Wikipedia:Àyọkà ọṣẹ̀ 28 ọdún 2011

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lógò Athens 2004
Lógò Athens 2004

Àwọn Ìdíje Òlímpíkì Ìgbà Oru 2004, oníbiṣẹ́ bíi Àwọn Ìdíje Òlímpíádì 28k, jẹ́ ìdíje pàtàkì akáríayé oníeré-ìdárayá púpọ̀ tó wáyé ní Athens, Gírìsì láti ọjọ́ 13 Oṣù Kẹjọ de ọjọ́ 29 Oṣù Kẹjọ, 2004 pẹ̀lú motto Welcome Home. Àwọn eléré-ìdárayá 10,625 ni wọ́n kópa níbẹ̀, èyí fi 600 ju iye tí wọ́n retí lọ, àwọn wọ̀nyí jẹ́ títẹlé lẹ́yìn pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ bíi 5,501 láti orílẹ̀-èdè 201. Àwọn ìdíje 301 fún ẹ̀ṣọ́ wáyé nínú àwọn eré-ìdárayá 28. Athens ọdún 2004 ni ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà Àwọn Ìdíje Òlímpíkì Ìgbà Oru 1996 tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní Ìgbìmọ̀ Òlímpíkì Olórílẹ̀-èdè kópa. Bákannáà ó tún jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ láti ọdún 1896 (lẹ́yìn Ìdíje 1906 tó ti jẹ́ rírẹ̀sílẹ̀ látìgbà náà wá) tí àwọn Ìdíje Òlímpíkì wáyé ní Gírìsì.

Athens je yiyan gegebi ilu agbalejo ninu Ipade 106k IOC to waye ni Lausanne ni September 5, 1997. Athens ti kuna idu re lodun meje seyin ni September 18, 1990 ninu Ipade 96k IOC ni Tokyo lati gbalejo Awon Idije Igba Oru 1996 eyi to sele ni Atlanta. abe idari Gianna Angelopoulos-Daskalaki, Athens mura fun idu miran, nigba yi fun eto lati gbalejo Awon Idije Igba Oru 2004. Iyorisirere ilu Athens lati gba awon Idije 2004 da lori ibebe Athens si itan Olimpiki ati itenu re mo ipa pataki ti orile-ede Girisi ati ilu Athens le ko nipa pipolongo iwa Olimpiki ati Isunkankan Olimpiki. Bakanna, ko ri bi idu won fun awon Idije 1996 to je fifi abuku kan fun ailojutu ati iyaju re - nibi ti idu na ko ni unkankan pato, to kan je pe o gbokan le itara ati ero okan pe eto ilu Athens ni lati gbalejo awon Idije ti ogorun odun; idu fun awon Idije 2004 je yiyin fun inirewesi ati ooto re, iranse re to lojutu, ati ekunrere eto idu re. Idu ti 2004 yanju awon isoro ti ti 1996 ko le yanju - pataki imura ilu Athens, idibaje afefeayika re, isuna re, ati ifoselu se ipalemo awon Idije. Iyorisirere Athens nigba to gbalejo Idije-eye Agbaye Ere Ori Papa 1997 losu kan ki idiboyan ilu agbalejo o to waye na tun se pataki nipa imura re lati gbalejo ere-idaraya akariaye. Eyi to tun fa ti won fi yyan ilu Athens ni itara larin awon omo egbe IOC lati da ogo Olimpiki pada si awon Idije, eyi ni won ro pe o sonu nigba Awon Idije Atlanta 1996 ti won fi abuku kan pe o ti je siseju lokowo. Nitorie, iyan Athens je bi ero pe yio yato si awon Idije 1996.

Leyin to ti lewaju ninu gbogbo awon iyipo idibo, Athens segun Rome laini inira nini ibo 5k to dopin. Cape Town, Stockholm, ati Buenos Aires, awon ilu meta miran ti won bo sinu iwe-kukuru IOC, je lile kuro ninu awon iyipo idibo seyin. Awon ilu mefa miran na tun se itoro, sugbon idu won je fifisile latowo IOC ni 1996. Awon ilu na ni Istanbul, Lille, Rio de Janeiro, San Juan, Seville, ati Saint Petersburg. (tẹ̀síwájú...)