Wikipedia:Ìtọrọ láti di alámòjútó/Dokimazo99
Àwọn ìfi orúkosílẹ̀ fún alámòjútó tó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ
[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àkókò tí a wà lọ́wọ́lọ́wọ́ ni
- Ijíròrò tó tẹ̀le yìí jẹ́ àkójọ ìjíròrò pẹ̀lú ìbéèrè fún ìparẹ́ àpilẹ̀kọ tó wà lókè. Ẹ jọwọ, ẹ má ṣe ṣe àtúnṣe sí i. Ẹ máa fi àwọn èrò tuntun yín sí ojú ìjíròrò tó yẹ (bíi ojú-ewe ìjíròrò àpilẹ̀kọ tàbí nígbà àyẹ̀wò ìparẹ́). Ẹ má ṣe fi àtúnṣe kankan sí ojú ewe yìí mọ́.
' Ó yege'. T CellsTalk 13:11, 25 Oṣù Bélú 2024 (UTC)
Ọ̀rọ̀ ìforúkọsílẹ̀
[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹ kú déédé àsìkò yí o! Orúkọ oníṣẹ́ mi ni Dokimazo99. Mo jẹ́ aláfikún sí Wikipedia ti èdè Yorùbá, èyí tí mo darapọ̀ mọ́ ní ọdún 2019. Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ ẹgbẹ̀ Yorùbá Wikimedians User Group tí ń ṣe agbátẹrù fùn Wikipedia èdè Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ṣe ìdásílẹ̀ Yoruba Wiki Fan-club Unilag, níbi tí mo ti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè tí wọ́n sì ń pàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ṣàfikún sí Wikipedia ti èdè Yorùbá. Mò ń fi àkókò yìí tọrọ láti di alábòójútó fún Wikipedia èdè Yorùbá kí ń ba lè ní àǹfààní láti máa mójútó àwọn àyọkà tí wọ́n bá ń kọ sí orí Wikipedia ti èdè Yorùbá. Mo fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín nípa fífi ìbò yín tìmí lẹ́yìn. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ìdìbò yín. Dokimazo99 (ọ̀rọ̀) 13:31, 24 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
Ìjíròrò
[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Àwọn ìjápọ̀ fún oníṣẹ́ Àpẹrẹ: Dokimazo99 (talk.contribs.deleted.logs.block log.lu.rfar.rfc.rfcu.ssp.spi)
- A lè rí àwọn àtúnṣe tí oníṣẹ́ Àpẹrẹ ti sọ̀rọ̀níṣókí ní ibí.
Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ tútù tó dára, pẹ̀lụ́ ìrẹ̀lẹ̀. Tí o kò bá mọ oníṣẹ́ tí ó fẹ́ di alábójútó yìí dáradára, Jọ̀wọ́ ṣe àyẹ̀wo àfikún rẹ̀ dáradára kí o tó dási.
Ìkọ àfìkọṣábẹ́
Faramọ́ (support)
[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Mo faramọ́ kí Dokimazo di alábòójútó Wikipedia Àyọ̀ká Adébísí (ọ̀rọ̀) 14:21, 24 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo faramọ́ kí Dokimazo99 jẹ́ alábòójútó lórí Yorùbá Wikipedia yìí, nítorí iṣẹ́ takuntakun wọn lórí Yorùbá Wikipedia. OMODASOLA ASAKE (ọ̀rọ̀) 14:23, 24 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo faramọ, Oníṣe Dokimazo99 tí ṣe ẹgbẹẹgbẹ̀rún àfikún sí Wikipedia Yorùbá. Ó ti kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Oníṣe nípa ṣíṣe àfikún sí Wikipedia Yorùbá. Jíjẹ́ alámójútó ma ràn án lọ́wọ́ láti dojú ìjà kọ àwọn ìbàjẹ́ tí àwọn Oníṣe mìíràn (yálà tí ó bá jẹ́ pẹ̀lú ète tí ó da tàbí èyí tí kò da) bá ṣe sí Wikipedia Yorùbá Dr Marve (ọ̀rọ̀) 14:29, 24 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo láyọ̀ kíkún láti faramọ́ Dorcas Omolade tí orúkọ oníṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ Dokimazo99 láti jẹ́ alábòjútó lórí Wikipedia Yorùbá yìí, ìdí ni pé, ó ti ṣiṣẹ́ ribiribi lórí ìkànnì yìí. Ìwúrí ńlá ni yóò jẹ́ fún akitiyan rẹ̀ láti jẹ alábòjútó wikipedia Yoruba yìí. Ruth-4life (ọ̀rọ̀) 15:04, 24 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo faramọ́ kí arábìnrin Dorcas Omolade pẹ̀lú orúkọ oníṣẹ́ Dokimazo99 di alábòójútó Wikipedia Yorùbá nítorí ìfarajì rẹ̀ àti àwọn ohun ribiribi tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè Wikipedia. SolutionTomi (ọ̀rọ̀) 15:12, 24 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo faramọ́ kí arábìnrin Dorcas Omolade pẹ̀lú orúkọ oníṣẹ́ Dokimazo99 di alábòójútó Wikipedia Yorùbá nítorí ìfarajì rẹ̀ àti àwọn ohun ribiribi tí wọ́n ti ṣe fún ìdàgbàsókè Wikipedia. Enitanade (ọ̀rọ̀)
- Mo fara mọ́ kí arábìnrin Dorcas pẹ̀lú orúkọ oníṣẹ́ Dokimazo99 ó di alábòójútó Wikipedia Yorùbá nítorí ipa takuntakun tí wọ́n ti kó, èyí tí wọ́n ń kó lọ́wọ́, àti èyí tí wọ́n máa kó nínú ìdàgbàsókè àti gbígbèèrú èdè Yorùbá àti ìfarajìn wọ́n fún tí tẹ̀síwájú àjọ Wikipedia.IamMKO (ọ̀rọ̀) 18:54, 24 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo fara mọ́ kí arábìnrin Dorcas pẹ̀lú orúkọ oníṣẹ́ Dokimazo99 ó di alábòójútó Wikipedia Yorùbá nítorí ipa takuntakun tí wọ́n ti kó, èyí tí wọ́n ń kó lọ́wọ́, àti èyí tí wọ́n máa kó nínú ìdàgbàsókè àti gbígbèèrú èdè Yorùbá àti ìfarajìn wọ́n fún tí tẹ̀síwájú àjọ Wikipedia.Olaide07 18:54, 24 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo faramọ́ pátápátá pé kí Omidan Dorcas Omolade tí orúkọ oníṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ (oníṣẹ:Dokimazo99) di alábòjútó lórí Wikipedia Yorùbá. Ó tó gbangba sùn lọ́yẹ́. Oníṣe:Macdanpets Macdanpets 07:53, 25 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo faramọ́ kí Dokimazo99 jẹ́ alábòójútó lórí Yorùbá Wikipedia yìí, nítorí iṣẹ́ takuntakun to n se lórí Wikipedia Yorùbá Ogundele1 (ọ̀rọ̀) 09:41, 25 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi farammọ́ Omidan Dorcas Omolade ti orúkọ oníṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ Dokimazo99 láti di alábòjútó lórí Wikipedia Yorùbá, nítorí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn àti pé wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n dáadáa. SojiJay (ọ̀rọ̀) 11:04, 25 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo fara mọ́ kí arábìnrin Dorcas pẹ̀lú orúkọ oníṣẹ́ Dokimazo99 di alábòójútó Wikipedia Yorùbá. Adeogun Yetunde Basirat (ọ̀rọ̀) 11:08, 25 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo bọwọ́ lu èyí láti mú kí Arábìnrin Dorcas Ọmọladé tí orúkọ oníṣẹ́ wọn jẹ́ Dokimazo99 jẹ́ alábòójútó lórí Yoruba Wikipedia yìí, mo nígbàgbọ́ pé wọ́n máa ṣe iṣẹ́ náà bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ. Official Mr. Pen (ọ̀rọ̀) 11:12, 25 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo faramọAgbalagba (ọ̀rọ̀) 11:45, 25 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
- Mo láyọ̀ kíkún láti faramọ́ Dorcas Omolade tí orúkọ oníṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ Dokimazo99 láti jẹ́ alábòjútó lórí Wikipedia Yorùbá yìí, ìdí ni pé, ó ti ṣiṣẹ́ ribiribi lórí ìkànnì yìí. Ìwúrí ńlá ni yóò jẹ́ fún akitiyan rẹ̀ láti jẹ alábòjútó wikipedia Yoruba yìí.Oluwatoyin Ayomide (ọ̀rọ̀) 15:14, 25 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 (UTC)
lòdìsí (oppose)
[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìdásí gbogboògbò (general comment)
[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]tí àwọn ìforúkosílẹ̀ kó bá dé ojú ìwọ̀n.
- Ijíròrò lókè yìí ni a fipamọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkójọ àwọn òfin àròkò náà. Ẹ jọwọ, ẹ má ṣe ṣe àtúnṣe sí i. Ẹ máa fi àwọn èrò tuntun yín sí ojú ìjíròrò tó yẹ (bíi ojú-ewe ìjíròrò àpilẹ̀kọ tàbí nígbà àyẹ̀wò ìparẹ́). Ẹ má ṣe fi àtúnṣe kankan sí ojú ewe yìí mọ́. Ẹ má ṣe fi àtúnṣe kankan sí ojú ewe yìí mọ́.