Jump to content

Akitoye

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:EngvarB

Akitoye
Reign 1841 - 1845
1851 - 1853
Coronation 1841
Predecessor Oluwole 1st term predecessor
Kosoko 2nd term predecessor
Successor Kosoko 1st term successor
Dosunmu 2nd term successor
Father Ologun Kutere
Born Lagos
Died Lagos
Burial Lagos
Religion Ifá

Akítóyè (kú lọ́jọ́ kejì oṣù kẹsàn-án ọdún 1853), tí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń ṣìpè nígbà mìíràn ní Akíntóyè, jẹ Ọba Eko ní ẹ̀mẹjì; ó kọ́kọ́ jọba láti ọdún 1841 sí 1845, lẹ́yìn náà, ó tún jọba láti ọdún 1851 sí 1853. Bàbá rẹ̀ ni Ọba Ologun Kutere, àwọn àbúrò rẹ̀ sì ni àwọn Ọba aládé Ọṣìnlokùn àti Àdèlé Àjọsùn.[1]

Wọ́n pa Ọba Olúwọlé ọdún 1841 nígbà tí àrá kan sán tí nǹkan bí àgbá ìbọn kan sì bẹ́ ní ààfin Ọba. Àwọn Afọbajẹ ìbá ìránṣẹ́ pe Ọmọba Kosoko láti wá gorí ìtẹ́ bàbá rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì tí ó mọ ibi tó wà. Yàtọ̀ sí èyí, ìjà láàárín Eletu Odibo ati Kòsọ́kọ́ fàá tí Eletu fi dènà Kòsọ́kọ́ láti jọba. Nítorí ìdí èyí, wọ́n fi Akítóyè, ẹni tí ó jẹ́ àbúrò bàbá Kòsọ́kọ́ àti àbúrò sí Ọṣinlokùn jỌba Èkó.[2][3] Akíkanjú oníṣòwò àti olówó ẹrú, Madam Tinubu, tí ó ti kọ́kọ́ fẹ́ Adele lọ́kọ gbárùkù ti àbúrò ọkọ rẹ̀, Akítóyè láti jọba dípò Kòsọ́kọ́.[4][5]

Bí Kòsọ́kọ́ ṣé lé Akítóyè kúrò lórí oyè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn olóyè, pàápàá jù lọ Eletu Odibo gbìyànjú láti tako Ìlà kàkà Akítóyè láti parí ìjà pẹ̀lú àbúrò bàbá ẹ́, ṣùgbọ́n kò gbà, ó fi àìmọ̀kan rẹ̀ parí ìjà náà pẹ̀lú Kòsọ́kọ́, ó sì pàṣẹ pé kí Kòsọ́kọ́ padà sí ìlú Èkó. Kòsọ́kọ́ wọ ọkọ̀ ojú omi tí gbajúmọ̀ olówò ẹrú, José Domingo Martinez padà sí ìlú Èkó. Akítóyè gbìyànjú láti tu Kòsọ́kọ́ lójú pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹ̀bùn, kódà, ó dá a lọ́lá oyè nípa fífi i jẹ òye Ọlọ́jà tí Eréko. Kòsọ́kọ́ yára lo anfaani yìí láti láti wá ojú rere àwọn olóyè ajagun, àti àwọn ará ìlú tí wọ́n jẹ́ Mùsùlùmí. Nígbà tí ó yá, gbajúmọ̀ tí Kòsọ́kọ́ gbajúmọ̀ láàárín àwọn olóyè sí ní kọ Eletu Odibo nínú, loofahri ìdí èyí, ó gba ìlú Badagry; lọ. Èyí kò tẹ́ Ọba Akítóyè lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ló pàṣẹ fún Eletu Odibo láti padà sí Èkó, èyí bí Kòsọ́kọ́ nínú, ó sì pinnu pé bí Eletu Odibo bá padà sí Èkó, òun yóò dé ara òun ládé, tí òun yóò sì jọba.

Wàhálà yìí bẹ́ sílẹ̀ láàárín Ọba Akítóyè àti Ọmọba Kòsọ́kọ́. Lásìkò náà, Kòsọ́kọ́ rán aláago rẹ̀ láti kéde káàkiri igboro Èkó pé "kí wọ́n kìlọ̀ fún màjèsín tí wọ́n fi jọba láàfin pé kó ṣọ́ra rẹ̀, pé bí kò bá ṣọ́ra, yóò jìyà, yóò jẹwé e yá". Akítóyè náà kò gbẹ́nu rọ̀, òun náà rán aláago rẹ̀ pé kó lọ kéde ikilọ pé, "a ti ti òjé bọ olóòṣà lọ́wọ́, kò sí baba ẹni tí ó lè bọ́ ọ". Inú bí Kòsọ́kọ́, ó sì fèsì pé, ó sì fèsì pé bí òjẹ́ ò bá ṣe é bọ́, òun yóò gé e".[3]

Rògbòdìyàn yìí mú Kòsọ́kọ́ àti àwọn sọ̀ǹgbè rẹ̀ dá wàhálà ogún Olómirò silẹ n'ilu Èkó lọ́dún. Àwọn sọ̀ǹgbè Kòsọ́kọ́ kógun ja Ọba Akítóyè láàfin rẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Ogun yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí Akítóyè fi salo gba orí omi ọ̀sà, lápá àríwá gba etí omi Agboyi pẹ̀lú iranlowo Òṣòdì Tápà, tí ó jẹ́ Balógun Kòsọ́kọ́. Oshodi Tapa parọ́ fún Kosoko pé lo ìṣújú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ láti sá lọ. Akítóyè kọjá sí Abẹ́òkúta, níbi tí wọ́n ti gbà á láàyè láti ṣe àtìpó.[2] ìbẹ̀rù Akítóyè mú Kosoko, ó sì pàṣẹ fún àwọn Ẹ̀gbá láti gé orí Akítóyè wá fún òun, ṣùgbọ́n àwọn Ẹ̀gbá kọ̀. Nígbà tí ó di ọdún 1845,àwọn Ẹ̀gbá ran Akítóyè lọ́wọ́ láti sá lọ sí Badagry,[6] ìlú àwọn ogunléndé àwọn ọmọ Èkó. Ní Badagry, Akítóyè wá àwọn ọmọ ogún mọ́ra pẹ̀lú iranlowo àwọn ajiyinrere òyìnbó àti ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí John Beecroft ṣojú fún.

Madam Tinubu àti àwọn alatileyin Akítóyè náà sá lọ fara pamó sí Badagry nígbà tí Kosoko jọba Èkó.[7]

Àtìpó ní Badagry, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òyìnbó Bìrìtìkó, àti ète okoòwò ẹrú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú láti gbapò ọba rẹ̀ ní Èkó padà láti Badagry kò ṣe é ṣe, Akítóyè lọ béèrè fún iranlọwọ láti ọ̀dọ̀ àwọn Aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, pàápàá jùlọ Gómìnà tí Cape Coast, ó sì ṣe àdéhùn láti tẹ̀lé ìlànà okoòwò ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, pàápàá jùlọ, àdéhùn láti fòpin sí okoòwò ẹrú.[8]

Nígbà tí ó di ọdún oṣù Kejìlá 1850, Akítóyè tún sìpẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì :

Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ kí ẹ fi ṣe ìrànlọ́wọ́ fúnmi nì wọ̀nyí..., wípé ẹ yóò gbàjọba ìlú Èkó, ẹ yóò sì ri àsíyá ilẹ̀ bọlẹ̀ níbẹ̀, àti pé, ẹ yóò dámi padà gẹ́gẹ́ bí ọba aládé ìlú Èkó pẹ̀lú ààbò tó péye, bí ẹ bá ṣe èyí, màá fọwọ́ sí ìwé àdéhùn láti fòpin sí okoòwò ẹrú, tí màá sì máa bá yín ṣòwò tí ó bá òfin mu.[8]

Ìrànlọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti bí wọ́n ṣe dá Akítóyè padà sí ipò Ọba ìlú Èkó lẹ́ẹ̀kejì lóṣù Kejìlá ọdún 1851

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oríṣiríṣi ìgbésẹ̀ ló wáyé láti ọwọ àwọn ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Akítóyè, tí ó ti ṣe àdéhùn láti fòpin sí okoòwò ẹrú, láti lè padà sórí ìtẹ́ Ọba ìlú Èkó lẹ́ẹ̀kejì. Àwọn òyìnbó ajíyìnrere ìjọ Anglican ni Badagry àti àwọn oníṣòwò ìlú Ẹ̀gbá àti Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ò fẹ́ ìdíwọ́ fún òwò wọn di pàǹpá pọ̀, wọ́n sì ran Akítóyè lọ́wọ́ nílùú Èkó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbiyanju Akítóyè láti takò fífi òpin sí okoòwò ẹrú jẹ́ ìwà ìmọtaraeninìkan, èyí tí ó tako òyìnbó ọ̀rẹ́ rẹ̀ ara ìlú Gẹ̀ẹ́sì, Domingo Martinez, tí ó ti fìgbà kan ràn án lọ́wọ́ láti gba ipò ọba rẹ̀ padà ṣùgbọ́n tí kò ṣeé ṣe lọ́dún 1846.[9]

Lọ́jọ́ kerindinlogbon oṣù Kejìlá ọdún 1851, ọjọ́ tí wọ́n ti wá sọ di ọjọ́ ìkógun ja Èkó tàbí ọjọ́. Ọjọ́ burúkú ni ọjọ́ náà, Ọba Kòsọ́kọ́ sa gbogbo agbára rẹ̀, ṣùgbọ́n pàbó ló jásí, nígbà tí ó di ọjọ́ kejidinlogbon oṣù Kejìlá ọdún 1851,ogun yìí, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ogun Ahóyaya tàbí Ogun Agidingbì borí Kòsọ́kọ́, tí Kòsọ́kọ́ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sálọ sí Ìjẹ̀bú. Lẹ́yìn èyí, wọ́n dá Akítóyè padà gẹ́gẹ́ bí ọba ìlú Èkó lẹ́ẹ̀kejì.

Nígbà tí ó di ọjọ́ kìíní oṣù kìíní odun 1852,Akítóyè fọwọ́ sí Ìwé Àdéhùn Láàárín Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Èkó láti fòpin sí okoòwò ẹrú.

Ikú àti ipa rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Akítóyè kú lọ́jọ́ kejì oṣù kẹsàn-án ọdún[10] lẹ́yìn ikú rẹ̀, ọmọ rẹ̀ Dòsùmú jọba. Ọba Dòsùmú gbàgbọ́ pé ewọ ni àwọn olóyè alátìlẹ́yìn Ọba àná, Kòsọ́kọ́: Òṣòdì Tápà, Ajéníà, àti Ipossu fún bàbá òun, Akítóyè jẹ.[11] Ṣùgbọ́n Jean Herskovits ní tirẹ̀ lérò pé Akítóyè pa ara rẹ̀ ni nígbà tí ó rí i pé gbajúmò òun ń dínkù nílùú Èkó, àti pé nígbà tí ó rí i pé òun kò lé mú àdéhùn tí ó bá àwọn Òyìnbó ṣe ṣẹ dojú àmì .[12]

Láti ṣe ayẹyẹ ìrántí ikú rẹ̀, wọ́n gbé Ẹ̀yọ̀ àkọ́kọ́ jáde ní Èkó.[13] Ọmọọmọ Akítóyè, Ìbíkúnlè Akítóyè jọba Èkó láti ọdún 1925 sí 1928.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Mann, Kristin (2007). Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760-1900. Indiana University Press, 2007. p. 45. ISBN 9780253348845. 
  2. 2.0 2.1 Smith, Robert (January 1979). The Lagos Consulate, 1851-1861. University of California Press, 1979. pp. 14–17. ISBN 9780520037465. 
  3. 3.0 3.1 Mann, Kristin (26 September 2007). Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760--1900. Indiana University Press, 2007. pp. 47–48. ISBN 9780253117083. 
  4. Kaplan, Flora S. (1997). Queens, queen mothers, priestesses, and power: case studies in African gender. New York Academy of Sciences, 1997. p. 8. ISBN 9781573310543. 
  5. Nelson; McCracken. Order and disorder in Africa: papers of the A.S.A.U.K. Biennial Conference, hosted by the Centre of Commonwealth Studies, University of Stirling, 8-10 September 1992, Volume 1. SOAS, University of London, 1992. p. 26. 
  6. The Church Missionary Record, Volume 17. p. 225. https://books.google.com/books?id=5MEPAAAAIAAJ&pg=PA225. 
  7. Akioye, Seun. "Madam Tinubu: Inside the political and business empire of a 19th century heroine". The Nation. 
  8. 8.0 8.1 Kopytoff, Jean Herskovits. A preface to modern Nigeria: the "Sierra Leonians" in Yoruba, 1830-1890. University of Wisconsin Press, 1965. pp. 73–74. 
  9. Smith, Robert (January 1979). The Lagos Consulate, 1851-1861. University of California Press, 1979. p. 21. ISBN 9780520037465. 
  10. Akyeampong, Emmanuel Kwaku; Gates, Henry Louis (2012). Dictionary of African Biography. 6. OUP USA. p. 148. ISBN 9780195382075. https://books.google.com/books?id=39JMAgAAQBAJ&q=akitoye+died+1853&pg=PA148. Retrieved 26 November 2016. 
  11. Mann, Kristin (2007). Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760-1900. Indiana University Press, 2007. p. 97. ISBN 9780253348845. 
  12. Kopytoff, Jean Herskovits. A preface to modern Nigeria: the "Sierra Leonians" in Yoruba, 1830-1890. University of Wisconsin Press, 1965. p. 82. 
  13. Williams, Lizzie (2008). Nigeria (New ed.). Chalfont St. Peter: Bradt Travel Guides. pp. 148. ISBN 978-1-84162-239-2. https://archive.org/details/nigeria0000will.