Samuel Ortom

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Samuel Ioraer Ortom
18th Governor of Benue State
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
May 2015
AsíwájúGabriel Suswam
Federal Minister of Industry, Trade and Investment Nigeria
In office
11 July 2011 – 25 October 2015
Supervising Minister, Nigerian Federal Ministry of Aviation Nigeria
In office
14 February 2014 – 15 August 2014
AsíwájúPrincess Stella Oduah-Ogiemwonyi
Arọ́pòOsita Chidoka
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí23 April 1961
Guma LGA, Benue State, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPDP

Samuel Ioraer Ortom tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún 1961 (23rd April 1961) jẹ́ òṣèlú, oníṣòwò àti aláàánú ọlọ́rẹ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Benue lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue lọ́wọ́́lọ́wọ́. Lọ́dún 2015 ló wọlé gẹ́gẹ́ bí gómìnà lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, nígbà tó di ọdún 2019, ó tún wọlé gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Benue fún sáà kejì ṣùgbọ́n lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP. Nígbà ìṣèjọba Ààrẹ ana, Goodluck Jonathan, Samuel Ortom ni Mínísítà abẹ́lé fún karai àti dídá Okowò sílẹ̀.

Ìgbé-ayé àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí a t sọ ṣáájú, wọn bí Samuel Ortom lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún 1961 (23rd April 1961) ní ìjọba ìbílẹ̀ Gumaìpínlẹ̀ Benue , lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2] Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ni St. John's Primary School, ní ìlú Gboko lọ́dún 1970, àti St. Catherine's Primary School, ní ìlú Makurdi, olú ìlú ìpínlẹ̀ Benue lọ́dún 1974, ó parí ẹ̀kọ́ àkóbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 1976. Ortom tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni Idah Secondary Commercial College, Idah ní ìpínlẹ̀ Kogí, ṣùgbọ́n kò parí rẹ̀ nítorí àìsówó lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. Ní àkókò yìí ló di awakọ̀ èrò jẹun. [1] He became a professional driver.[3]. Samuel Ortom kò jẹ́ kí èyí fà á sẹ́yìn, nígbà tí ó lówó, ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ títí ó fi gba ìwé ẹ̀rí ọ̀mọ̀wé, Doctor of Philosophy (Ph.D) ní Commonwealth University, Belize, nípa ètò gbélé-kàwé.[4] Ṣíwájú àkókò yìí, ó kàwé gboyè Dípólómà nínú ìmọ̀ ọjà títà ni Ahmadu Bello University, ní ìlú Zaria àti ní Benu State University, níbi tí ó ti kàwé gboyè Dípólómà nínú iṣẹ́ ìròyìn lọ́dún 1998.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 Ayado, Solomon (26 September 2014). "Ortom, From Motor Park Tout To A Minister Of The Federal Republic". Leadership. Retrieved 4 October 2014. 
  2. "Name list of Nigeria's new cabinet". People's Daily. Xinhua. 13 July 2011. http://english.people.com.cn/90001/90777/90855/7438200.html. Retrieved 4 October 2014. 
  3. "News Forum – Celebrating Chief Dr. Samuel Ortom at 53". News Forum. Archived from the original on 8 November 2014. Retrieved 26 October 2014. 
  4. Agerzua, Tahav. "Celebrating Chief Dr. Samuel Ortom at 53". National Accord. Archived from the original on 6 October 2014. Retrieved 4 October 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)