi Annan) ti kàwé. Nígbà ti ó wà ní ilé-ìwé girama, ó sábà máa ń kópa nínú eré orí ìtàgé, ó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn eléré-oníṣe, èyí sì mu kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré tó dára jù lọ ní Cape Coast, ní Ghanalọ́hùn-ún.[2]

Ní kété tí Michel dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré, ó kópa nínú eré kan tí woṇ́ máa ń ṣàfihàn rẹ̀ lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Things We Do for Love, lẹ́yìn èyí ni ó gbé fíìmù rẹ̀ jáde tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Divine Love. Jackie Aygemang àti Van Vicker sì kópa nínú eré náà.

Ní ọdún 2018, ó tún kópa nínú fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Agony of the Christ, èyí sì mú u kí àwọn èèyàn yàn án fún ìdíje gbígba àmì-ẹ̀yẹ ti Africa Movie Academy Awards ní ọdún 2009. Ní ọdún 2009, ó fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pé òun máa ń gbà tó dọ́là mẹ́ẹ̀dógún lọ́nà ẹgbẹ̀rún kan($15,000) sí dọ́là márùndínlógójì lọ́nà ẹgbẹ̀rún kan ($35,000) lórí fíìmù kan.[4] Àti pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eré-ajẹmọ́fẹ̀ẹ́ ni òun máa ń sábà ṣe, òun ò fìgbà kan rí ní ìbálòpò pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́[5]. Ní ọdún 2017, ó sọ ọ́ di mímọ̀ lórí ètò rédíò kan tí wọ́n ti gbà á lálejò pé òun ò ní máa gbà láti ṣe fíìmù kọkan tí òun máa nílò láti fẹnu ko èèyàn lẹ́nu.[5]

{{columns-list|colwidth=30em|

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "PHOTOS: Majid Michel Steps Out With Pregnant Wife". 2016. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "AMAA 2009: List of Winners and Nominees". Retrieved 17 January 2010.  [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "Interview with Majid at ModernGhana.com, 2008". Retrieved 22 October 2009. 
  4. 4.0 4.1 Opurum, Nkechi (23 April 2012). "Rita Dominic wins best actress". Daily Times (Lagos, Nigeria). http://dailytimes.com.ng/article/rita-dominic-wins-best-actress. 
  5. 5.0 5.1 Alonge, Osagie (23 April 2012). "Rita Dominic, Majid Michel win big at AMAA 2012". Nigerian Entertainment (Lagos, Nigeria). http://thenetng.com/2012/04/23/rita-dominic-majid-michel-win-big-at-amaa-2012/.