Rahmon Adédoyin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Rahmon Adedoyin
Ọjọ́ìbíRahmon Adegoke Adedoyin
1 Oṣù Kínní 1957 (1957-01-01) (ọmọ ọdún 65)
Ile-Ife, Osun State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ife
All Saints University School of Medicine
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́1990–present
Notable workOduduwa University
The Polytechnic, Ile-Ife

Ọmọba Rahmon Adégòkè Adédoyin ẹni tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kínì oṣù Kíní, ọdún 1957 (born January 1, 1957) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè is a Nàjíríà. Olùkọ́ni, àti bajú-gbajà oníṣòwò ,bákan náà ni ó jẹ́ olùdásílẹ̀ iké-ẹ̀kọ́ Fásitì Odùduwà àti ilé-ẹ̀kọ́ gbogb-nìṣe Polytechnic, ní Ilé-Ifẹ̀[1] Nínú ìtàkurọ̀sọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣojú ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn Vanguard, Rahmon fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé Ọba Okùnadé Ṣìjúadé tí ó wàjà kọjá nílé-Ifẹ̀ ni ó yan ọòun gẹ́gẹ́ bí Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ ṣáájú kí ó tó gbésẹ̀ nítorí iṣẹ́ ìdàgbà-sókè ribiribi tí òun gbé ṣe ní ìlú náà, pàápàá jùlọ nílẹ̀ Yorùbá lápapọ̀.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé, ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Rahmon Adégòkè ni wọ̀n bí nídìílé ọba Akui, ní Ilé-Ifẹ̀Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun[3] níbi tí ó ti parí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó tẹ̀ síwájú nílé-ẹ̀kọ́ Fásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ níbi tí ó ti gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Sáyẹ́nsì ní ọdún 1983, lẹ́yìn èyì ni ó tú kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìṣirò ( Mathematics Education). Ẹ̀wẹ̀, ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ fásitì Centurion International ní orílẹ̀-èdè California, níbi tí ó ti gba oyè ìmọ̀ ẹlẹ́kej (master's degree), tí ó sì tún gba oyè ìmọ̀ ọ̀mọ̀wé ( doctorate degree) nílé ẹ̀kọ́ All Saints University School of Medicine, New York City, ní ọdún 1966.[4]

Pẹ̀lú ìgbìyànjú rẹ̀ láti gbẹ́ ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ sókè ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ó dá ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe ( Polytechnic), Ile-Ife kalẹ̀ ní ọdún 1984 tí ó sì dá Fásitì Oduduwa náà kalẹ̀ ní ọdún 2009. Rahmon jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn Industrial Statisticians ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[4]

Àwọn ìtọ̀ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]