Jump to content

Sunday Ìgbòho

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Chief
Sunday Ìgbòho
Ọjọ́ìbíSunday Adéníyì Adéyẹmọ
(1972-10-10)10 Oṣù Kẹ̀wá 1972
Ìlú IÌgbòho, ní Òkè-Ògùn, Ìpínlẹ̀ Oyo
Iṣẹ́Ajìjàǹgbara, Olóṣèlú àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ-ènìyàn

Olóyè Sunday Ìgbòho tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gan-an ń jẹ́ Sunday Adéníyì Adéyẹmọ (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 1972 [1]) jẹ́ gbajúmọ̀ ajìjàǹgbara, olóṣèlú àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ajìjàǹgbara fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Oòduà àti ìṣọ̀kan àwọn ọmọ Yorùbá káàkiri Nàìjíríà.[2] Òun ni alága àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Adeson International Business Concept Ltd, bẹ́ẹ̀ náà wọ́n fi òye Akọni Oòduà ilẹ̀ Yorùbá dáa lọ́lá.[3] Sunday di ìlúmọ̀ọ́ká lórí ìkànnì abánidọ́rẹ̀ẹ́ lósù kìíní ọdún 2021, nígbà tí ó fún àwọn darandaran Fúlàní ní gbèdeke ọjọ́ méje láti kúrò nílẹ̀ Ìbàràpá, nítorí ìpakúpa tí wọ́n fura pé àwọn Fúlàní wọ̀nyí ni ó pa Ọ̀mọ̀wé Abọ́rọ̀dé.[4][5]

Ìgbésí ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Sunday ní ìlú Igboho, lÓkè-ògùn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Bàbá rẹ̀ tọ́ ọ dàgbà ní ìlú Mọdákẹ́kẹ́Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ nípa túntún kẹ̀kẹ́ alùpùpù ṣe, èyí ló fi ń jẹun kí ó tó tún bẹ̀rẹ̀ túntún ọkọ̀, lẹ́yìn èyí ló bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kí ó tó dá ilé-iṣẹ́ Adeson business Concept sílẹ̀.[6][7]

Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní di gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká nípa ipa akọni tí ó kó nínú ogun Modákẹ́kẹ́ àti Ifẹ̀ láàárín ọdún 1997 sí 1998, níbi tí ó ti gbè lẹ́yìn àwọn ènìyàn Modákẹ́kẹ́.[8] Lẹ́yìn èyí, ó padà sí Ìbàdàn, níbẹ̀ ló ti pàdé Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àná, Lam Adesina nípa ìgbésẹ̀ akin tí ó gbé nílé epo kan láti gbèjà àti jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn níbẹ̀.[9] Bákan náà, ó bá Gómìnà àná Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ mìíràn, Rasheed Ladoja ṣiṣẹ́, tí ó sìn di ọkàn nínú àwọn ìsọ̀ǹgbè olùfọkàntán rẹ̀.[10][11]

Gẹ́gẹ́ bí Akọni Ilẹ̀ OòduàSunday gbajúmọ̀ nípa jíjà fún ẹ̀tọ́ Yorùbá nípa lílo oògùn àti agbára ìbílẹ̀[12][13] bákan náà ni ó ń sapá àti akitiyan láti lẹ̀ jẹ́ kí àwọn ọmọ Yorùbá ó da dúró gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè olómìnira lábẹ́ orúkọ "Orílẹ̀-èdè Oòduà.[14][15]. Nitori naa ni o fe je Akoni Oodua awon Yoruba.[16]

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni Oṣu Kẹwa Ọdun 2023, Sunday Igboho ti tu silẹ ni Ilu Benin nibiti wọn ti mu u lẹhin ti o salọ fun ọlọpa ni Nigeria ni ọdun 2021.[1].

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Seven things to know about Sunday Igboho". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2021-01-23. Retrieved 2021-01-23. 
  2. Nenge, Katrine (2018-10-16). "Handsome and successful: The story of Sunday Igboho’s". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-21. 
  3. Alao, Moses. "2019: I Inherited Powers To Command Guns From My Father —Sunday Igboho". tribuneonlineng.com. Archived from the original on 2021-01-24. Retrieved 2021-01-21.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "INSECURITY: Why Fulani herders must leave Oyo - Igboho". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-01-19. Retrieved 2021-01-21. 
  5. "Nothing must happen to Igboho, Ibarapa Youths warn FG, Oyo govt". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-01-20. Retrieved 2021-01-21. 
  6. Editor. "Sunday Igboho Biography, Age, Early Life, Family, Education, Career And Net Worth". Information Guide Africa. Retrieved 2021-01-21. 
  7. "Meet Area Boss Called Sunday Igboho". TheCityPulseNews.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-05-17. Retrieved 2021-01-21. 
  8. Abimbade, Isaac (2017-11-14). "Why My Mum Gave Me The Name SUNDAY IGBOHO". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-21. 
  9. "Sunday Igboho's biography~Lifestyle - AMEBO ONLINE NEWSPAPER". www.amebo9jafeed.com.ng. Retrieved 2021-01-21. 
  10. says, Onyewuchi Nze (2017-04-15). "HOW OBASANJO, ADEDIBU OFFERED ME N100M TO IMPEACH LADOJA –SUNDAY IGBOHO". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-21. 
  11. Adedire, Toyin. "Exclusive pictures and interview with Sunday Igboho-I am a human rights defender". www.ibadancityng.com. Archived from the original on 2021-09-19. Retrieved 2021-01-21.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. Alao, Moses. "2019: I Inherited Powers To Command Guns From My Father —Sunday Igboho". tribuneonlineng.com. Archived from the original on 2021-01-24. Retrieved 2021-01-21.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. "Meet Sunday Igboho, The Man People Believe Could Command A Gun Out Of Thin Air To Fight - Opera News". ng.opera.news. Archived from the original on 2021-02-06. Retrieved 2021-01-21. 
  14. editing (2020-09-16). "Sunday Igboho: An Intractable Revolutionary By Rèmí Oyèyemí". Sahara Reporters. Retrieved 2021-01-21. 
  15. "You Can't Frustrate Operation Amotekun, Sunday Igboho Warns Miyetti Allah Leader". OyoAffairs.net (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-09-29. Retrieved 2021-01-21. 
  16. "[ICYMI]: I inherited powers to command guns from my father - Sunday Igboho". Tribune Online. 2021-01-25. Retrieved 2021-06-13.