Jump to content

Seyi Adisa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Seyi Adisa
ọmọnìyàn
ẹ̀yàakọ Àtúnṣe
ọjó ìbí7 Oṣù Bélú 1983 Àtúnṣe
ìlú ìbíLagos State Àtúnṣe
iṣẹ́ oòjọ́ rẹ̀Amòfin Àtúnṣe
kẹ́ẹ̀kọ́ níUniversity of Birmingham Àtúnṣe

Ṣeyi Joseph Adisa (tí a bí ni ọjọ́ keje Oṣù kọkànlá ọdún 1983) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, agbẹjọro ati oloṣelu ni, ó sì tún jẹ́ olókoòwò, agbẹnusọ àti alabojuto ni ile iṣẹ ijọba. Ó ti fi ìgbà kan jẹ́ Akọ̀wé agba fún Gómìnà nigba kan ri ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi . Ní akoko yi, ó jẹ́ ọmọ ile igbimọ aṣofin ni Ipinle Oyo, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nibi ti o ti n ṣoju fun agbegbe Afijio labẹ asia ẹgbẹ All Progressive Congress (APC).

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bi Ṣeyi Adisa ni ilu Èkó sinu ẹbí Olóyè ati Ìyáàfin Ebenezer Babatunde Adisa ni ọjọ keje Oṣu kọkànlá, ọdún 1983. Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ́kọ́ rẹ̀ ní ile-iwe alakọbẹrẹ St. Leo's Nursery and Primary School, ilu Ikẹja, ni Ipinlẹ Èkó. Lẹyin ile ẹkọ alakọbẹrẹ, ó ré kọjá lọ sí ilé-ìwé girama to gbajugbaja ni ilu Eko, ti a n pe ni King's College, Lagos. Nigbati Ṣeyi kẹkọ jade ní King's College, ó gba ile ẹko Lambeth College lọ lati gba ìwé ẹ̀rí ti a n pe ni A Levels lori ìmọ̀ òfin, ìṣèlú ati okoòwò, akọsilẹ sọ wípé ó peregede nínú ẹkọ rẹ nílé iwe yii. Ṣeyi Adisa kò darà duro lẹyin eyi, o gba ile iwe giga Yunifasiti ti Birmingham (University of Birmingham[1]) lọ nibiti o ti gba imo ijinle lori ìmò òfin.

Ṣeyi tun fakọyọ ni ile iwe to wa fun awọn amofin ti a n pe ni The BPP Law School nibi ti o ti tayọ lori bi a ṣe n fi imo ofin ṣiṣẹ ṣe, Legal Practice Course (LPC). Nigba ti o pada de si orilẹ-ede Naijiria, Ṣeyi fi orukọ silẹ ni ile-ẹkọ awọn amofin ti orilẹ-ede yii, Nigerian Law School ti o si tun ṣe daada nibẹ. Ṣeyi Adisa kò jafara ninu ilakaka rẹ lati di akọ́ṣẹ́moṣẹ́ to dangajia ninu iṣẹ to yan laayo nigba ti o gbé'lé kẹkọ gboye ni awujọ awọn Akọwe ati alabojuto ti orilẹ-ede Naijiria, Institute of Chartered Secretary and Administrators Course ti o si gba ami ẹyẹ fun akeko to tayọ julọ ninu ẹkọ imo akọwe fun ile iṣẹ nlanla ati olokoowo (Corporate Secretaryship) ni ibamu pẹlu iṣẹ rẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba. Laipẹ yii ni Ṣeyi Adisa kẹkọ gba oye ẹlẹẹkeji ni ile ẹkọ giga Yunifasiti ti BIrmingham (University of Birmingham).

Iṣẹ́ àti ìrírí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣeyi pẹlu ẹnikan ni oludasilẹ ile-iṣẹ ti a n pe ni T&A Legal[1]. Ile-iṣẹ yii jẹ agbarijọ awọn agbẹjọro, wọn si ṣetan lati ṣiṣẹ fun olukuluku ti o ba nilo iṣẹ wọn. Ile-iṣẹ yii bẹrẹ pẹlu agbẹjọro meji pere ṣugbọn laarin ọdun mẹjọ, wọn di mẹta-din-logun ti ọfisi wọn si di mẹta. Ṣeyi ni ile-iṣẹ yii fi si akoso wiwa onibara, o si mu ọpọlọpọ onibara ti o kun fun ile-iṣẹ nlanla lati oke okun, ile-iṣẹ ijọba pẹlu awọn olokoowo kekeeke lati orilẹ-ede Naijiria naa wa ba T&A Legal da owo pọ̀. Ṣaaju asiko idasilẹ ile-iṣẹ T&A Legal yii, Ṣeyi ti ba ile-iṣẹ agbẹjọro kan ti a n pe ni Adepetun Caxton-Martins Agbor & Segun ṣiṣẹ ni ẹka epo rọbi ati iṣuna owo fun iṣẹ akanṣe.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2022-11-02. Retrieved 2022-11-02.