Jump to content

Ronke Odusanya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ronke Odusanya
Ọjọ́ìbíRonke Odusanya
3 Oṣù Kàrún 1973 (1973-05-03) (ọmọ ọdún 51)
Ìpínlẹ̀ Ògùn
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaFederal Government Girls College, Nigeria
Iṣẹ́
  • Òṣèrébìnrin
  • Olóòtú
  • Aláwàdà
Ìgbà iṣẹ́2000-títí àkókò yìí
Notable work
  • Jenifa (2008)
  • Astray (Isina) (2016)
  • A Girl's Note (2016)

Ronke Odusanya tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 1973 (3rd May 1973) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá, ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà,[1][2][2][3][4][5] film producer and stage performer.[6]

Ìgbé-ayé àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Rónkẹ́ ní ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 1973, (3rd May 1973) ní Ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó kàwé ní St. Benedict Nursery & Primary School àti Federal Government Girls College, Akure.[7] Rónkẹ́ tún tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ ní Ifáfitì Ọlábísí Ọnàbáńjọ, níbi tí ó ti gba ìwé-ẹri nínú ìmọ̀ Iṣẹ́ Ìròyìn.[8]

Aáyan nínú iṣẹ́ tíátà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Rónkẹ́ Òdúsànyà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, lẹ́yìn tí ó kàwé gbàwé ẹ̀rí. Wọ́n fún un ní Flakky Idi Dowo gẹ́gẹ́ bí orúkọ ìnagijẹ lágbo àwọn òṣèré sinimá àgbéléwò lẹ́yìn tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí Fathia Balogun kọ, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Folúkẹ́" lọ́dún 2006.[9] Lẹ́yìn èyí, Rónkẹ́ kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí Adébáyọ̀ Sàlámì, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ọ̀gá Bello kọ, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Kerikeri". Lọ́dún 2001 ni ó kọ́kọ́ kópa gẹ́gẹ́ bí òṣèré Nollywood, nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Baba Ologba".[10][10] Lẹ́yìn ìgbà náà, ó ti kópa nínú ẹgbẹlẹmùkú sinimá àgbéléwò, lára wọn ni ''Jenifa níbi tí ó ti kópa gẹ́gẹ́ bí Becky,[11][12] Twisted, àti A Girl's Note, àti àwọn sinimá-àgbéléwò mìíràn. Lọ́dún 2017, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí òṣèrébìnrin tí ó dára jù gẹ́gẹ́ bí olú-ẹ̀dá ìtàn nínú sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá, fún ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Àìlátúnṣe.[13]

Àtòjọ àwọn sinimá àgbéléwò tí ó ti kópa

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Twisted (2007)
  • Jenifa (2008)
  • Láròdá òjò (2008)
  • Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo (2009)
  • Astray (Ìṣìnà) (2016)
  • A Girl's Note (2016)[14]
  • Àṣàkẹ́ Òní Bread (2016)
  • The Stunt (2017)
  • Ayọ̀mídé (2017)[15]
  • Obsession (2017)
  • Àìlátúnṣe (2017)
  • Olóríire (2018)
  • Owó Agbára (2018)
Odun Amin-eye Abala fiimu Abajade
2017 Best of Nollywood Awards Òṣèrébìnrin tó pegedé jù gẹ́gẹ́ bí olú-ẹ̀dá ìtàn nínú sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá[16] Àìlátúnṣe Yàán

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Nwachukwu, John Owen (20 November 2016). "Popular actress, Ronke Odusanya reveals what men call her breasts". Dailypost Nigeria. https://dailypost.ng/2016/11/20/popular-actress-ronke-odusanya-reveals-men-call-breasts/. Retrieved 20 April 2019. 
  2. 2.0 2.1 Obiuwevbi, Jennifer (17 October 2015). "Yoruba Movie Actress Ronke Odusanya Looks Lovely in these Makeup Photos!". Bellanaija. https://www.bellanaija.com/2015/10/yoruba-actress-ronke-odusanya-looks-lovely-in-these-makeup-photos/. Retrieved 20 April 2019. 
  3. Adedosu, Adekunle (23 December 2014). "Ronke Odusanya finally speaks on alleged husband-snatching scandal". TheNet. http://thenet.ng/ronke-odusanya-finally-speaks-on-alleged-husband-snatching-scandal/. Retrieved 20 April 2019. 
  4. Esho, Wemi (10 June 2014). "Nollywood Actress Weds US Based Lover Secretly". Pulse. Archived from the original on 20 April 2019. https://web.archive.org/web/20190420031605/https://www.pulse.ng/lifestyle/relationships-weddings/ronke-odusanya-nollywood-actress-weds-us-based-lover-secretly/vq5gcdh. Retrieved 20 April 2019. 
  5. BASSEY, EKAETTE (3 November 2018). "Yoruba actress, Ronke Odusanya, gives lesson on self-esteem". vanguardngr. https://www.vanguardngr.com/2018/11/yoruba-actress-ronke-odusanya-gives-lesson-on-self-esteem/. Retrieved 20 April 2019. 
  6. "9 Years After First Production, Ronke Odusanya Releases New Flick 'Gangan'". Tribuneonline. Archived from the original on 20 April 2019. Retrieved 20 April 2019. 
  7. "Ronke Odusanya". Ibaka TV. 20 November 2016. Archived from the original on 20 April 2019. https://web.archive.org/web/20190420031607/https://ibakatv.com/ronke-odusanya. Retrieved 20 April 2019. 
  8. Nigeria, Information (3 May 2018). "Popular Nollywood actress Ronke Odusanya celebrates birthday with lovely photo". Information Nigeria. https://www.informationng.com/2018/05/popular-nollywood-actress-ronke-odusanya-celebrates-birthday-with-lovely-photo.html. Retrieved 20 April 2019. 
  9. "CHARMING! NOLLYWOOD ACTRESS RONKE ODUSANYA STUNS IN NEW OUTFIT". Daily Advent. 14 January 2019. http://www.dailyadvent.com/ettmt/2019/01/14/charming-nollywood-actress-ronke-odusanya-stuns-in-new-outfit/. Retrieved 20 April 2019. 
  10. 10.0 10.1 izuzu, chibumga (5 March 2015). "9 things you should know about "Jenifa" actress". Pulse Nigeria. Archived from the original on 20 April 2019. https://web.archive.org/web/20190420031604/https://www.pulse.ng/entertainment/movies/ronke-odusanya-9-things-you-should-know-about-jenifa-actress/jhj9tnr. Retrieved 20 April 2019. 
  11. "Jenifa". Nollywood Forever. Archived from the original on 15 November 2021. Retrieved 20 April 2019. 
  12. "Jenifa". Africa Archive. Retrieved 20 April 2019. 
  13. Bolanle Ninalowo, IK Ogbonna, Rachel Okonkwo, "What Lies Within" among nominees Archived 2021-10-19 at the Wayback Machine., Pulse, Retrieved 20 April 2019
  14. A Girl's Note, IMDB, Retrieved 20 April 2019
  15. ayomide ( 2017), NLIST, Retrieved 20 April 2019
  16. Ezeamalu, Ben (6 September 2017). "Nominees for the Best of Nollywood Awards, 2017". Bonawards. Archived from the original on 26 October 2020. Retrieved 20 April 2019.