Olufunke Adeboye
Olufunke Adeboye | |
---|---|
Born | Olufunke Ojo Ibadan |
Nationality | Nàìjíríà |
Institutions | Yunifásitì ìlú Èkó |
Notable awards | 2012 Gerti Hesseling Prize |
Olufunke Adeboye jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ẹ̀ka fún ìtàn ní Yunifásítì ìlú Èkó, Nàìjíríà.[1] Òun ni adarí Faculty of Arts ilé-ìwé náà lọ́wọ́ lọ́wọ́.[2] Àwọn ǹkan tí Adeboye fẹ́ràn láti ma ṣe ìwádìí nípa ni ìtàn Nàìjíríà kí ó ti pé àwọn òyìnbó amúnisìn ko Nàìjíríà lẹ́rú, nígbà tí wọ́n kọ lẹ́rú àti nípa bí ìjọ pentecostal ṣe gbilẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Africa.[3]
Ìpìlẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Olufunke Adeboye (orúkọ àbísọ rẹ̀ ni Òjó) ní Ibadan, Nàìjíríà. Ó lọ ilé ìwé Our Lady's Girls' High School, Ile-Ife, ní ìpínlẹ̀ Osun, Nàìjíríà ní odún 1983. Ó lọ Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, Nàìjíríà níbi tí ó ti gba àmì ẹyẹ Bachelor of Arts (B.A.), Masters of Arts (M.A.), àti Dókítà(PhD) nínú ìmò ìtàn ní ọdún 1988, 1990, àti 1997.[3] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi igbákejì olùkọ́ ní Yunifásitì Ìpínlẹ̀ Ogun (tí orúkọ rẹ̀ ti yí padà sí Olabisi Onabanjo University), Ago Iwoye, Nàìjíríà ní ọdún 1991. Ní ọdún 1999, ó lọ sí ẹ̀ka ìtàn ní Yunifásitì ìlú Èkó gẹ́gẹ́ bi olùkọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń gòkè nínú iṣẹ́ rẹ̀ kí a tó sọ di ọ̀jọ̀gbọ́n ní oṣù kẹta ọdún 2011.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Contributors" (in en). Religion on the Move!: New Dynamics of Religious Expansion in a Globalizing World 15: 461–466. 2013-01-01. doi:10.1163/9789004243378_025. ISBN 9789004243378.
- ↑ "VICE CHANCELLOR APPROVES THE RE-APPOINTMENTS AND APPOINTMENTS OF DEANS AND SUB–DEANS". University of Lagos. Retrieved 12 January 2020.
- ↑ 3.0 3.1 "Olufunke Adeboye - Google Scholar Citations". scholar.google.com. Retrieved 2020-01-12.
- ↑ "Staff Directory: Adeboye Olufunke". University of lagos. Retrieved 13 January 2020.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]