National Democratic Coalition (Nigeria)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

National Democratic Coalition (NADECO) ni wọ́n dá sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Karùún ọdún 1994 (May 15, 1994) láti ọwọ́  (broad coalition of Nigerian democrats),  tí ó pè ìjọba ológun tí  Sani Abacha láti kúrò lórí àléfà fún ẹni adìbòyàn  June 12, 1993, ìyẹn M. K. O. Abíọ́lá.[1] Àwọn afẹ̀hónú hàn olóṣèlú náà wá láti apá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà.[2]  Wọ́n sì jẹ́ kị́ àwọn ènìyàn mọ ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ fajúro sí ìṣèjọba ológun àsìkò náà.[3] Ní June 11, 1994, nípa ìtẹ̀lé àlàkalẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú NADECO, Abíọ́lá kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti ẹni tó jáwé olúborí nínú ìdìbò June 12, tí ó sì fara ṣoko lẹ́yìn tí ìjọba ológun sì fipá mu tì mọ́lé  ní  June 23.[4]

Ní ọjọ́ kẹtàdín-lógún oṣù Kọkànlá ọdún 1994 (17 November 1994),  àdó olóró dún gbàmù ní Pápákò Òfurufú Èkó  ní àyájọ́ ayẹyé ọdún kan lórí àléfà ọ̀gágun Sani Abasha. Àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ òṣèlú NADECO kìlọ̀ pé " àjálù ní yóò jẹ́ fún gbogbo àgbáyé, bí àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà bá gbà wípé jàgídì-jàgan ló lè mú kí àwújọ àgbáyé ó dá sọ́rọ̀ náà."[5]

Wálé Ọ̀sun, tí ó jẹ́ fì̀dí hẹẹ́ akọ̀wé àpapọ̀ (acting secretary-general) fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni wọ́n fi sáhàámọ́ ní ọjọ́ Kọkàndín-lógún oṣù Kárùún ọdún 1995 (May 19, 1995). Wọ́n tún fi páńpẹ́ ọba mú Olóyè Cornelius Adébáyọ̀ lẹ́yin oṣù kan tí àdó olóró kan tún dún ní ìlú Ìlọrin àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ NADECO míràn.[6] Ní July 1997, ìjọba ológun tún fẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ NADECO wípé àwọn ni wọ́n wà nídì jijù àdó olóró  oríṣiríṣi ibùdó àwọn ológun tó ti wáyé , tí ó sì tún sọ ní gbangba wípé àwọn agbọ̀rọ̀dùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan náà sì tún kún wọ́n lọ́wọ́ lórí ìwà láabi náà. Ẹni tí ó jẹ́ Ọ̀gá àwọn Ọlọ́pàá tẹ́lè, Ibrahim Coomassie, sọ wípé òun fẹ́ fi ọ̀rọ̀ wá aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu wo .[7]

Ní August 1999, ẹgbẹ́ òṣèlú náà pe ọgágun Sani Abasha lẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn wípé kó wá san owó ìtanràn tí ó tó $20 million fún ìwà ìrẹ́jẹ rẹ̀ lórí ẹgbẹ́ náà, lásìkò ìṣèjọba rẹ̀.[8]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Empty citation (help) 
  2. Eghosa E. Osaghae (1998). Crippled giant: Nigeria since independence. Indiana University Press. p. 294. ISBN 0-253-21197-2. 
  3. Gilbert M. Khadiagala, Terrence Lyons (2001). African foreign policies: power and process. Lynne Rienner Publishers. p. 30. ISBN 1-55587-966-7. 
  4. Empty citation (help) 
  5. Empty citation (help) 
  6. Empty citation (help) 
  7. Empty citation (help) 
  8. Empty citation (help)