Osinlokun
Ìrísí
Ọṣìnlókùn | |
---|---|
Oba of Lagos | |
Odun 1821 sí 1829 | |
Adele | |
Idewu Ojulari | |
[[Royal house|]] | Ado, Ologun Kutere |
Father | Ologun Kutere |
Born | Èkó |
Died | Ọdún 1829 Èkó |
Burial | Benin |
Ọba Ọṣìnlókùn tàbí Ẹṣinlokùn (tí ó kú lọ́dún 1829) jọba Èkó láti ọdún 1821 sí 1829. Bàbá rẹ̀ ni Ọba Ológun Kútere, àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ni Ọba Adele àti Akitoye, èyí ló sọ ìdílé Ọba Ológun Kutere tóbi ju àwọn ìdílé ọba Èkó tí wọ́n kù lọ.[1] Lára àwọn ọmọ Ọṣìnlókùn ni Idewu Ojulari, Kosoko, àti Opo Olu.
Gígorí oyè
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lọ́dún 1820 tàbí 1821, Ọṣìnlókùn lo anfaani àṣìṣe àbúrò rẹ̀, Ọba Àdèlé, tí wọ́n wọ́n dá lẹ́bi fún dídá Eégún sílẹ̀ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́kun láti máa ṣe é lásìkò náà[2] láti fipá gbàpò Ọba nínú ìdìtẹ̀ jọba. Wọn lé Àdèlé kúrò ní ìlú lọ sí Badagry níbi tí ó ti di olórí ìlú níbẹ̀. Nígbà tí ó wà ní Badagry, Àdèlé gbìyànjú láti fipá gbàpò ọba ìlú Èkó ṣùgbọ́n kò ri ṣe.
Ikú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọsinlokùn kú lọ́dún 1829, tí ọmọ rẹ̀ Idewu Ojulari sì jọ̀ba lẹ́yìn rẹ̀.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Mann, Kristin (2007). Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760-1900. Indiana University Press, 2007. p. 45. ISBN 9780253348845.
- ↑ Smith, Robert (January 1979). The Lagos Consulate, 1851-1861. University of California Press, 1979. pp. 14–17. ISBN 9780520037465.