Jump to content

The Ghost and the Tout

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

 


The Ghost and the Tout
Fáìlì:The Ghost and the Tout poster.jpg
AdaríCharles Uwagbai
Olùgbékalẹ̀Toyin Abraham
Samuel Olatunji
Àwọn òṣèréSambasa Nzeribe
Toyin Abraham
Rachael Okonkwo
Omowumi Dada
Lasisi Elenu
Ilé-iṣẹ́ fíìmùToyin Abraham Productions
Déètì àgbéjádeỌjọ́ Kọkànlá oṣù kaàrún Ọdún 2018
ÀkókòÌṣẹ́jú Mẹ́tàlélọ́gọ̀rún
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
ÈdèÈde Gẹ̀ẹ́sì
Owó àrígbàwọlé₦77,233,105[1]

The Ghost and the Tout tí a mọ̀ sì Abaraméjì àti Ọmọ ìta jẹ́ eré oníse orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ọdún 2018 tí olùkọ̀tàn àti olùdarí rẹ̀ jẹ́ Charles Uwagbai . Àwọn ògbóǹtàrìgì òṣèré bíi Sambasa Nzeribe, Toyin Abraham, Rachael Okonkwo àti Omowumi Dada ni àwọn tí ó kópa Ìṣaájú. Eré oníṣe náà di àfihàn tó dájú ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ kọkànlá Oṣù Kaàrún ọdún 2018 ó sì gba àwọn àtúnyẹ̀wò rere láti ọ̀dọ àwọn alárìwíísí.

Eré oníṣe náà di àṣeyọrí pẹ̀lú ọgbọ̀n mílíọ̀nù ní àárín ọ̀sẹ̀ kan ósì wà ní ipò kaàrún nínú àwọn eré oníṣe ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó gbajúgbajà jùlọ ní ọdún 2018 . Eré oníṣe náà tún wà ní ipò karùndínlógbọ̀n nínú àpapọ̀ àwọn eré oníṣe tí ó gbajúgbajà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àkòrí eré oníṣe náà dá lórí ọ̀dọ́mọdé bìrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìsìlá (Toyin Abraham) tí ó ń gbé ní àárín agbolé. Ó pàdé abaraméjì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mike (Sambasa Nzeribe), ẹnití ó nílò ìrànlọ́wọ́ ọmọbìrin náà láti bá àwọn ènìyan tí ó fi sílẹ̀ sọ̀rọ̀. Pẹ̀lú ìbéèrè abaraméjí náà, ìpòruru ọkàn àti ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún láti yanjú ohun àràmọ̀dà ìpànìyàn tí ìgbésí ayé rẹ̀ sì yí padà sí ohun tí ó wúni lórí. Òhun nìkan ni ó mọ nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.