30 Days in Atlanta
30 Days in Atlanta | |
---|---|
Adarí | Robert Peters |
Olùgbékalẹ̀ | Ayo Makun |
Àwọn òṣèré | |
Ìyàwòrán sinimá | James M. Costello |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Èdè | English |
Owó àrígbàwọlé | ₦163 million |
30 Days in Atlanta jẹ́ fíìmù àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jáde ní ọ̣dún 2014. Ó jẹ́ fíìmù apanilẹ́rìn-ín tí Patrick Nnamani kọ, tí Ayo Makun ṣe agbátẹrù rẹ̀, tí Roberts Peters sì jẹ́ olùdarí fíìmù náà.[1] Ipinle Eko àti ìlú Atlanta ni a ti ya fíìmù ọ̀un, tí ó sì jáde fún wíwò ní sinimá ni ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù kẹwàá, ọdún 2014. [2]Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fíìmù náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríwísí àti lámèétọ́ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan, ó pàpà wà lára àwọn fíìmù tí ọ̀pọ̀ ènìyàn wò ní ọdún 2015 káàkiri àwọn sinimá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[3][4][5][6]
Àhunpọ̀ Ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní Ipinle Eko, ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria kan (Ayo Makun), tí ó tẹ̀dọ̀ sí ìlú Warri, tí ó sì kúndùn láti máa panilẹ́rìn-ín lọ́pọ̀lọpọ̀ àti ọ̣mọ àbúrò bàbá rẹ̀ kan tó kàwé (Ramsey Nouah), tó sì nímọ̀ nípa ẹ̀rọ ayárabíàṣá, ni a rí pé oníṣòwò kan Dr. Johnson Adetola Briggs (Majid Michel) àti ìyàwó rẹ̀ (Juliet Ibrahim) pè síbi ayẹyẹ pàtàkì kan ní Ìlú Lekki ní Lekki Gardens Estate ní Ipinle Eko. Láìròtẹ́lẹ̀, Akpos jẹ ẹ̀bùn ńlá kan láti lo ọgbọ̀n ọjọ́ ní ìlú Atlanta, ó sì pinnu láti lọ pẹ̀lú ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀.
Ní kété tí wọ́n dé ibùdókọ̀- ọ̣kọ̀-òfurufú, ni wọ́n pàdé olóṣèlú ti ilè Naijiria kan tí wọ́n mọ̀ bí ẹ̣ní mowó, tí wọ́n sì kí i. Ibí tí wọ́n ti ń rìn láti fójú ní oúnjẹ ni Akpos ti kọ́kọ̀ rí ohun alákọ̀ọ́kọ́ tó yà á lẹ́nu. Ó rí ọmọ òyìnbó kan tí ó kọ̀rọ̀ sí ìyá rẹ̀ lẹ́nu tí ìyá rẹ̀ ò sì bá a wí, ó sì gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa ń ṣẹ̀ ní ìlú rẹ̀ ní Naijiria. Èyí sì mú u kí ó bi ọmọ náà ní ìbéèrè àmọ́ ìyá ọmọ náà bá Akpos wí.
Ó ṣe alábàápàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àjèjì mìíràn ní Amerika. Wọ́n ṣe ọ̀pọ̀lọ̣pọ̀ fàájì ní ìlú náà, ó sì ní ìgbà kan tí wọ́n pàdé ọ̀rẹ́ wọn kan, Okiemute (Desmond Elliot) tí wọ́n mọ̀ láti Naijiria. Lẹ́yìn tí wọ́n kíra tí wọ́n sì yọ̀ tán, ọ̀rẹ́ wọn yìí pè wọ́n wá sí ilé-oúnjẹ kan. Ní ibi tí wọ́n ti ń jẹun, Akpos tún rí ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì mìíràn, ó rí obìnrin kan tó ń san owó oúnjẹ tí òun àti ọ̣kọ rẹ̀ jọ rà, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ̣un tán. Ó sì tún gbọ́ àwọn ọmọ Naijiria kan tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àìmọ̀ọ́ṣe ilé-oúnjẹ náà. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó rí arábìrin kan Kimberly (Karlie Redd) tí ó nífẹ̀ẹ́ sí, àmọ́ Okiemute gbà á nímọ̀ràn pé kó má kọnu ìfẹ́ si nítorí bàbá arábìnrin náà.
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Richards fi èrò ọkàn rẹ̀ hàn sí Akpos pé òun fẹ́ fé ̣ Kimberly, Akpos sì fi ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé òun máa gbè é lẹ́yìn. Bí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣáà ṣe ń sọ̀rọ̀, Kimberly sọ fún Akpos pé bàbá òun nífẹ̀ẹ́ sí àwàdà tí ó ṣe lọ́jọ́ sí àti pé ó máa wùn ún láti fún Akpos níṣẹ́ níbi ilé-oúnjẹ wọn kí ó ba lè máa fi àwọn ọ̀rọ̀ àwàdà rẹ̀ pa àwọn ènìyàn lẹ́rìn-ín. Richards lòdì sí àbá yẹn, ó sì gbìyànjú láti mú kí Akpos kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ náà nítorí pé bí àwọn agbófinró bá gbá Akpos mú pé ó ń ṣiṣẹ́ ní ìlú náà, wọ́n le tì í mọ́lé, àmó Akpos fi tayọ̀tayọ̀ gba iṣẹ́ náà.
Lọ́jọ́ burúkú kan tí èṣù gbomi, Richards àti Akpos wọ ọkọ̀, àmọ́ Richards gbàgbé àpò owó rẹ̀ sí ilé, kò sì sí owó tí wọ́n máa fi san awakọ̀ náà. Awakọ̀ ṣáà gbaṣọ lọ́rùn wọn, ó sì já wọn bọ́lẹ̀. Bàbá Kimberly ni Ọlọ́run fi kẹ́ wọn lọ́jọ́ náà, tí ó padà wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó gbé wọn dé ilé rẹ̀, àwọn ẹbí rẹ̀ sì ṣe wọ́n lálejò. Ibẹ̀ ni Akpos ti rí arábìrin kan, Clara tí ó sì kẹnu ìfẹ́ sí.
Akpos bá ara rẹ̀ láàrin àwọn onítẹ́tẹ́ kan, ó sì dara pọ̀ mọ́ wọn láti máa ta tẹ́tẹ́. Àwọ̣n onítẹ́tẹ́ yìí gbìyànjú láti gbé owó rẹ̀ sálọ àmọ́ Akpos fi ìwà jàgídíjàgan rẹ̀ hàn wọ́n nígbà tí ó fọ́gò mọ́ ara rẹ̀ lórí láti ṣẹ̀rù bà wọ́n, àmọ́ àwọn arákùnrin yìi ́feré ge nítorí wọ́n gbọ́ ariwo ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá.
Akpos àti Richards ní ìpèníjà mélòó kan nínú ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Kimberly àti Clara. Àmọ́ lẹ́yìn gbogbo ìpèníjà ọ̀hún, àwọn obìnrin méjèèjì gbà láti tẹ̀lé wọn padà sí Naijiria.
Àwọn Akópa[edit]
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ayo Makunbíi Akpors
- Ramsey Nouah bíi Richard
- Richard Mofẹ́ Damijo bíi Odiye
- Desmond Elliot bíi Okiemute
- Kesse Jabari bíi Wilson
- Vivica A. Fox bíi Wilson's wife
- Lynn Whitfield bíi Odiye's immigration lawyer, Clara
- Karlie Redd bíi Kimberly
- Majid Michel bíi Adetola Briggs
- Omoni Oboli
- Racheal Onígà bíi Richard's mum
- Mercy Johnsonbíi Esse
- Ada Ameh bíi Akpors Mum
- Yemi Blaq
- Juliet Ibrahim bíi Adetola's wife
- Ifedayo Olarinde bíi Freeze
Awon Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "AY shoots first movie '30 days in Atlanta' featuring Vivica Fox". Kokoma 360. Archived from the original on 5 September 2014. Retrieved 5 September 2014.
- ↑ "Watch Lynn Whitfield & Vivica Fox in Trailer for Nigerian-Produced '30 Days in Atlanta' (The Plight of the Black Actress)". indieWire. Archived from the original on 5 September 2014. Retrieved 5 September 2014.
- ↑ "AY's '30 Days In Atlanta ' Bags Highest Grossing Nigeria Movie Of All Time AY's '30 Days In Atlanta ' Bags Highest Grossing Nigeria Movie Of All Time". 360nobs.com. 20 January 2015. Archived from the original on 2 October 2020. Retrieved 22 January 2015.
- ↑ "Movie breaks box office record, grosses N76M". pulse.ng. Archived from the original on 12 May 2016. Retrieved 26 December 2014.
- ↑ "Photos: Comedian AY's '30 DAYS IN ATLANTA' Breaks Nollywood Box Office Record". informationng.com. Retrieved 26 December 2014.
- ↑ "Amazing success of 30 Days in Atlanta thrills AY -How the movie grossed N76 million in 42 days!". encomium.ng. Retrieved 26 December 2014.