Jump to content

Ojukokoro

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ojukokoro: Greed
Fáìlì:Ojukokoro poster.jpg
AdaríDare Olaitan
Olùgbékalẹ̀Olufemi D. Ogunsanwo
Dare Olaitan
Àwọn òṣèréWale Ojo
Tope Tedela
Charles Etubiebi
Seun Ajayi
Ali Nuhu
Shawn Faqua
Somkele Iyamah
Emmanuel Ikubese
Ìyàwòrán sinimáBaba Agba
OlóòtúSeun Opabisi
Ilé-iṣẹ́ fíìmùSingularity Media
House Gabriel Studios
BCI Studios
OlùpínFilmOne Distributions
Déètì àgbéjáde
  • 17 Oṣù Kọkànlá 2016 (2016-11-17) (AFRIFF)
  • 17 Oṣù Kẹta 2017 (2017-03-17) (Nigeria)
Àkókò110 minutes
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish
Yoruba
Bini

Ojukokoro: Greed, jẹ́ fíìmù orílè-èdè Nàìjíríà tó jáde ní ọdún 2016. Ó jẹ́ fíìmù ajẹmọ́-ìà-ọ̀daràn àti ajẹ́mọ́-àwàdà, èyí tí àwọn òṣèré bí i Wale Ojo, Tope Tedela, Charles Etubiebi, Seun Ajayi, Shawn Faqua, Ali Nuhu, Somkele Iyamah, Emmanuel Ikubese àti Afeez Oyetoro kópa nínú rẹ̀. Orúkọ ẹni tó kọ ọ́, tó sì darí rẹ̀ ni Dare Olaitan, Olufemi D. Ogunsanwo sì ló gbe jáde.[1]

Olaitan kọ ìtàn Ojukokoro ní ọdún 2014, èyí sì jẹ́ fíìmù rẹ̀ àkọ́kọ́ tí wọ́n máa gbé jáde. Ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta ọdún 2017 ni wọ́n gbé fíìmù náà jáde.[2][3]

"Ojukokoro dá lórí ìtàn alábòójútó ilé epo kan tó pinnu láti ja àwọn òṣìṣẹ́ rè lólè. Nínú ìrìn-àjò yìí ló ti ṣàwárí pé òun nìkan kọ́ ló ní irú èrò yìí lọ́kàn, tí ó sì tún kíyèsi pé tí ènìyàn bá ní ìdí pàtàkì láti ṣe nǹkan, ìyẹn ò ní kó jẹ́ ohun tó dára."[4]

Ìyàwòrán bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kẹrin ọdún April 2016. Wọ́n sì ṣàgbéjáde ìpolówó lérèfé ti fíìmù náà ní oṣù kẹwàá ọdún 2016.[5] Ní oṣù kìíní ọdún 2017, wọ́n ṣàgbéjáde ìpolówó fíìmù náà ní kíkun.[6]

Ìgbéjáde fún ìwòran

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù Ojukokoro ní àwọn sinimá káàkiri ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta ọdún 2017.

Wọ́n ṣá̀fihàn Ojukokoro ní Metrograph, ní New York, ní osù kẹrin, láti ọjọ́ kẹtàlá títí wọ ọjọ́ karùndínlógún ọdún 2018.

Ní oṣù kẹrin ọdún 2021, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàfihàn rẹ̀ lórí Netflix, ní USA.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Izuzu, Chidumga. "Pulse Movie Review: Mixed with violence and humour; "Ojukokoro" is uniquely entertaining". pulse.ng. Archived from the original on 13 March 2017. Retrieved 23 October 2017. 
  2. "Film Review: In Dare Olaitan’s Ojukokoro, greed is good » YNaija". ynaija.com. 18 March 2017. Retrieved 23 October 2017. 
  3. Staff, Konbini (20 March 2017). "'Ojukokoro (Greed)' Is Proof All Nollywood Needs Is A Good Script". konbini.com. Archived from the original on 23 October 2017. Retrieved 23 October 2017. 
  4. Izuzu, Chidumga. "Nolly Thursdays: Tope Tedela, Seun Ajayi, Beverly Naya attend "Ojukokoro" premiere". pulse.ng. Archived from the original on 15 June 2017. Retrieved 23 October 2017. 
  5. Izuzu, Chidumga. ""Ojukokoro (Greed)": Watch Tope Tedela, Linda Ejiofor, Somkele Idahalama in trailer". pulse.ng. Archived from the original on 25 May 2017. Retrieved 23 October 2017. 
  6. Dare Olaitan (27 January 2017). "OJUKOKORO (GREED) TRAILER MARCH 17TH!". Retrieved 23 October 2017 – via YouTube. 
  7. Oke, Tolu (8 April 2021). "Ojukokoro Set To Make Netflix Debut On Friday". The Culture Custodian (Est. 2014). Retrieved 25 April 2021.