Jump to content

Yẹmí ṣóladé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Yẹmí ṣóladé (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlélọ̀gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1960) jẹ́ gbajúmọ̀ àti arẹwà ọmọkùnrin òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1]

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, wọ́n bí Yẹmí ṣóladé lọ́jọ́ kọkànlélọ̀gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1960 sí ìlú Èkó lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà . Nígbà èwe rẹ̀, ó kàwé ní St. Thomas Aquilla Primary School àti Birch Freeman Secondary school, ní Sùúrùlélrè, ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Lẹ́yìn èyí, Yemi fò gẹ̀ẹ̀rẹ̀, ó dèrọ̀ ìlú Ọba níbi tí ó ti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó sìn gba ìwé ẹ̀rí A Level ni ilé-ìwé gíga Tyhill College ní ìlú Coventry lorílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn èyí, ó tún padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sìn tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Oyo State College of Arts and Science, OSCAS. Lẹ́yìn náà ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè sí i nínú iṣẹ́ tíátà ní Obafemi Awolowo University (OAU), ní Ilé-Ifẹ̀ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[2] [3] [1] [4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "All You Need To Know And More About Yemi Solade (Biography) - Playground.ng". Playground.ng. 2017-01-31. Archived from the original on 2019-12-10. Retrieved 2019-12-10. 
  2. Published (2015-12-15). "My first wife left me, says Yemi Solade". Punch Newspapers. Retrieved 2019-12-10. 
  3. "Yemi Solade: 13 facts you should know about the Nollywood actor - Nigerian Entertainment Today". Nigerian Entertainment Today. 2016-02-01. Retrieved 2019-12-10. 
  4. "Yemi Solade wears new look - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2019-07-12. Retrieved 2019-12-10.