Tọ́pẹ́ Àlàbí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Tọ́pẹ́ Àlàbí, tí gbogbo ènìyàn tún mọ̀ sí oore tí kò wọ́pọ̀ tàbí Agbo Jésù (tí a bí ní ọjọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1970)[1] jẹ́ olórin ẹ̀mí[2] ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olùkọ orin sí fíìmù [3] àti òṣèré orí-ìtàgé àti fíìmù àgbéléwò.[4]

Ìlú Èkó ni a ti bí Tọ́pẹ́ Àlàbí ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1970 sínú ẹbí Alàgbà Joseph Akínyẹlé Ọbáyomí ati Ìyáàfin Kẹ́hìndé Ọbáyomí. Òun nìkan ṣoṣo ni ọmọbìnrin tí ó wà láàrin àwọn ọmọ mẹ́ta tí ó wà nínú ẹbí náà. Ní agbègbè Yewa, Ìmẹ̀kọ ní Ìpínlẹ̀ Ògùn ni ó ti wá.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Biography". Tope Alabi. Retrieved 2010-12-06. 
  2. Shepherd, John; Laing, Dave (2003). Continuum encyclopedia of popular music of the world, Volumes 3-7. Continuum. p. 171. ISBN 978-0-8264-7436-0. 
  3. . http://ajol.info/index.php/nmr/article/view/35368. 
  4. . http://allafrica.com/stories/200807280673.html.