Jump to content

Olúyọ̀lé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Baṣọ̀run Olúyọ̀lé jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn jagunjagun tí ó wá láti ìlú Ọ̀yọ́ sí ìlú Ìbàdàn.

Wọ́n bí Baṣọ̀run Olúyọ̀lé ní Ọ̀yọ́ àtijọ́ sí inú ìdílé Olúkùoyè tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ Àrẹmọbìnrin Àgbọ̀nyín tí ó jẹ́ ọmọ Aláàfin Abíọ́dún nígbà náà . Òun ni ó kọ́kọ́ rí ìlú Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bí ìlú olókìkí yàtọ̀ sí ibùdó ogun. Ìdí rèé tí ó fi fi ìdí ìjọba tó gíríkì múlẹ̀ nígbà náà.[1]

Àsìko rẹ̀ ni àwọn ìlú tí wọ́n wà ní abẹ́ Ìbàdàn gbèrú si. Kò kùnà láti gbé iṣẹ́ àgbẹ̀ lárugẹ, bẹ́ẹ̀ ni ó fi ìpìlẹ̀ ọrọ̀ ajé tí ó nípọn múlẹ̀. Ìdí rèé tí a fi ń pe Ìbàdàn ní "ilé Olúyọ̀lé".[2]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí jagunjagun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Látàrí họ́u họ́ù tí ogun dá sílẹ̀ láàárín àwọn àgbààgbà olóyè ìlú Ọ̀yọ́-ilé láti gorí àpèrè Aláàfin ti Ọ̀yọ́ nígbà náà tí ó ṣófo, èyí ni ó mú kí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láàárín Aláàfin àti Baṣọ̀run Gáà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ọ̀yọ́ ìgbà náà sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn. Fífọ́nká tí àwọn ọmọ Ọ̀yọ́ fọ́n ká yí, tí wọ́n sì ti lọ tẹ̀dó sí oríṣìíríṣìí ibùgbé tí wọn kò sì fẹ́ san ìsákọ́lẹ̀ fún Ọ̀yọ́ mọ́, àsìkò yìí ni Iba Olúyọ̀lé di lààmì-laaka láàrín àwọn jagunjagun. Ó kọ́kọ́ di ìlúmọ̀ọ́ká látàrí ipa tí ó kó láàárín àwọn ọmọ ogun tí wọ́n borí ogun Òwu, ní èyí tí ó sì mú kí ìjọba ilẹ̀ Ẹ̀gbá àti àwọn ìlú bí Ìbàdàn ó ṣubú. Láti bu ọlá fún pẹ̀lú ipa rẹ̀ láti lè jẹ́ kí ìjọba Ọ̀yọ́ tí ó ti ń dẹnụ kọlẹ̀ ó tún gbìnà yá nínú àwọn ogun tí ó mú Ọ̀yọ́ borí ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú-Rẹ́mọ yí ni ó mú kí wọ́n fi jẹ ''Ààrẹ Àgò ilẹ̀ Ìbàdàn''. Òun náà sì fi ara rẹ̀ jẹ oyè ''Òsì-Kakaǹfò'', tí ó sọ ọ́ di ológun apàṣẹ wàá kẹta fún ilẹ̀ Ìbàdàn.[3]

  • Akínwùmí Àtàndá (200) Basọ̀run Olúyọ̀lé Ibadan; Rasmed Publications, ISBN 978-8024-75-0. Ojú-iwé 140.


  1. "Why IBA OLUYOLE Family Of IBADAN Is Popular - Family Head, Alhaji NURENI AKANBI Speaks". City People Magazine. 2017-03-13. Retrieved 2021-07-26. 
  2. "Why Ibadan in praise is called home of Oluyole?". LiveTimes9ja. 2017-09-24. Retrieved 2021-07-26. 
  3. "Origin of Ibadan Land". Welcome To MACOS Urban Mangement Consultancy. 2008-06-25. Retrieved 2021-07-26.