Jump to content

Oluremi Sonaiya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Remi Sonaiya
Ọjọ́ìbí2 Oṣù Kẹta 1955 (1955-03-02) (ọmọ ọdún 69)
Ibadan, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gíga
Iṣẹ́
  • Olóṣèlú
  • Ònkọ̀wé
  • Onímọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́
Ìgbà iṣẹ́1984 títi di àsìkò yìí
Political partyKOWA
Olólùfẹ́Babafunso ṣonaiya
Àwọn ọmọ2
Websiteremisonaiya.com

Olúrẹ̀mí Comfort Sónáìyà, a bi ní ọjọ́ kejì, osù keta, odún 1955, Ó jẹ olóṣèlú kan gbòógì ní orílè-èdè Nàíjírìa, ọ̀mọ̀wé àti ònkọ̀wé ni. [1] Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó díje fún igbákejì olòrí orílẹ̀-èdè Nàíjírìa ní abẹ́ àsìá ẹgbẹ́ KÓWÀ ní ọdún 2015. Ó fìdí rẹmi ní ọdún 2019 tí ó tún jáde gẹ́gẹ́ bíi aṣojú ẹgbẹ́ náà tí Dókítà Adésínà Fágbénró Byron sì gbégbá orókè.

Ìgbésí ayé àti ètò-ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sónáìyà jẹ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn, olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ , Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ alápéjúwe sẹnti lukes, Mòlété, Ìbàdàn àti ilé ẹ̀kọ́ girama Sẹnti Annes, Mòlété́ bakaánà ní ìlu Ìbàdàn. Ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Ilé Ifè (tí à ńpè ní Obáfémi Awólọ́wọ̀ Unifásítì báyìí) níbi tí ó ti kẹ́kòó èdè Faransé, o parí ní ọdún 1977. [2]

Ó gba másításì ti Art nínú Lítírésọ̀ Faransé ní Unifásítì Cornell ní Amẹ́ríkà àti masításì ní Lìngúísítíkì ní Unifásítì Nàìjíríà ní ọdùn 1984. Ó Padà sí Cornell ní ọdún 1988 láti lépa ètò ẹkọ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú Lìngúísítíkì. [3]

Ní ọdún 1982, wọ́n gbàá síṣé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ gẹ́gẹ́ bíi igbákejì olùkọ́ ní abala àwọn tí ó ń mójú tó ètò ẹ̀kọ́ Èdè àjèjì, ó padà di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú èdé faransé àti lìngùísítíkì ní ọdún 2004. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú awọn ọmọ ẹgbẹ Alexander von Humboldt Foundation, níbití wọ́n ti sọ ọ́ di Ambassador àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì láti 2008 sí 2014. [3]

Ní ọdún 2010, Ó fẹ̀yìn tì kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ní Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Unifásitì, Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú KÓWÀ , wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi alukoro ẹgbẹ́, wọ́n sì tún fàá kalè ní ọdún 2015 gẹ́gẹ́ bií olùdíje fún igbákeji olórí orílẹ̀ èdè lábẹ́ ẹgbẹ́ náà. Sónáìyà se ipò kej̀ilá níbi ìdìbo pè|lú ìbò mẹ́rin dín lọgọrin lé lẹ́ gbẹ̀rún mẹ́tàlá.

Àwọn àtẹ̀jáde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sónáìyà ní abala tí ó ń siṣẹ́ le lóri nínú ìwé ìròyìn ayélu já́ra Nàij́íria, Sónáíya tí ṣe atèjade opolopo iwe pèlú.    

  • Àṣà àti Idanimọ lórí Ipele: Àwọn ibakcdun Àwọn ìṣèlú-ìṣèlú àti Àwọn Iṣẹ-iṣe ní Àwọn Iṣẹ iṣe Àtijọ́ Ìlú Áfríkà ( Conforming Arts of 2001) (2001) ISBN   9789782015785
  • Àwọn nkan Èdè: Ṣàwárí Àwọn ìwòn ti Multilingualism (2007) [4]
  • Ìgbékelẹ̀ láti Gbà   - Àwọn ìyípadà lórí Ìgbésì ayé àti Aṣáájú ní Nigeria (2010)  ISBN 9789789115983    
  • Fojúsi àìfọ̀kànbalẹ̀   - Nigeria àti Àwọn Ẹgàn miíràn (2013) ISBN 9785108473    
  • Ìsàlẹ̀-ọjọ Naijiria   - Orile-ede yíì Gẹdọ Dìde! (2014) ISBN 9789785205732    

Ọkọ rẹ̀ ni Babafúnsọ́ Sónáìyà, ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ sáyẹ́nsì ẹranko, won bí ọmọkùnrin kan àti obìnrin kan àti àwọn ọmọ-ọmọ. [2]

Àwọn ìtọ́kasì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]