Odò Ògùn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Coordinates: 6°44′44″N 3°20′33″E / 6.745589°N 3.34259°E / 6.745589; 3.34259

Odò Ògùn
Mouth elevation0 m (0 ft)

Odò Ògùn jẹ́ alagbalúgbú omi tí ó ń ṣàn kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ń ṣàn lọ sínu Lagoon ní Ìlú Èkó .

Ṣíṣẹ̀ àti ṣíṣàn rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Odo Ògùn lò bẹ̀rẹ̀ láti river rises in Ìpínkẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìtòsí ìlú Ṣakí tí fífẹ̀ rẹ̀ sì tó nkan bí 8°41′0″N 3°28′0″E / 8.68333°N 3.46667°E / 8.68333; 3.46667 tí ó sì ń ṣàn gba flows through Ìpínlẹ̀ Ògùn ọjá lọ sí inú odò Ọ̀sà ní Ìpínlẹ̀ Èkó . Wọ́n dẹ́bùú omi yí ní Ikere Gorge Dam iní ó wà ní ìlú Ìsẹ́yìn ní agbègbè ìjọba Ìbílẹ̀ Ìsẹ́yìn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ojúkò (reservoir) omi yí tó 690 million cubic metres (560,000 acre⋅ft).[1] Ojú kò omi yí tánọ̀ bu iyì kún Oyo National Park, nípa ṣíṣe àlékún ọ̀nà ìgbafẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú bí ó ṣe ń ṣàn kiri agbègbè náà. Odò Ofiki tí òun náà tún ń ṣàn nítòsí Ìlú Ṣakí ni ó ń tọ Odò Ògùn lẹ́yìn. Ẹ̀wẹ̀ Odò Ọ̀yán náà tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára wọn, èyí tí wọ́n dẹ́bùú rẹ̀ ní Ọ̀yán River Dam èyí tí ó jẹ́ orísun omi fún ìlú Abẹ́òkúta àti ìlú Èkó lápápọ̀. Ní àqọn agbègbè tí ènìyàn ti pọ̀jù, wọ́n ma ń lo omi yí láti fi wẹ̀ tàbí fọ aṣọ pàá pàá jùlọ fún mímu, lọ́pọ̀ ìgbà. Omi yí tún m ń jẹ́ ohun èlò tí wọ́n fi ma ń fọ ohun kóhun pàápàá jùlọ odò ẹran

Ìtàn rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínú Ìgbàgbọ́ Yorùbá, Yemọja jẹ́ Olú Odò Ògùn. Olúṣọ́ ìjọ Àgùdà kan Charles Phillips, tí ó jẹ́ bàbá fún Charles Phillips tí ó padà di Bíṣọ́ọ́bù fún ìjọ Àgùdà ti ìpínlẹ̀ Òndó nígbà ayé rẹ̀, kọ̀wé kan ní ọdún 1857 pé: "àwọn ènìyàn tí ó ń gbé lẹ́bàá odò Ògùn ma ń sin Odò náà, ṣáájú kí ó tó ṣàn wọ inú ọ̀gbun / ibúdò ńlá. [2] Odò náà gba àárín ìlú Ọ̀yọ́ à̀tijọ̣́ kojá. Ìlú Ọ̀yọ́ ni a lè pín sí ìsọ̀rí mẹ́fà. Mẹ́ta ní apá ìwọ̀-Oòrùn ti Odò Ògùn àti mẹ́ta sí ìlà-Oòrùn Odò náà. [3] Nígbà kan rí, Odò náà kópa nínú lílànà fún àwọn oníṣòwò nípa kíkó àwọn ọjà wọn wọ ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Abẹ́òkúta sí Ìletò Èkó . [4]

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Dams and Reservoirs, Societies and Environment in the 21st Century: Proceedings of the International Symposium on Dams in the Societies of the 21st Century, 22nd International Congress on Large Dams (ICOLD), Barcelona, Spain, 18 June 2006. Taylor & Francis. 
  2. McKenzie, Peter Rutherford (1997). Hail Orisha!: a phenomenology of a West African religion in the mid-nineteenth century. BRILL. p. 30. ISBN 90-04-10942-0. https://books.google.com/books?id=BIdITHIAEs0C&pg=PA201. 
  3. Stride, G.T. (1971). Peoples and Empires of West Africa: West Africa in History 1000-1800. Nelson. p. 296. ISBN 0-17-511448-X. 
  4. "British and Foreign State Papers". Google Books. Retrieved November 22, 2019.