Jump to content

Wale Aboderin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Gbadebowale Aboderin
Ọjọ́ìbíGbadebowale Aboderin
1958
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Journalist, entrepreneur, editor and the chairman of Punch Nigeria Limited
Gbajúmọ̀ fúnchairman of Punch Nigeria Limited


Gbadebowale Aboderin (1958 – 30 May 2018) jẹ́ oniroyin láti orílẹ̀-èdè Naijiria, oníṣòwò àti alábòójútó eré-ìdárayá. Òun ni alága Ìwé-ìròyìn Punch títí ìgbà tó kú, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tí bàbá rẹ̀ dá sílè. Ìwé-ìròyìn Vanguard ṣe àpejúwe ìwé-ìròyìn yìí gẹ́gẹ́ bíi òpó kan pàtàkì fún iṣẹ́ ìgbéròyìn jáde.[1] Ó kàwé ní Government college, ní ìlú Ibadan àti Clifton college, kó tó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọkọ̀ òfurufú ní Burnside-Ott Flying School. Nínú eré-ìdárayá, ó jẹ́ alága, Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Agbábọ́ọ̀lù Ìpínlẹ̀ Èkó àti igbákejì ààrẹ Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà.[2] Aboderin kú lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ọkàn tí ó ṣe ní Eko. Aare ilẹ̀ Nàìjíríà, Muhammadu Buhari, Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ rí, Akinwunmi Ambode wà lára àwon tó ṣàánú fún àwọn ẹbí rẹ̀.

Ní ọdún 1997, ó ṣe ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù inú apẹ̀rẹ̀ aládàáni ti ilẹ̀ Nàìjíríà àkọ́kọ́ fún àwọn obìnrin, Dolphins.[3]

Wale Aboderin kú ní 30 May 2018 ní Ikoyi, Ìpínlẹ̀ Èkó, ní ẹni ọdún 60.[4]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Wale Aboderin : Pillar of Journalism/Man of the people". Vanguard. June 14, 2018. Retrieved 2018-07-29. 
  2. Ojo, Mojirade. "Wale Aboderin (1958 – 2018)". Retrieved 2018-07-29. 
  3. "Aboderin: Man who changed face of women’s basketball". Punch. 
  4. "Aboderin, Punch newspaper Chairman, dies at 60". www.premiumtimesng.com. 2018-05-31. Retrieved 2023-02-13.