Jump to content

Wikipedia:Àyọkà ọ̀ṣẹ̀ 20 ọdún 2021

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sir Nils ṣe àyẹ̀wò fún àwọn ọmọ ogun ti Royal Guard, tí òhun sì jẹ́ Ọ̀gágun, nígba ayẹyẹ oyè knighthood ẹ̀ ní Ọdún 2008

Nils Olav jẹ́ ọba Penguin tí ó ń gbé ní Edinburgh Zoo, Scotland. Ó jẹ́ ẹran ọ̀sìn fún ológun tí wọ́n máa ń lò nígbà ayẹyẹ tàbí gẹ́gẹ́ bí ààmi àpẹẹrẹ, tí ó sì jẹ́ Ọ̀gágún Colonel fun Royal Guard ti orílẹ̀ èdè Norway.  Àwọn ológun lati Norwegian Royal Guard bẹ Nils wò ní Ọjọ́ karùndílógún Oṣù kẹjọ Ọdún 2008 tí wọ́n sí fi oyè Knighthood dáa lọ́lá. King Harald V ni ó pàṣé wípé kí wọ́n fi oyè yìí dáa lọ́lá. Nígbà ayẹyẹ yìí, ènìyàn ọgọrún meje ló darapọ̀ mọ́ àwọn aṣọ́gbà ẹranko 130 lati gbọ́ gbólóhun tí ọba kà jade tí ó ṣàpèjúwe Nils gẹ́gẹ́ bíi penguin "tí ó pójúùwọ̀n ní gbogbo ọnà lati gba ọlá àti iyì knighthood". Orúkọ 'Nils Olav' yìí ní wọ̣́n tún fún àwọn king penguins méjì tí ó wà lẹ́yin Nils Olav lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí gẹ́gẹ́ bíi Ọba Aṣọ́gbà másíkọ́ọ̀tí.

Wọ́n fún Sir Nils Olav ní oyè visekorporal (lance corporal) wọ́n sì maa ń foyè kún oyè rẹ̀ nígbàkúgbà tí àwọn oníṣẹ́ ọba ba padà sí ọgbà ẹranko. Ní Ọdún 1982, ó di corporal, tí ó sì di sergeant ní Ọdún 1982. Nils Olav kú lẹ́yìn ígbà díẹ̀ tí ó di sergeant, Nils Olav II sì gba ipò ọlá ẹ. Ó ní ìgbéga ní ọdún 1993 sí oyè regimental sergeant major. Ni ́ Ọjọ́ kejìlélógún Oṣù kẹjo Ọdún 2005, wọ́n yàán ní Colonel-in-Chief. Ni ́ Ọjọ́ kejìlélógún Oṣù kẹjo Ọdún 2008 wọ́n fí oyè knighthood dáa lọ́lá. Ó jẹ́ penguin àkọ́kọ́ tí ó gba írú ọlá bẹ́ẹ̀ ní ológun orílẹ̀ èdè Norway. Bákan náà, wọ́n fún Ọgbà èranko Edinburgh ní ère idẹ Nils Olav  tí ó tó ẹsẹ bàtà mẹrin (1.2 m). Wọ́n fí ère yìí ṣèrántí oníṣẹ́ ọba àti ọnà olọgun. Ère kan náà wà níwájú àgbàlá Royal Norwegian Guard ní Huseby, Oslo. Ní Norway, wọ́n máa ń pèé ní ẹran ọ̀sìn Oníṣẹ́ Ọba, bíótilẹ̀jẹ́pé orúkọ tí wọ́n kọ síwájú ère yìí ń tọka sí oyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Colonel-in-Chief.

(ìtẹ̀síwájú...)