Jump to content

Tope Alabi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tope Alabi
Ọjọ́ìbí27 Oṣù Kẹ̀wá 1970 (1970-10-27) (ọmọ ọdún 54)
Lagos, Nàìjíríà
Iṣẹ́
  • Gospel Singer
  • Actress
  • Film Music Composer
Gbajúmọ̀ fúnGospel music
Àwọn ọmọ3

Tọ́pẹ́ Àlàbí tí wọ́n tún mọ̀ sí "Oore tí ò common" àti agbo Jésù ni a bí i ní (ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1970), ó jẹ́ òṣèré, akọrin eré sinimá àti òǹkọrin ìgbàgbọ́.[1]

Ìgbé ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Tọ́pẹ́ Àlàbí ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1970 ní ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà fún Pa Joseph Akínyẹlé Ọbáyọmí àti Madamu Agnes Kẹ́hìndé Ọbáyọmí. Òun nìkan ni obìnrin lààrin ọmọ mẹ́ta nínú ẹbí náà. Ọmọ bíbí ìlú Yewa, Ìmẹ̀kọ ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni. Tọ́pẹ́ Àlàbí gba ìwé ẹ̀rí ìwé mẹ́wàá (West African Examination Conncil WAEC) ní ilé ẹ̀kọ́ Ọba Akínyẹlé Memorial High School, Ìbàdàn ní ọdún 1986. Lẹ́yìn èyí, ó tẹ́ síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbogboǹṣe Polí Ìbàdàn (The polytechnic Ìbàdàn) ní ibi tí ó ti kọ́ nípa ẹ̀kọ́ ìbánisọ̀rọ̀ gbogbogbòò tí ó sì jàde ní ọdún 1990. Tọ́pẹ́ Àlàbí lépa ẹ̀kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀sílàra àti ìfọkànsìn tí ẹ̀kọ́ gbà.

Iṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òǹkọrin àti òṣèré

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tọ́pẹ́ Àlàbí ti fi ìgbà kan jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ "Jesters International Comedy Group". Ìgbà tí ó yá ó ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ eléré orí ìtàgé àti àrìnjó ní ìlú Ìbàdàn àti Èkó. Ó ṣeré ní agbo eré àgbéléwò Yorùbá ti Nàìjíríà. Àlàbí padà di òǹkọrin ìgbàgbọ́ lẹ́yín tí ó di onígbàgbọ́ tòótọ́. Láàrin ọdún 1982 sí 1984 láyé ìgbà ilé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì, ìfẹ́ rẹ̀ sí orin àti eré orí ìtàgè mú un darapọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n mọ̀ ní ìgbà yẹn sí "Jesters International" (Jacob, Pápílolò àti Adẹ́rùpọkọ̀) ẹgbẹ́ tí ó wà ní Ìbàdàn, ní ibẹ̀ ni ó ti ní imọ̀ àti ìrírí àkọ́kọ́ nínú eré orí ìtàgé. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ móhùnmáwòrán Nigerian Television Authority (NTA) Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bìi akọ̀ròyìn lábẹ́ àbójútó ọ̀gbẹ́ni Yanjú Adégbìtẹ́, láàrin ọdún 1990 sí 1991. Ó tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú "Centre Spread Advertising Limited" agbègbè Ìlúpéjú Èkó ní ọdún 1991 sí 1992. Lẹ́yìn tí ó ti ní orísirísi ìrírí iṣẹ́, Patrick Tèmítọ́pẹ́ Àlàbí padà sí iṣẹ́ eré orí ìtàgé gẹ́gẹ́ bí ó ṣe darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ olókìkí nǹi "Àlàdé Arómirẹ́ Theartre Group" ní ọdún 1994. Níbẹ̀, ó ṣàwárí ìyàtọ̀ ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olóore ọ̀fẹ́ àti abínibí òsèré àti olórin[2] Ní Àlàdé Arómirẹ́ Theartre Group wọ́n ṣe àfihàn kòṣeemánìí eré orí ìtàgé àti iṣẹ́ eré orí ìtàgé fún Tọ́pẹ́ Àlàbí. Ó kópa nínú onírúnrú eré àgbéléwò, eré orí ìtàgé àti pàápàá jùlọ orin inú eré gbígbé jáde èyí tí wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ jùlọ tí wọ́n sì gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ̀ ní ilé iṣẹ́ eré àgbéléwò Yorùbá Nàìjíríà ti òde òní. Onírúnrú òǹkọ̀tàn, agbéréjáde àti adarí eré ní ilẹ́ iṣẹ́ eré àgbéléwò Yorùbá ni ó ti pe Tọ́pẹ́ Àlàbí láti kọ àti láti gbé orin jáde fún onírúnrú eré àgbéléwò wọn, ó ti ní títí di òní, orin eré tí o tó ọ̀tàdínnírinwó-ó-lé-mẹ́wàá (350) tí ó ti kọ fún orísirísi eré àgbéléwò Yorùbá. Ó yẹ kí a sọ níbi tí a wà yí pé Tọ́pẹ́ Àlàbí ni olúlànà fún kíkọ orin abẹ́lẹ̀ ní ilé iṣẹ́ fídíò àgbéléwò Yorùbá.[3]

  • Ore ti o Common (2001)
  • Iwe Eri (2003)
  • Agbara Re NI (2005)
  • Agbara Olorun (2006)
  • Angeli MI (2007)
  • Kokoro Igbala (2008)
  • Kabiosi (2010)
  • Moriyanu
  • Agbelebu (2011)
  • Alagbara (2012)
  • Agbelebu (2013)
  • Oruko Tuntun (2015)
  • Omo Jesu (2017)
  • Yes & Amen (2018)
  • Spirit of Light (TY Bello) (2019)
  • Olorun Nbe Funmi (Iseoluwa)
  • Eruretoba (TY Bello)
  • Adonai (TY Bello)
  • Awa Gbe Oga (TY Bello)
  • Angeli (TY Bello)
  • No One Else (TY Bello)
  • Oba Mi De (TY Bello)
  • Olowo Ina (TY Bello)
  • War (TY Bello)
  • Lowo Olorun Lowa (2020)
  • Unless You Bless Me (2022)
  • Igbowo Eda (2023)
  • Oluwa Ni: The Spontaneous Worship (2024) [4]

Àwọn itọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Tope Alabi Biography, Husband, Children, Halleluyah, Albums and Songs". Informationcradle. 2017-06-28. Archived from the original on 2019-03-24. Retrieved 2018-11-26. 
  2. Egbo, Vwovwe (2018-04-10). "Tope Alabi surprises husband on his birthday". Pulse.ng. Retrieved 2018-11-26. 
  3. Adeyemi, ST (2005-09-13). "The Culture Specific Application of Sound in Nigerian Video Movies". Nigerian Music Review (African Journals Online (AJOL)) 5 (1). doi:10.4314/nmr.v5i1.35368. ISSN 1116-428X. 
  4. VibeOnVibe.com.ng (2023-02-02). "Stream ‘Tope Alabi - Oluwa Ni: The Spontaneous Worship Album". VibeOnVibe.com.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2024-02-01. Retrieved 2024-02-02.