Segun Adewale

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Segun Adewale   Ṣẹ́gun Adéwálé jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí ní ọdún(1955) jẹ́ olórin, tí ọ̀pọ̀ sì gbà wípé òun ni ẹni àkọ́kọọ́ tí ó kọ́kọ́ kọ orin Yo-Pọọ̀pù tí ó jẹ́ àdàlú orin funk, jazz, jùjú, régè àti Afró.[1]

Ìgbé Ayé ré[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọmọba Ṣẹ́gun Adéwálé ni wọ́n bí sí ilé ọÓba tí òun náà sì jẹ́ ọrùn ìlẹ̀kẹ̀ pẹ̀lú nílùú Ògbómọ̀ṣọ́ìpínlẹ̀ Ọyọ́, ní orílẹ̀ èdè Nàìjírìà. Adéwálé filé sílẹ̀ nítorí wípé àwọn òbì rẹ̀ méjẹèjì lòdì sí iṣẹ́ orin tí ó yàn láàyò láti ṣàtìpó ní ìlú Èkó láti máa kórin rẹ̀ lọ. Nì ìlú Èkó yí ni ó ti pàdé olórin jùjú tí a mọ̀ sí S.L Atọ́lágbé àti I.K Dáìíró ní ọdún (1970). Adéwálé jẹ́ ọmọṣẹ́ lẹ́yìn akọrin Prince Adékúnlé òun oẹ̀lú ọ̀kórin Afro-Jùjú Sínà Peters. Ní ọdún 1977, òun àti Ṣínà Peters dá ègbẹ́ orin tiwọn sílẹ̀ tí wọ́n pè ní "Shina Adéwálé and the Superstars International". Wọ́b gbé àwo orin mẹ́sàán jáde kí wọ́n tó túká ní ọdún 1980, káti kọ dá ẹgbẹ̀ tiwọn sílẹ̀. Nígbà tí ó fi ma di ọdún 1984, Ṣẹ́gun Adéwálé ti si gbajúgbajà olórin Yo-Pop.

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Segun Adewale". Discogs. Retrieved 2019-03-14.