Jump to content

Olaoluwa Abagun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Olaoluwa Abagun
Ọjọ́ìbíOlaoluwa Abagun
August 24, 1992
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́Obafemi Awolowo University
Iṣẹ́Lawyer, Women rights activist

Olaoluwa Abagun jẹ́ agbẹjọ́rò Nàìjíríà àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin.

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé àti ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Abagun ní Èkó, ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní 2008 kúrò ní Queens’ College Lagos, níbi tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ “Outstanding Service to College Life Award” gẹ́gẹ́ bí igbákejì olórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lóbìnrin ilé-ẹ̀kọ́ náà. Ní kété lẹ́yìn náà, ó tẹ̀síwájú sí Yunifásítì Obafemi Awolowo University níbi tí ó ti gba Bachelor of Laws (LL.B) Degree,[1] tí ó sì ṣe Master of Arts degree nínú Gender and Development ní Institute of Development Studies, University of Sussex.[2] Kìrìtẹ́ẹ́nì ni.[3]

Wọ́n bí Abagun sínú ìdílé ẹlẹ́sìn méjì. Bàbá rẹ̀ jẹ́ Mùsùlùmí, nígbà tí màmá rẹ̀ jẹ́ Kìrìtẹ́ẹ́nì.[4] Òun ni ọmọ obìnrin kan ṣoṣo nínú ọmọ mẹ́rin àwọn òbí rẹ̀. Nígbà tí ó ń dàgbà, ó ṣàlàyé ìgbà kékeré rẹ̀ pé wọ́n mú bí wọ́n ṣe mú àwọn arákùnrin rẹ̀, bí àwọn òbí rẹ̀ ti mú u pẹ̀lú ìkọbi-ara kékeré sí akọ-ń-bábo.[5] Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò mìíràn, ó fi hàn pé àwọn òbí rẹ̀ láìmọ̀ fi ẹsẹ rẹ̀ sí ojú ọ̀nà ìṣègbèfábo. Ó tọpasẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ fún ìjàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn sí ọ̀rọ̀ lórí níní òye child rights act nígbà tí ó wà ní 13.[5]

Ní 15, ó pàdé pẹ̀lú Gómìnà nígbà náà, Babatunde Fashola àti ìgbìmọ̀ rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀rọ Kọ̀m̀pútà mọyì rẹ̀. Abagun ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí i ara ìwúrí fún ìpinnu rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ alágbàwí fún àwọn obìnrin.[4]

Ìjàfẹ́tọ̀ọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kí ó tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde pẹ̀lú pẹ̀lú dìgíìrì law ní 2015, Abagun kọ àwọn ìwé tí ó dá lé ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin, ó sì jẹ́ lára àwọn tí ó wà ní ẹsẹ̀ tó kẹ́yìn 2014 ní "Ìdíje Àròkọ Àyájọ̀ Ọ̀dọ́ Áfíríkà" fún iṣẹ́ rẹ̀ tí ó pè ní Policies on the Empowerment of Young Women in Africa: The Missing Piece in the African Jigsaw. Ó tún dá "Girl Pride Circle" sílẹ̀, ẹgbẹ́ tí ó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ní Nàìjíríà .[6]

Ní oṣù kẹta 2016, ní UN Commission lórí Ipò àwọn Obìnrin, ìfágbára wọ àwọn ọmọbìnrin, ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ Safe Kicks Initiative: Adolescent Girls Against Sexual Violence, tí ó ń sapá láti kọ́ àwọn afarapa ìwà ipá ìbálòpọ̀ àti àwọn obìnrin lápapọ̀ lórí bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo ara wọn nípa kíkọ́ martial arts.[7][8] Ní oṣù kejè 2016, wọ́n ròyìn pé ó ti ń kọ́ ó lé ní ọ̀dọ́mọdébìnrin 250 láti ara ètò yìí. Ó tún di ará Nàìjíríà kan ṣoṣo tí wọ́n fún ní owó ìgbọ̀wọ́ láti Women Deliver organization.[9] Ó tún sọ̀rọ̀ ní eto 72 ti United Nations General Assembly pẹ̀lú ọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ akọ-ń-bábo.[10]

Ní oṣù kejè 2017, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ó tayọ láti sọ̀rọ̀ lórí àkọ́lé Fast Forward: Preparing the World to Come with members of UK parliament. Ó mú wá sí àkíyèsí pé òun yóò sa ipá láti rí i dájú pé "ìbádọ́gba takọtabo" wà, àti ìdàgbàsókè nínú ìkọbi-ara àwọn obìnrin Nàìjíríà sí ìṣèlú nípa ṣíṣe àgbàwí fún àlàáfíà tí ó dára sí i, ẹ̀kọ́ àti èròǹgbà ìjọba.[11]

Lórí ìṣègbèfábo, ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i "ríridájú pé gbogbo ènìyàn, àti akọ àti abo lẹ́tọ̀ọ́ sí ààyè tí ó tó láti ṣàwárí agbára wọn ní kíkún", nígbà tí ó ń ṣe ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ Chimamanda Ngozi Adichie pé "gbogbo wa pátá ni kí a jẹ́ aṣègbèfábo". Ó tún sọ pé kí a má rí ènìyàn pẹ̀lú ìtẹnumọ́ akọ tàbí abo ní ọkàn.[12] Ó ṣàlàyé ìṣègbèfábo gẹ́gẹ́ bí i "àbá tí ó mú ìbáṣepọ̀ àwùjọ àti ọrọ̀-ajé ọgbọọgba fún mùtúmùwà gẹ́gẹ́ bí olúborí, láìfì ti takọtabo ṣe", pẹ̀lú àkíyèsí pé "kì í ṣe ogun takọtabo" gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ṣe ń ṣì í gbọ́.[10] Ní oṣù kìíní 2018, ó sọ̀rọ̀ lórí bí àìnífẹ̀ẹ́sí ìṣèlú àwọn obìnrin Nàìjíríà ò ṣe tẹ́ ẹ lọ́rùn,ó sì gbà wọ́n níyànjú láti kópa nínú Ìdìbò gbogboogbò Nàìjíríà, 2019.[13]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Ms Olaoluwa Abagun". Wise Initiative. Retrieved 2 March 2019.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Olaoluwa Abagun". Women Deliver. Retrieved 4 January 2019.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Kumolu, Charles (October 18, 2017). "ABAGUN: Fashola’s whispers added more springs to my legs". Vanguard (Nigeria). Archived from the original on November 8, 2017. Retrieved November 9, 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. 4.0 4.1 Kumolu, Charles (October 18, 2017). "ABAGUN: Fashola’s whispers added more springs to my legs". Vanguard (Nigeria). Archived from the original on November 8, 2017. Retrieved November 9, 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. 5.0 5.1 Kalejaiye, Esther (August 27, 2016). "I am an unapologetic feminist" Olaoluwa Abagun". The Guardian. Archived from the original on November 12, 2017. Retrieved November 9, 2017. 
  6. "Olaoluwa Abagun - Safe Kicks Initiative: Adolescent Girls Against Sexual Violence". Women Deliver. Retrieved November 9, 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. Attia, Karin (March 23, 2016). "Who runs the world? Girls! Not at the UN CSW". Open Democracy. Retrieved November 9, 2017. 
  8. Sanders, Linley (15 March 2018). "These Young Women Prove #MeToo Isn't Just Happening in the U.S.". Teen Vogue (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 27 December 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "How Olaoluwa Abagun Is Raising 250 Adolescent Girls To Help Prevent Sexual Violence In Alimosho". women.ng. July 21, 2016. Archived from the original on October 27, 2016. Retrieved November 9, 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  10. 10.0 10.1 Kumolu, Charles (October 18, 2017). "ABAGUN: Fashola’s whispers added more springs to my legs". Vanguard (Nigeria). Archived from the original on November 8, 2017. Retrieved November 9, 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  11. "Six Nigerians tapped to debate global issues in UK Parliament". Premium Times. July 21, 2017. Retrieved November 9, 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. Kalejaiye, Esther (August 27, 2016). "I am an unapologetic feminist" Olaoluwa Abagun". The Guardian. Archived from the original on November 12, 2017. Retrieved November 9, 2017. 
  13. "Female leaders fear women being sidelined in Nigeria's 2019 elections". Reuters. Retrieved 2018-02-01. 
Wikiquote logo
Wikiquote logo
Nínú Wikiquote a ó rí ọ̀rọ̀ tójẹmọ́: