Sasha p

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sasha P
Background information
Orúkọ àbísọAnthonia Yetúnde Àlàbí
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíiAyaba Híí-họpù Nàìjíríà [1]
Ọjọ́ìbí21 Oṣù Kẹfà 1983 (1983-06-21) (ọmọ ọdún 40)[2]
Ìbàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Nàìjíríà
Ìbẹ̀rẹ̀Èkó, Nàìjíríà
Irú orinHíí-họpù
Occupation(s)
  • Òṣèré tó ń rẹ̀kọ́ọ̀dù
  • Amúnídùn
  • Tálọ̀ tó Dágánjíá
  • Agbẹjọ́rò
Years active1993–2014
Associated acts

Sasha P (bí Anthonia Yetunde Alabi ní ọjọ́ kọnkọ̀lélógún oṣù karùn-ún ọdún 1983), Wọ́n tún mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ayaba híí-họpù Nàìjíríà, ó jẹ́ rápà Nàìjíríà, Olórin, Obìnrin-Onísọ̀wọ̀, Agbẹjọ́rò àti Olùwúnilórí.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó jẹ́ àbíkẹ̀yìn nínu ọmọ mẹ́jo, Ó jẹ́ ẹni tó jẹ́ wí pé ìyá rẹ̀ nìkan ló tọ́ ọ, Alákọ̀wé ni, tí wọ́n sáábà máa ń pè é ní Sisí Fádékẹ́mi, lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú tá.[3] Ó bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé orin rẹ̀ ní Ìbàdàn .[4] Ó lọ sí ilé-ìwé International School Ibadan àti Fásitì Èkó tó fí gba oyè fínnífínní ìparí ẹ̀kọ́ ní ìṣe Agbẹjọ́rò.[5][6]


Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Orin gẹ́gẹ́ bí Iṣẹ́ Àyoò rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

"I believe as an individual, I have a social responsibility to make a difference any way I can" "

-Sasha speaking about giving back to the community

Sasha P jẹ́ obìnrin tó rí Orí-ire rẹ̀ nínu orin nígbà tí ó jẹ́ wí pé obìnrin díẹ̀ lọ kọ Híí-họpù nígbà náà. Lẹ́yìn ìgbà náà , Orí-ire rẹ̀ yìí ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrànlọ́wọ́ fún àwọn rápà obìnrin àti àwọn obìnrin Olórin yòókù ní Híí-họpù Nàìjíríà .[7] Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ma ṣe ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Olórin àti fọwọ́bọ̀wé pẹ̀lú eLDee's Trybe records.[8][9] Sasha P sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin Olórin olókìkí ní Nàìjíríà láti ọdún, pàápàá lẹ́yìn àṣeyọrí rẹ̀ lórí álíbọ̀bú àkọ́kọ́ rẹ̀ First Lady lábẹ́ ìkóso rẹ̀ STORM. Ó wà lára àwọn tó dárúkọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ òye ní Nàìjíríà àti ilẹ̀-òkun. Ó gba Oyè "Best Female Artist" ní ọdún 2009 ní ilẹ̀-òkun ní the Women in Entertainment Awards fún Orin àdàkọ tó pè ní "Adara". Ó wà lára àwọn tó dárúkọ fún Oyè méjì lẹ́ẹ̀kan ṣo (Best Female Video and Best Cinematography) láti ọwọ́ SoundCity Video Music Awards fún Orin adákọ kejì tó pè ní Only One ní ọdún 2009.

Ó jẹ́ Obìnrin Olórin àkọ́kọ́ Nàìjíríà tó ma kọ́kọ́ ṣeré ní 20th anniversary of the World Music Awards ní oṣù kẹwàá ọdún 2008. Ó jẹ́ obìnrin Olórin àkọ́kọ́ Nàìjíríà tó má kọ́kọ́ gba the Best Female AwardMTV Africa Music Awards (MAMA).[10] Yàtọ̀ sí Adara, Ó kọ orin tó fi silẹ̀ Gidi Babe ní nígbà ọjọ́-ìbí rẹ̀ ní ọdún 2009. Ó fi orin àdàkọ silẹ̀ ní ọdún 2012 tó pè ní Bad Girl P.[11]

Ní ọdún 2013, Sasha P ṣe àlàyé wí pé òun ma fi orin silẹ̀ láti fi ojú sí ìṣọ̀wò àwọn aṣọ tó dára tí òun ṣe .[12][13]

Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Demola Adeshina (13 December 2011). "Sasha: First Lady of Hip Hop". YNaija. Retrieved 28 March 2015. 
  2. Patience Bambalele (14 August 2012). "Nelson, Sasha join forces to fuse jazz and rap sounds". South Africa: Sowetan Live. Retrieved 28 March 2015. 
  3. "Sasha P Remembers Her Dad 25 Years After". Information Nigeria. 19 August 2014. Retrieved 28 March 2015. 
  4. "I wrote my first song at 10 – Sasha". Newswatch Times. 1 December 2013. http://www.mynewswatchtimesng.com/wrote-first-song-10-sasha/. 
  5. "Young, Talented, Very Nigerian". Sahara Reporters. http://saharareporters.com/2008/03/13/young-talented-very-nigerian. 
  6. "I have always encouraged the growth of women in music, says Sasha P". Encomium. Retrieved 28 March 2015. 
  7. Kehinde Ajose. "Nigeria: Survival Tales of Top Music Divas". Allafrica. Retrieved 28 March 2015. 
  8. "Saturday Celebrity Interview: The Rapper, The Fashionista, The Advocate – It's the 'First Lady of Nigerian Hip Hop', Sasha P!". Bella Naija. Retrieved 28 March 2015. 
  9. Samond Biobaku. "Sasha opens up on secret formula, journey so far". Newswatch Times. Retrieved 28 March 2015. 
  10. "Sasha P". Women of West Africa. Retrieved 28 March 2015. 
  11. "Sasha P drops new single: Bad Girl P". Information Nigeria. Retrieved 28 March 2015. 
  12. "Sasha P: I Studied Law Because I Have Always Been Very Opinionated". Aprokocity. 2 September 2013. Retrieved 28 March 2015. 
  13. Olabanke Banjo (September 6, 2016). "Where Are They Now? 3 Nigerian Female Rappers We will Love to See Make a Comeback". Archived from the original on 14 January 2017. https://web.archive.org/web/20170114201017/http://www.olisa.tv/2016/09/where-are-they-now-top-3-nigerian-female-rappers-we-will-love-to-see-make-a-comeback/.