Jump to content

Ogechukwukanma Ogwo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ogechukwukanma Ogwo

Ogechukwukanmawes Ogwo jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti olóòtú orí ẹ̀rọ rédíò, ó ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bíi olóòtú ètò lorí ẹ̀rọ rédíò Brilla FM, lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Raypower FM.[1][2][3] Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olóòtú ètò orí rédíò fún bíi ọdún méjìlá. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ètò kan tọ́ pẹ̀ ní 'Straight from the Heart', lórí rédíò RayPower FM, ní oṣù kẹrin, ọ́dún 2002. Lẹ́yìn náà, ó di olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ agbóhùngbójìjí, níbi tí ó ti jẹ́ olóòtú àwọn ètò bíi ‘Top 10 Countdown Show’ àti ‘Rock Radio’. Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2003, ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú Brilla 98.9 FM, èyí tó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó ti ṣiṣẹ́ olóòtú àwọn ètò bíi ‘Whistles Of The Night’, ‘The Afternoon Blazing Drive’, ‘Top 8 Countdown’, ‘The Sunday Morning Show’ àti ‘The Super Morning show’ lórí rédíò Brilla FM. Ó ti gbàlejò àwọn olókìkí eléré ìdárayá bíi 2face Idibia, D'banj, Don Jazzy, Ali baba, Mike Ezuruonye, Rita Dominic, Olamide, Kenny & D1, Omawumi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]