Jump to content

Sálíù Adétúnjí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Saliu Adétúnjí)

Ọba Sálíù Adétúnjí (tí a bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1928 - Oṣu Kẹta Ọjọ 2, Ọdun 2022) jẹ́ ọba aládé lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni Olúbàdàn tí ìlú Ìbàdàn lọ́wọ́́lọ́wọ́. Ó gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn ókànlélógójì lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹta ọdún 2016.[1] [2]

Ìtàn ayé rẹ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Kábíyèsì Sálíù Adétúnjí, Olúbàdàn tí ìlú Ìbàdàn lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1928. Orúkọ bàbá àti ìyá rẹ̀ ni Rájí Oláyíwọlá àti Sùwébátù Àmọ̀pé. Iṣẹ́ owó oríṣiríṣi ni Ọba Sálíù kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ kí ó tó wà faramọ́ iṣẹ́ ìránṣọ, èyí ló mú un dèrò ìlú Èkó. Lẹ̀yìn ìṣe ìránṣọ, ọba Sálíù tún dá iṣẹ́ akáhùn-orin sílẹ̀ lọ́dún 1960. Ó pe ilé iṣẹ́ akáhùn-orin rẹ̀ ní Bàbálájé Records. Iṣẹ́ yìí ló mú un gbajúmọ̀ débi pé òun ló ká ohùn orin àwọn gbajúgbajà àwọn olórin fújì bíi; Dáúdà Epo-àkàrà, King Wàsíù Àyìndé Marshal. Òun ni Balógun ìlú Ìbàdàn kí ó tó di Olúbàdàn tí ìlú Ìbàdàn lọ́dún 2016.[3] [4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. vanguard; vanguard (2016-03-04). "Adetunji crowned as 41st Olubadan of Ibadanland". Vanguard News. Retrieved 2019-11-19. 
  2. "Adetunji becomes the 41st Olubadan of Ibadanland". Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria. 2015-12-15. Retrieved 2019-11-19. 
  3. "Tailor who would be next Olubadan - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2016-01-21. Retrieved 2019-11-19. 
  4. "Ibadan Chiefs Support Chief Saliu Adetunji As Next Olubadan". Breaking Times. 2016-01-22. Archived from the original on 2016-06-12. Retrieved 2019-11-19.