Yinka Ayefele
Yinka Ayefele | |
---|---|
Yinka Ayefele ńkọ orin nibi ayeye kan ni Ìpínlẹ̀ Ògùn | |
Ọjọ́ìbí | Ọláyínká Joel Ayéfẹ́lẹ́ 1 Oṣù Kejì 1968 Ipoti-Èkìtì, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Ọmọ Nàìjíríà |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Olórin |
Ìgbà iṣẹ́ | 1998–títí di àsìkò yìí |
Olólùfẹ́ | Temitope Titilope[1] |
Parent(s) | Chief Joshua Taiwo Ayefele (Father)[1] |
Olayinka Joel Ayefele MON jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti akọrin Ìhìnrere ní ìlànà Kìrìsìtẹ́nì.[2][3] Ó sì tún jẹ́ olóòtú ètò orí rédíò, àti olùdásílẹ̀ Fresh àti Blast FM, tó wà káàkiri apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà.[4][5][6]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹlpẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Ayefele Ipoti-Ekiti, èyí tó jẹ́ ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, tó wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà[7]
Ètò Ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ilé-ìwé Our Saviours Anglican Primary School ní Ipoti-Ekiti ló lọ fún ẹ̀kọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ girama, kí ó tó lọ sí Ondo State College of Arts and Science ní Ikare Akoko, tó wà ní Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà.[8]
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ayefele ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i akọ̀ròyìn àti agbéròyìnjáde ní Federal Radio Corporation of Nigeria, Ibadan, níbi tí ó sì máa ń ṣàgbéjáde orin kékèèké lórí rédíò.[9] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin tó yàn láàyò ní ọdún 1997 lẹ́yìn tí ó farapa ní ìjàm̀bá ọkọ̀ tó bá eegun ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́, tí ó sì mu kí ó wà ní orí wheelchair.[10][11] Nígbà tó ṣì wà ní ilé-ìwòsàn níbi tí ó ti lo bí i oṣù mẹ́sàn-án, ọ̀rẹ́ rẹ̀ Kola Olootu, bẹ̀ ẹ́ wò, ó sì gbà á níyànjú pé kí ó hun àwọn orin kan pọ̀.[12] Ìyànjú yìí ló bí àwo-orin Bitter Experience ní ọdún 1998, tó sì mú u wá sí gbàgede.[13] Àgbéjáde àwo-orin Sweet Experience ló tẹ̀lé orin Bitter Experience.[14] Àwọn àwo-orin ìmíì tó ti ọwọ́ akọrin yìí jáde ni Something Else, Divine Intervention àti Life after death, tí ó gbé jáde láti fi ṣẹ̀yẹ Gbenga Adeboye, tó jẹ́ olóòtú ètò orí rédíò, olórin àti apanilẹ́rìn-ín.[15] Orin Bitter Experience ṣàpèjúwe àwon ìrírí rẹ̀, Sweet Experience sì jẹ́ "adùn tó gbẹ̀yìn ewúro rẹ̀".[16]
Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ayefele ti gba àmì-ẹ̀yẹ tó lé ní igba.[17] Lára wọn ni:
- Ọmọ-ẹgbé Order of the Niger láti ọwọ́ Goodluck Ebele Jonathan, tó fìgbà kan jẹ́ ààrẹ Federal Republic of Nigeria (2011)
- Ekiti cultural ambassador award
Àtòjọ àwọn orin rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Bitter Experience (1998)
- Sweet Experience (1999)
- Something Else (2000)
- Divine Intervention (2001)
- Fun Fair (2002)
- Life after Death (2003)
- Aspiration (2003)
- Fulfilment (2004)
- New Dawn (2005)
- Next Level (2006)
- Gratitude (2007)
- Absolute Praise (2008)
- Transformation (2009)
- Everlasting Grace (2010)
- Prayer Point (2011)
- Goodness Of God (2012)
- Comforter (2013)
- Overcomer (2014)
- Upliftment (2015)
- Fresh Glory (2016)
- Living Testimony (2017)
- Favour (2018)
- Beyond The Limits (2019)
- Ekundayo (Exhilaration) (2020)
- Manifestation (2021)
- So Far So Good (2022)
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Our Correspondent. "New Telegraph – How Yinka Ayefele's father died after birthday celebration". newtelegraphonline.com. Archived from the original on 11 February 2015. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Yinka Ayefele's travails". The Punch – Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 11 February 2015. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Yinka Ayefele celebrates". The Punch – Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 11 February 2015. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Nigeria's Fresh FM radio station partially demolished following critical reporting". Committee to Protect Journalists (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-08-27. Retrieved 2021-03-13.
- ↑ "Yinka Ayefele's travails". The Punch – Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 11 February 2015. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Yinka Ayefele celebrates". The Punch – Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 11 February 2015. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Shock as Yinka Ayefele's father dies at birthday party – DailyPost Nigeria". DailyPost Nigeria. 15 October 2014. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Yinka Ayefele discusses his accident, marital life, Patience Jonathan rally and music in new interview". dailystar.com.ng. Archived from the original on 23 October 2013. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Yinka Ayefele Bereaved As Late Father Wanted Him To Be A Banker". nigeriafilms.com. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "The incredible lifestyle of an entertainer". Vanguard News. 24 August 2014. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ Emokpae Odigie (2015). When Reasoning Is on Vacation. Strategic Book Publishing & Rights Agency. p. 77. ISBN 9781631351914. https://books.google.com/books?id=j6a8BwAAQBAJ&pg=PA77.
- ↑ "Yinka Ayefele: What The President's Handshake Did To Me, Articles – THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 11 February 2015. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "People Take Advantage of My Condition----Yinka Ayefele". modernghana.com. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Yinka Ayefele to release new album in January 2015". Nigerian Entertainment Today – Nigeria's Number 1 Entertainment Daily. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "Yinka Ayefele – Gbenga Adeboye Life after death". Last.fm. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ Administrator. "About Yinka Ayefele". ayefeleradio.com. Archived from the original on 11 February 2015. Retrieved 11 February 2015.
- ↑ "HISTORIC: HONOR NIGHT IN TORONTO! Ayefele Bags 200th Award in Canada…Receives Special Lifetime Achievement Award * Nigeria Embassy Officials to witness Ceremony * Sir Shina Peters as Special Guest!". nigeriastandardnewspaper.com. Archived from the original on 11 February 2015. Retrieved 11 February 2015.